O. Daf 25
25
Adura fún ìtọ́sọ́nà ati Ààbò
1OLUWA, iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si.
2Ọlọrun mi, emi gbẹkẹle ọ: máṣe jẹ ki oju ki o ti mi, máṣe jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ̀ mi.
3Lõtọ, maṣe jẹ ki oju ki o tì ẹnikẹni ti o duro tì ọ: awọn ti nṣẹ̀ li ainidi ni oju yio tì.
4Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ.
5Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo.
6Oluwa, ranti ãnu ati iṣeun-ifẹ rẹ ti o ni irọnu; nitoriti nwọn ti wà ni igba atijọ.
7Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ igba-ewe mi, ati irekọja mi: gẹgẹ bi ãnu rẹ iwọ ranti mi, Oluwa, nitori ore rẹ:
8Rere ati diduro-ṣinṣin ni Oluwa: nitorina ni yio ṣe ma kọ́ ẹlẹṣẹ li ọ̀na na.
9Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀.
10Gbogbo ipa Oluwa li ãnu ati otitọ, fun irú awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ mọ́.
11Nitori orukọ rẹ, Oluwa, dari ẹ̀ṣẹ mi jì, nitori ti o tobi.
12Ọkunrin wo li o bẹ̀ru Oluwa? on ni yio kọ́ li ọ̀na ti yio yàn.
13Ọkàn rẹ̀ yio joko ninu ire, irú-ọmọ rẹ̀ yio si jogun aiye.
14Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀.
15Oju mi gbé soke si Oluwa lai; nitori ti yio fà ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọn na.
16Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju.
17Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi.
18Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi.
19Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka.
20Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ.
21Jẹ ki ìwa-titọ ati iduro-ṣinṣin ki o pa mi mọ́: nitoriti mo duro tì ọ.
22Rà Israeli pada, Ọlọrun, kuro ninu ìṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 25: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.