Fẹ́ràn bí JésùÀpẹrẹ

Jíjẹ Ọ̀rẹ́
Mo ni alábàáṣiṣẹ́ títún kan sẹ́yìn díè tó fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ mi gidi gan-an. Dípò kín kí káàbọ̀ sínú ẹgbẹ́ wa, Mi kò se dáadáa sí i. Kódà, àwọn ìgbà mìíràn má burú sí i. A máa jáde láti ìgbà sí ìgbà àmọ́ nígbà tó bá rọrùn fún mi nìkan.
Oṣù díè kọjá lo àti pé àyẹ̀wò fi hàn pé bàbá mi ni àrùn jẹjẹrẹ. Kò pé púpò kín tó rí ara mi ni ìbùdó ìpèsè ìtọ́jú láàárín ọjọ́ mélòó tó kù ní ayé rè. Ẹnì yìí tí mi kò fún ni àkókò bẹ̀rẹ̀ sí ni gbàdúrà fún mi lákòókò tó ń bani lẹ́rù yìí. O sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù pẹ̀lú mi lalálé títí tó má fi rè mi tó láti tó sùn lọ. O se oúnjẹ tí mo fẹ́ràn gan-an fún mi kí n to wọnú ọkọ̀ òfuurufú. O ṣètò ẹ̀bùn pẹ̀lú gbogbo àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi yòókù láti rán ṣe si mi. Àti nígbà tí mo padà senú iṣẹ́, o pèsè ara rè lárọ̀ọ́wọ́tó láti bá ṣòro àti bá mi sunkún nígbàkigbà tí mo bá nílò.
O jé ọ̀rẹ́ mi kí n tó mò pé mo nílò oókan. O bìkítà nípa mi nígbà tí mo bìkítà fún un. O fẹ́ràn mi nígbà tí mó jẹ́ ẹnì tí wón kò lè fẹ́ràn.
Mo rò pé mo mò ohun tí ojúlówó ìfẹ́ jẹ́. Mo rò pé mo lóye bí Jésù se fẹ́ràn wa. O wá já sí pé, Mi o tọ̀nà rara. Fún ìdí kan, Mo rò pé a lẹ́tọ̀ọ́ sí ojúlówó ìfẹ́. Bí, a bẹ̀rẹ̀ si ni fẹ́ràn àwọn ènìyàn jẹmọ́-kán àti pé tí ìyen bá ṣẹnuure, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ o ma di ojúlówó. Àmọ́ kì i se ònà tí Ọlọ́run ti fẹ́ràn re. O kú fún wa nígbà tí a yìí jé elésè. Jésù rí mi bí ẹnì to yé fún ìfẹ́ kódà nígbà tí mi kò ye fún mi. O fẹ́ràn ni ojúlówó ìfẹ́ lo ni si mi láti ìbẹ̀rẹ̀, àti pé ọ̀nà yìí Ló fi pé wa láti fẹ́ràn àwọn mìíràn.
Ọ̀rẹ́ yen fẹ́ràn mi bí Jésù se fẹ́ràn mi. Mo fẹ́ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀.
Sam Simala
Life.Church Wichita
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Báwo ni a ṣe lè kọ́ láti gbé bí Jésù tí a kò bá kọ́kọ́ fẹ́ràn bí Ẹ̀? Máa káa lo pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àti tọkọtaya Life.Church bí wọn ṣe sọ asòtúnsọ àwọn ìrírí àti àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ tó fi wọn sábẹ́ ìmísì láti gbé àti fẹ́ràn bí Jésù.
More