Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú WúwoÀpẹrẹ

Travel Light

Ọjọ́ 5 nínú 7

Jíjọ̀wọ́ Ìṣàkóso

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, mò ń mú ètò ìkọ́ṣẹ́ mi wá sí ìparí. Alágbàyìdá ni ètò náà jẹ́, àmọ́ ń kò mọ ohun tí ó kàn lẹ́yìn tó bá parí. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ní bèrè (nígbà mìíràn ṣeni mo ma ń fọwọ́ lalẹ̀) lọ́wọ́ Ọlọ́run nípa ǹkan tí ó kàn, ó sì fẹ́ jọ pé Ó ń fún mi lésì ní gbogbo ìgbà, àmọ́ èsì Rẹ̀ kò yé mi rárá. Fún ìdí èyí, mo rò wípé arọ́n ló ńṣe mí. 

Mò ń pàdánù àkóso lórí ohun tí mo fẹ́. Ọlọ́run ò tẹ̀lé ètò tí mo lérò fún ayé mi.

A mú mi rántí màmá tó bí Jésù. Ìwọ kàn tiẹ̀ f'ojú inú wòó. Kìí ṣe ìpinnu Màríà láti di ọ̀dọ́mọbìnrin tó lóyún láì ṣègbéyàwó. Kò sí ní ìkápá rẹ̀ láti pinnu èsì ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ lẹ́yìn tí ó mọ̀ wípé kìí ṣe òhun ló l'oyún. Kò sí ní ìkápá rẹ̀ láti yí èrò àwọn ènìyàn padà, ó sì dá mi lójú wípé àwọn ènìyàn tẹnu bọlẹ̀ ní àkókò náà.

Ní gbẹ̀yìn-gbẹ́yín, mo pinnu láti jọ̀wọ́ àfojúsùn tí mo ní nípa ọjọ́ ọ̀la lẹ́yìn èyí mo wá tẹ́ gbogbo ètò ayé mi síwájú Ọlọ́run. Ní àfarajọ bí Màríà ti sọ wípé—jẹ́ kí ó rí fún mi bí ìfẹ́ Rẹ sí mi. 

Kò bá má yà mí lẹ́nu, àmọ́ Ọlọ́run kò y'ẹ́nu padà nípa èsì Rẹ̀. Ó tẹ̀síwájú láti máa tọ́ mi láti lọ sí ìlú mìíràn níbi ti n kò ti ní iṣẹ́, ẹbí, ìrètí, tàbí ibi tí mo lè gbé. 

Màríà àti Jósẹ́fù rin irú ìrìn-àjò yí lọ sí Íjíbítì, ìyàtọ̀ ibẹ̀ kàn ni wípé ṣeni àwọn méjèèjì ń sá àsálà fún ẹ̀mí ọmọ wọn, ẹni tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run bákannáà. 

Ọkàn mi pòrùúru, àmọ́ mo ṣáà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésẹ̀ ní ìgbọràn sí ìtọ́ni. Lẹ́ẹ̀kan si, kò yẹ kí ẹnu kò yà mí, àmọ́ mo padà ri ilé ìgbé, àwọn alábàágbé, iṣẹ́, ní àfikún jíjẹ́ olùdarí nínú ìjọ. 

Ohun gbogbo ló yọrí sí rere fún Màríà, Jósẹ́fù, àti Jésù pẹ̀lú!

Bóyá ipò, iṣẹ́ ẹni, ìṣúná, ọmọ títọ́, ìbáṣepọ̀, tàbí àwọn ohun afẹ́ tí mo fẹ́ràn—níwọ̀n ìgbà tí mo bá fi àkóso ohun gbogbo sí ìkápá araà mi, ǹkan kìí fẹ́ jọ ra wọn lọ títí. 

Bí mo ti ń yí po, ni mo ń gbìyànjú láti ló kọ́kọ́rọ́ tí kò yẹ, pẹ̀lú ipá, láti ṣílẹ̀kùn tó wà ní iwájú mi. Ní apá kan sì nìyí, Ọlọ́run mọ kọ́kọ́rọ́ náà tí yóò ṣílẹ̀kùn tó kàn nínú ayé mi pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Mo ti jọ̀wọ́ àdììtú ayé mi sí ọwọ́ Rẹ̀ láti àkókò yí lọ. Ìwọ náà jọ̀wọ́ọ tìrẹ. 

Kaelyn, kò sí ní ìṣàkóso

Gba èyí rò: Kíni ǹkan ẹyọ kan tí o fi ọwọ́ dọin dọin mú? Kíni ǹkan náà tó ń fò ọ́ láyà láti pàdánù? Apá wo nínú ayé rẹ ni èsì Ọlọ́run kò ti ní ìtumọ̀? Kíni ìgbésẹ̀ rẹ àkọ́kọ́ láti jọ̀wọ́ ìṣàkóso?

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Travel Light

Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/