Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú WúwoÀpẹrẹ

Bóyá irú ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn yìí ti ṣe ọ́ rí: À ń di ẹrù sínú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ara ìpalẹ̀mọ́ láti rin ìrìn àjò lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bíi wa fún ọdún Kéresìmesì. Ìṣesí mi sí àwọn ọmọ mi àti ọ̀kọ mi dàbíi ti ọ̀gá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ró lágbára ọ̀tun tó wá ń darí àwọn yòókù bí ó ti wù ú nitorí pé iṣẹ́ ti wọ̀ o lọ́rùn. Ọkọ mi rọra tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ mi láti bèèrè pé "kí ló ń ṣẹlẹ̀?" Ó hàn gbangba pé èyí ti kọjá bíì ìpalẹ̀mọ́ ìrìnàjò ti máa ń mu mí lómi látẹ̀hìnwá.
Bí a ṣe ń tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí bèrè àwọn ìbéèrè tí kò ṣàjèjì sí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ ara mi, Kí ló dé tí ara ni mí lásìkò yìí tí gbogbo ènìyàn ń yọ ayọ̀ ọdún? Kín ni ìdí? Àsìkò yìí wà fún Jésù ọmọ tuntun tí a bí, ẹbí, ọ̀rẹ́, oúnjẹ, ẹ̀bùn, bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá àti nnkan mímu kòkó dídùn tó gbóná. Ó jẹ́ àsìkò ọ̀tọ̀ tí a máa ń sinmi lọ́wọ́ bóojí o jí mi. Kí ló wa ṣẹlẹ̀ sí mi?
Nígbà tí mo ríi pé nkò leè ro ọ̀rọ̀ yìí jinlẹ̀ tó, mo pinnu láti bẹ Ọlọ́run kí ó ràn mí lọ́wọ́ nípa líla ojú mi sí nnkan tí ó ń ṣẹlẹ̀. Ọ̀rọ̀ òdì tí mọ̀lẹ́bí kan sọ sí mi lọ́dún tó kọjá ló wá sọ́kàn mi.
Àbí ibi yìí ni gbogbo ìnira ọkàn ti wá? Àsìkò tí a fi wà lórín ìrìnàjò yìí ṣí òye mi sí pé mo ti fi ààyè gba ọ̀rọ̀ òdì yìí, mo sì gbà á gbọ́ nítorí pé ó bá èrò mi pé kò sí ààbò fún mi mu. Mo bínú sí ara mi pé nkò gba ara mi sílẹ̀, inú tún bí mi pé mo gbé àjàgà yìí sọ́kàn láti ìgbà yìí wá. Inú tún bí mi pé mo ńjẹ́ kí èrò yìí kó ní ipá lórí ẹbí mi. Ṣùgbọ́n bíbínú sí ara mi kò mú kí ìnira yìí kúrò.
Lákòótán, mo pinnu láti gbàdúrà fún ẹni tí ó ṣẹ̀ mí. Bí kò tilẹ̀ yí onítọ̀hún padà, dájúdájú yóò yí èmi padà , èyíì ní èrò mi. Mo pinnu láti máa gbà wọ́n níyànjú nítorí bóyá wọ́n sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ nítorí pé àwọn náà lérò pé àwọn kò ní ààbò tó tàbí bóyá nnkan kan ń dùn wọ́n lọ́kàn bíi tèmi. Ọ̀nà tí ó dára jù láti tọ̀ ni èyí. Ọ̀nà ti Ọlọ́run.
Mo pinnu láti dáríjì. Jésù sọ, Ó sì fún wa ní àpẹẹrẹ bí a ṣe ń dárí ji ènìyàn. Ó dárí jì mí. Àádọ́rin lọ́nà méje lọ́jọ́ kan ni iye ìgbà tí Ó ní kí á máa dárí ji ara wa. Ọ̀nà míràn tí a tún leè fi sọ èyí ni pé, kí a máa dárí ji ara wa ní gbogbo ìgbà tí ó bá yẹ.
Ọ̀kọ̀ wa kò wúwo lọ́dún yìí nítorí n kò gbé àjàgà ẹrù àti ìrora ọkàn. Dípò bẹ́ẹ̀, àlàáfíà, ìwàláàyè àti ìmọ́lẹ̀ Jésù ni mo kó.
Ìbáṣepọ̀ wo ló ń fún ọ ní ìnira nínú ayé rẹ? Báwo ni o ṣe lè jẹ́ kí Jésù tí ó wà nínú rẹ mú ìnira náà kúrò?
Krístì, rínrin ìrìnàjò láì gbẹ́rù tó wúwo ní Kérésìmesì yìí
Rò ó:Tani oó ma gbàdúrà fún nígbogbo ìgbà? Báwo lo ṣe lè dárí jì wọ́n?
Nípa Ìpèsè yìí

Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.
More