Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú WúwoÀpẹrẹ

Fi Ìtíjú Sílẹ̀
Mo rántí dáadáa. Mo sọfún ẹnìkan tí mo pọ́nlé kí o jòwó gbàdúrà fún mi. Nígbà tí wọ́n béèrè pé nípa kíni, ohun kan tí mo lè sọ ni wípé nńkan ńṣe mí. Bẹ́ẹ̀ni, nínú ọkàn mi, nínú ẹ̀mí mi, nńkan kàn ko tọ̀nà. Àgbàlagbà ní mí o, àmọ́, mi ò le ṣàlàyé pàtó ǹkan tó ń se mi.
Ìtíjú ní.
Láti gbọ́ ará wa ni àgbọ́yé, kìí se ẹ̀bi rárá. Ẹ̀bi ní kí o mọ̀ pé o ti ṣe àṣemáṣe. Ìtíjú ní kí o lérò wípé ìwọ gan an ni àṣìṣe. Ìyàtò ńlá.
Ìtíjú máa ń mu dá wa lójú pé a ní láti fi irú ẹni tí a jẹ́ gangan pamọ́, nítorí kò sí ẹní tó fẹ́ mọ irú ẹni tí a jẹ́. O máa ń dáyà jáwa àmọ́ Ọlọ́run mọ irú ẹni tí a jẹ́ gangan. Èyí gán ní ohun tí mo ń ní ìrírí rẹ̀ nítorí àwọn ohun tí a sọ àti tí a ṣe sí mi lọ́jọ́ tó ti pẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yìí fi ìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú mi tó bẹ́ẹ̀ tí won di àwọn ohun tí mo fi nṣe òdiwọn ara mi.
Òtító rẹ̀ ní yìí: Olórun rí wa kedere, ohun gbogbo tí a jẹ́, O sí tún na ọwọ́ ìfẹ́ sí wa. Nígbàtí Ó bá ńwo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi, A máa rí àwọn ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin tí kò ní àbàwọ́n nítorí Jésù kú láti gbà ipò ìtìjú wa. Èmi, àti gbogbo wa lè jọ̀wọ́ ìtìjú wa lọ́wọ́, kí a sì mọ rírì iyì tí Ọlọ́run bù fún wa.
Èyí dùn láti gbọ́, bẹ́ẹ̀ni, àmọ́ o ní nńkan tí mo ti kọ́. Mímú ìtìjú kúrò kìí ṣe ohun tí a lè “parí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀”. Ní t'èmi, mo máa ń ṣí ìtìjú kúrò láwẹ́láwẹ́ ni bí mo ti ń ni òye tí mo ṣì ńtako àwọn irọ́ tí mo ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Lẹ́hìn èyí, mò ń fi ọ̀kọ̀ọ̀nkan àwọn ìtìjú náà s'ọ̀kò dànù bí mo ṣe ń ṣe àwárí àti àkójọ àwọn òtítọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi rọ́pò ìrọ́ kọ̀ọ̀kan.
Fífi ìtìjú ṣílẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀ ní kíákíá, ó lè má rọrùn, tàbí lọ geere, àmọ́ ó fúyẹ́. Ọlọ́run ò síjúlé gbogbo àìdá tí o gbàgbọ́ nípa ará rẹ, àmọ́, Ó máa ru gbogbo rẹ̀ dànù fún ọ, tí ìwọ bá gbà Á láàyè.
Amanda, tí ń mú ìtìjú kúrò
Ìgbésẹ̀: Ṣàwarí àwọn ọ̀rọ̀ òdì tí o tí gbàgbọ́ kí o bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé pẹ̀lú àti nípa ìkéde Ọ̀rọ̀ Olórun dípò àwọn irọ́ náà. www.life.church/declarations
Nípa Ìpèsè yìí

Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.
More