Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú WúwoÀpẹrẹ

Travel Light

Ọjọ́ 1 nínú 7

Jíjọ̀wọ́ Ohun gbogbo

Njẹ́ ìwọ́ ti rin ìrìn-àjò ìdárayáa ti oní àpò gbígbé sẹ́yìn? (Ìrìn àjò yí jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ ní òkè òkun, àwọn arìnrìn àjò á gbé àpò sẹ́yìn, wọn a má sá àwọn nkan tí wọ́n bá rí lọ́nà, tí ó wúlò fún wọn bí wọ́n ṣe ńlọ títí dé òpin ìrìn àjò yìí). Ójẹ́ ohun tí ó kún fún ìgbádùn, àwọn òpin ìrìn àjò yí má ṣábà jà sí ibi tí ó ya ni lẹ́nu. Tí o bá ńrì ìrìn-àjò ìdárayá yí fún ìgbà àkọkọ, ìwọ yíò tètè rí wípé gbogbo ohun tí o bá mú bọ̀ yíò jẹ́ ohun tí o nílò láti gbé. Wọn a ma rin ìrìn àjò yí fún ọ̀pọ̀ máìlì, tí wọn ó sí má gun àwọn òkè. Àwọn tí wọ́n má ńrin ìrìn-àjò yìí mọ̀ wípé àwọn kò lè mú gbogbo ohun tí àwọn fẹ́ àti tí wọ́n rí ní ọ̀nà padà bọ̀. Àwọn tí wọ́n ti nrin ìrìn-àjò yí fún ìgbà pípé gan mọ̀ pé kòṣeésẹ láti mú gbogbo ohun tí àrìnrìn àjò bá fẹ́ràn láti mú padà.

Gbogbo ìwọ̀n ló ṣe pàtàkì

Ìrìn àjò yí kò yàtọ̀ púpọ̀ sí ìrìn àjò ayé wa, àbí? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, mo ń gbìyànjú láti gbé àwọn nkan tí Ọlọ́run ò gbèrò fúnmi láti gbé. Mo mọ pé Ọlọ́run ò fẹ́ kí n má gbé ìṣòro ẹbí, ìnìra nípa owó, àbámọ̀ lórí ìpinnu tí kọ sunwọ̀n, ìlépa tí mi ò rí mú ní ilé iṣẹ, àti gbogbo ohun tí mo gbìyànjú láti gbé lónì.

Olọ́run sọ wípé kí á gbé ẹrù wa wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (1 Pétérù 5:7) kí á fi gbogbo ohun tí ó ń dáwa dúró sílẹ̀ (Hébérù 12:1). Ójẹ́ ìyàlẹ́nu láti mọ̀ wípé Olọ́run fẹ́ kí á jọ̀wọ́ gbogbo ohun tí ó ńdáwa dúró. Ṣùgbọ́n kíni ìdí tí Olọ́run ṣe fẹ́ kí á rin ìrìn-àjò yí láìsí erù wúwo? Kílódé tí ó fẹ́ gba ohun tí ó ń dẹ́rùbà wá, ìtìjú, àfẹ́sódì, àbámọ̀, ati orí kunkun?

Nígbàtí o bá ń di àpò láti lò fún ìrìn àjò ìdárayáa gbígbé àpò sẹ́yìn yìí, ohun tí o ò bá dì ńfàyè sílẹ̀ fún nkan míràn. Olọ́run fẹ́ àyè síi nínú ayé wa fùn ara Rẹ̀

Èyí jẹ́ ìrọ́pò ìyàlẹ́nu tí o bá rò; A gbé gbogbo ìṣòro wa fún Ọlọ́run Òhun á sì fún wa ní ara Rẹ̀. Òkùnkùn fún ìmọ́lẹ̀. wàhálà fún àlàfíà. inú-bíbí fún ayọ̀. Àbámọ̀ fún òmìnira. Bí a se ńgba àwọn nkan yìí lọ́wọ́ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ni erù wa fúyẹ́ síi.

Kíni àwọn nkan tí o gbé l'ọ́nà tí wọ́n ti wá ń wúwo? Ìwọ kò ní láti gbé wọn mọ́. O le fi wọ́n sílẹ̀ láti fi dípò mímọ Ọlọ́run síi. Kíni nkan tí o fẹ́ gbé tí kò lẹ́tọ̀ fún o láti gbé? Báwo ni o se lè gbẹ́kẹ̀lé Olọ́run pẹ̀lú rẹ? Kíni ohun tí o ròpé o nílò tí ìwọ kò ní okun láti gbé? Báwo ni o se lè jẹ́ kí Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn bẹ́ẹ gbé lára erù yìí

Matt, ń kọ gbogbo àdìmẹ́rù sílẹ̀

Gbàdúrà: Ọlọrun, mo dúró lórí ọ̀rọ̀ Rẹ. Èmi yíò bẹ̀rẹ̀ láti máa gbẹ́kẹ̀lé Ọ nípa (fi ẹ̀bẹ̀ àdúrà rẹ nípàtó síbí). Mo dúpẹ́ fún bí Ẹ ṣe ń gbàmí tí Ẹ sì ń gbémiró. Àmín.

Tẹ́tísí àwọn ìwàásù, kí o sì gba àwọn ohun àmúlò nípa ètò yìí.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Travel Light

Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé die síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.life.church/