Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú WúwoÀpẹrẹ

Jíjọ̀wọ́ Ẹrù Kíkójo
Nígbà kan rí, mo fẹ́ràn láti máa kó ẹrù jọ púpọ̀ ju, pàtàkì jù lọ aṣọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ idunadura, aṣọ, bata, pẹ̀lú ojú lọ́nà fún àti ra nkan míràn, ìpòngbẹ sí oun tí ẹlòmíràn wọ. O padà hàn sí mi pé gbogbo oun tí mò ń kó jọ ti ga tó bẹ ẹ tí ó ti ṣíji bo sí sin Ọlọ́run ní ojojúmọ́.
Ìwé Róòmù 12:1 ní ẹ̀dà ti "The Message" túmọ̀ rẹ̀ báyìí, “Mú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ayé rẹ, àwọn—ìdùbúlẹ̀, jíjẹ oúnjẹ, iṣẹ́ ṣíṣe, àti ìrìnkiridò ayé—kí o sì kó wọn síwájú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọrẹ.”
Mo wá ṣe ìdánwò kan: Mo yẹra fún ríra aṣọ àti bàtà fún odidi ọdún kan gbáko!
Jesu bá wa sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ nípa bí ó ṣe yẹ kí a ṣe sí àwọn ẹrù tí à ń kójọ. Nínú ìwé Lúùkù 12, Ó sọ̀rọ̀ pọ́ńbélé nípa rẹ̀.
… “Kíyèsára! Di ara rẹ gírí nítorí onírúurú ojúkòkòrò; ìgbésí ayé rẹ kò pin lór ọ̀pọ̀ ohun ìní.” Lúùkù 12:15 NIV
Mo kọ́ ẹ̀kọ́ tó pọ̀ níwọ̀n ọdún kan. Mo ríi pé ẹrù kíkó jọ kìí ṣe àjàgà fún èmi nìkan. Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Tearfund tó kárí àgbáyé, ni mó wá rí àjàgà tí àwọn ẹrù tí mò ń kójọ ń fà fún àwọn òṣìṣẹ́ lókè òkun. Àti pẹ̀lú bí ó ṣe ń hàn sí mi bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi fi ń ṣiṣẹ́ kára kára lóríi ẹ̀tọ́ bíntíń, àkójọ mi tayọ òṣùwọ̀n.
Bí ojúkòkòrò mi sí ẹrù kíkójo ti ń dínkù, bẹ́ẹ̀ni ìpòngbẹ́ mi fún Ọlọ́run ń gbèrú si. Mo rò pé má a di aláìní, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ mo rí ọ̀pọ̀ gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kìí ṣe irú "ọ̀pọ̀" tí ó n kó ẹrù jọ, bíkòṣe èyí tí yóò tú ọ sílẹ̀.
Ǹjẹ́ mo lè gbà ọ́ níyànjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àpọ́sítélì? Láì bìkítà irúfẹ́ ìfẹjúmọ́ láti ṣá ma kó nkan jọ—nítorí òmìnira ni Jésù fi tú wa sílẹ̀. Ẹ dúró ṣinṣin, pẹ̀lú pẹ̀lú èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí àjàgà ẹrù kíkó jọ rìn yín mọ́lẹ̀.
Ní báyìí, mo tí ń padà r'aṣọ, àmọ́ òṣùwọ̀n mi ti dúró déédé. Mo mọyì ore ju àtẹ̀yìnwá. Mo mọ rírì oun tó dára tó sì yanrantí si. Mi ò pàdánù púpọ̀ mọ́, bẹ̀ẹni mò ń gbìyànjú láti dí ye lé àwọn ènìyàn tí ó ṣe àwọn nǹkan tí mò ń lò nípa ṣíṣe àṣàrò bí mo ṣe ń ra ọjà. Kọ́lọ́fín ìpamọ́ aṣọ mi ti joro, àmọ́ ìgbésí ayé mi wá ní ìtumọ̀ si. Síbẹ̀, oun tí ó dára jù nípa jíjọ̀wọ́ àwọn ẹrù inú ayé mi ni ìyànda àti àǹfààní láti sin Olùṣẹ̀dá tó tayọ jùlọ.
Sáárà, bíbọ́ kúrò lọ́wọ́ kíkó ẹrù jọ
Gbàdúrà: Ọlọ́run, ǹjẹ́ ọ̀nà kankan wà tí mo ti gba ẹrù kíkójo láyè láti dínà ìfẹ́ mi sí Ọ àti sí àwọn aládùúgbò mi bi? <
Nípa Ìpèsè yìí

Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.
More