Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú WúwoÀpẹrẹ

Jíjọ̀wọ́ Àníyàn àti Àbámọ̀
Wo ibí ná. Má ṣe àníyàn nípa rẹ́. Ohunkóhun tó wù kó jẹ̀, má ṣe àníyàn.
Ò ń ròó l'ọ́kàn rẹ pé ẹnu dùn ún r'ófọ́, abi?
Lóòtọ́, kò r'ọrùn. Àrùn ìpayà ati OCD ń bá mi f'ínra lójóojúmọ́. Lọ́jọ́ tí ñkan bá ṣ'ẹnuure gan, mo mọ̀ pé àrùn yí sì wà l'ára mi, ní kẹ́lẹ́ ọkàn mi, tí ó ń jìjàdù láti bá mi kanlẹ̀. Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé, èyí kìí ṣe òpin ìtàn náà.
Olọ́run kò dá wa láti máa gbé nínú ẹ̀rù. Mi ò sọ pé kò sí ohun ẹ̀rù nínú ayé yìí. Mi ò sì sọ pé mi ò kí ńṣe àkóléyà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lè ṣẹlẹ̀ bíi ìbáṣepọ̀ tó gúnmọ́ tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí ńkan p'agi d'ínà rẹ̀, àdánù nínú ètò ìṣúná, àwọn ànfààní tó bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́, àbí àwọn àjálù búburú míràn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀rù yìí tí a bá ńkó wọn lé àyà báyìí, wọn yíò mú wa máa fò'yà ọjọ́ iwájú nígbà gbogbo, èyí yíò sì máa mú wa gbe àwọn ìgbésẹ̀ ti yíò yori sí àbámọ nípa àwọn ohun tí ò ti ṣẹlẹ̀ sẹ́hin.
Mo ti mọ̀ báyìí pé jíjọ̀wọ́ àwọn àníyàn ọkàn, a máa mú kí ènìyàn gbé ìgbé ayé tí kò ní àbámọ̀ nínú.
Àṣírí ibẹ̀ rèé: Ọlọ́run kò fún wa ní okun láti máa ṣe àníyàn tabi k'ábàmọ̀, ṣùgbọ́n Ó fi t'ìfẹ́tìfẹ́ fún wa ní ànfààní láti gbó'jú sókè sí Òun kí a sì wi fún ùn pe, "Se O lè bá mi gbé ẹrù yìí?" Ìdáhùn Rẹ̀ sí wà nígbà gbogbo ni'pé "Tayọ̀tayọ̀ ni n Ó bá ọ gbe, Mo ti ń retí kí o pe mi síi." Lẹ́hìn èyí, àwa náà yíò bá s'ípá, a ó jọ̀wọ́ ohun gbogbo, léra, léra àti léraa wọn.
Bákannáà, ẹ̀ jẹ́ kí á gbà pé a ò le ṣe aláìmáṣe àṣìṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àjálù ibi yíò ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, Ìfẹ́ Ọlọrun borí ẹ̀rù mọ́lẹ̀.
1. Ọlọ́run kò kàn jókòó sí ìbi kan k'O máa ronú bí Òun yíò ṣe bá ọ́ l'áyé jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ire ní Ó ńrò sí ọ, láì déènà p'enu, Ó n'ífẹ̀ rẹ̀ gidi.
2. Nígbà tí àjálù ibi bá ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run a máa lò wọ́n láti fi ọ́ rọ ohun tí ó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nítorípé O fẹ́ràn rẹ.
Nígbàtí jìnnìjìnnì bá bò ọ́, bíi ẹnipé ibi ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, tàbí ibí tí dé bá ọ gan an, tí ò sí jẹ́ pé ǹkan tí ó kọ́ sọ sí ọ lọ́kàn ni pé, dúró, fi ohun gbogbo sílẹ, máa ṣ'àníyàn - má ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, lo okun tí Ọlọ́run fúnọ kí o sì ké sí Í nípa ádùrá, kíka Ìwé-Mímọ́, kí o sì bá àwọn olóòótọ ènìyàn gb'ìmọ̀ran pọ.
Dán èyí wò:Gb'àdúrà lóhùn òkè sí Ọlọ́run. Sọ fún ùn pàtó ohun tí o k'ábàmọ̀ rẹ̀ tàbí ohun tí ò ńṣe àníyàn lé lórí. Sọ fún Ọlọrun pé o kó gbogbo rẹ̀ lé E lọ́wọ́. Lẹ́hìn èyí, rán ara rẹ l'étí àwọn òtítọ́ nípa Ẹni tí Ọlórun jẹ́ àti ẹni tí Ọlọ́run dá ọ láti jẹ́.
Ìpayà kò ṣe àkàwé Tommy
Nípa Ìpèsè yìí

Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.
More