O. Daf 147:7-11

O. Daf 147:7-11 YBCV

Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru: Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun, ẹniti o pèse òjo fun ilẹ, ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla. O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún. Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin. Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀.