ORIN DAFIDI 147:7-11

ORIN DAFIDI 147:7-11 YCE

Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa. Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run, ó pèsè òjò fún ilẹ̀, ó mú koríko hù lórí òkè. Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ, tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké. Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí, kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà. Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.