Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi. Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti. Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin. Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi. Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.
Kà Jer 29
Feti si Jer 29
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jer 29:10-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò