Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbíÀpẹrẹ
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, a gbé ìgbésẹ̀ láti tẹ̀síwájú nínú ìpè Ọlọ́run fúnwa láti mú ẹbíi wa gbòòrò nípasẹ̀ gbígba ọmọ tọ́. A mọ̀ wípé yóò le, ṣùgbọ́n a ti pinnu láti jẹ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Jésù fún àwọn ẹbí tó ń la ìgbà àìní kọjá. A ṣetán nígbà náà láti yí ayé padà. Láìmọ̀ wípé Ọlọ́run náà ń gbaradì láti yí ayéè tiwa náà padà.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn níí máa sọ fúnwa wípé ẹni ọ̀tọ̀ niwá fún èyí tí à ń ṣe yìí. Ṣùgbọ́n jẹ́kí nsọ àṣírí kan fún ọ: kò sì ǹkankan tó ṣe pàtàkì nípa àwọn òbí tí ńgba ọmọ tọ́. A ti wówa palẹ̀; a máa ń kùnọ̀; a máa ń pariwo, àti wípé kìí ṣe ohun gbogbo ní ìkápá wa ní ńlọ geere. A jẹ́ awọn ènìyàn lásán tó ń rìn nípa ìgbàgbọ́ tíí sì ń lúwẹ̀ẹ́ nínú ìkùnnọ̀. Ǹkan tí ó ṣe pàtàkì, kàn ní, ohun tí Ọlọ́run máa ńse tí a bá gbọ́ràn.
À ti rí ìwàláàyè Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà gẹ́gẹ́ bíi ẹ́bií alágbàtọ́ ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, tí Ó sì ń mú ìdíwọ́ kúrò ju t'àtẹ̀yìnwá. Nígbà tí a sọ ìrètí nù nípa Ìbá ṣe pẹ̀lú àwọn òbí tó bí ọmọ kan, Ọlọ́run farahàn. Nígbà tí a nílò láti ṣe ó dìgbà sì àwọn ọmọ tí ati gbàtọ́, Ọlọ́run farahàn. Nígbà táa lérò wípé a lè má rí ọjọ́ mìíràn, Ọlọ́run farahàn.
Ìrìn àjò yìí ti rànwá lọ́wọ́ láti ní òye nípa bí Ọlọ́run ti ńrí wa. Gẹ́lẹ́ bí a ti ńgba àwọn ọmọ tó ní ẹ̀dùn wọlé sínú ilée wa, Ọlọ́run pẹ̀lú tí gbà wá wọlé sínú ẹbíi rẹ̀. Òhun ni Bàbá wa tí ńbẹ ní Ọ̀run àti olùgbèjà wa. Kìí bìkítà irú ìṣòro tí a ní, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá, tàbí ibi tí a kùsí. Tí a bá tọ̀ọ́ wá, yóò dìrọ̀ mọ́wa bíi bàbá, fẹ́wa láì ní ìdiwọ̀n, yóò sì pè wá lọ́mọ rẹ̀ pẹ̀lú.
Tí o bá lérò pé o kò pójú-òṣùwọ̀n, tí ó bá lérò wípé òń kojú ohun tí kò ṣeéṣe, tàbí ìgbésẹ̀ tó kàn kò tilẹ̀ yéọ, mo máa rọ̀ọ́ láti wá ojú Ọlọ́run fún ìjọba rẹ̀. Àwọn ènìyàn lè ríọ bíi aláàgọ̀ná. Kódà, ó dámilójú wípé wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n mo lè fún ọ ní ìdánilójú yìí: Ọlọ́run ti ń súré tẹ̀lé ọ. Ó sì ní ètò fún ayéè rẹ tó kọjáa ohunkóhun tío lèrò lónìí.
Taylor Ketron
Alábòójútó fún YouVersion
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.
More