Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbíÀpẹrẹ

7 Things The Bible Says About Parenting

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ní oṣù kẹfà 2020, èmi àti aya mi ńretí ọmọ wa àkọ́kọ́. À ńjẹ oúnjẹ alẹ́ pẹlú bàbá mi, nitorinà mo pinnu láti bèrè fún ogbón. Mo bèèrè lọwọ bàbá mi kí o fún mi ní ìmọ̀ràn tí o dára jùlọ nípa ìtọjú ọmọ láti inú ìṣúra ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òbí.

Ó ronú fún isẹju díẹ̀, ó wá fúnmi ní àpẹẹrẹ tí èmi kì yio gbàgbé. Bàbá mi sọ wípé ìtọjú ọmọ dàbí ìwọ̀n - kò kí í se bíi èyí tí a ńdúró lé láti wọn ara wa, sùgbón bíi èyí tí o rí bí ààmì ìdájọ́. Ìfẹ́ wà ní ẹgbẹ́ kan; ní apá Kejì ìbáwí. Lílo ọ̀kan ní ìgbà gbogbo láìsí èkejì máa jẹ́ ìpalára fún ọmọ rẹ.

Bàbá mi túnbọ̀ sàlàyé wípé bí o bá se fi ìfẹ́ hàn sí ọmọ rẹ, ni wọn yóò ṣe gba ìbáwí. Àti wípé bí ọ bá se ìbáwí tí o pọ, o nilo láti jẹ́ kí wọn mọ bí o se n'ifẹ wọn tó. Ìfẹ́ púpò láìsí ìbáwí lè ba ọmọ jẹ́, bákannáà ìbáwí púpò láìsí ìfẹ́ lè pá ọmọ lára, tíó sìlè lé wọn kúrò.

Láti ọjọ́ yí lọ, lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni mo máa ńro ìbámu láàrin ìbáwí àti ìfẹ́. Mo n'ígbàgbọ́ pé inú àwọn òbí kìí dun tí wọn bá mba ọmọ wí. Kò ńṣe ohun tí wọn má ń gbádùn láti ṣe. Ó le sùgbón, ó dára. Nítorí náà màá gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn kí o lo ìwọ̀n kànnà fún ìbáwí ọmọ kí wọn le mọ pé ọ fẹ́ràn wọn àti pé o bìkítà nípa wọn.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe fẹ́ràn àwọn ọmọ wa tí a sì nílò láti bá wọn wí, Bàbá wa tí ńbẹ ní ọ̀run fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì b'áwọn wí. Tí iwọ bá ti gba Jésù ṣí inú ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà, lẹ́yìn náà Ọlọ́run ti di Bàbá rẹ̀. A ti gbà ọ sínú ìdílé e rẹ̀

Brad Belyeu
Amojú-Ẹ̀rọ fún YouVersion

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

7 Things The Bible Says About Parenting

Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.

More

A fé láti dúpe lówó YouVersion fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ si, jọwọ lọ sí: http://www.bible.com/reading-plans