Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbíÀpẹrẹ

7 Things The Bible Says About Parenting

Ọjọ́ 1 nínú 7

A gbé ẹsẹ Bíbélì yí kọ nínú yàrá ọmọ wa kí a tó gbé dé láti ilé ìwòsàn, a ṣì nri ní alaalẹ́ tí a bá ti gbé sórí ibùsùn rẹ. O jẹ ohun tí ń ránwa létí nípa ìpè àti ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa l'ọ́wọ́ gẹgẹ bí òbí rẹ.

Gẹgẹ bí òbí, a kọkọ ní ojúṣe láti kọ àwọn ọmọ wa ni ìpìlè ìgbàgbọ. Bí a fẹ tàbí a kọ, a nṣe àpèjúwe ìgbàgbọ fún àwọn ọmọ wa l'ójojúmọ́. Gbogbo ọ̀rọ̀, gbogbo ìgbésè, àti gbogbo ohun tí a bá ńṣe ni a fí ńṣe àpèjúwe. Ṣíṣe ohun tí o pé l'ójojúmọ́ àti gbogbo ìgbà lè má rọrùn fún wa gégébí òbí. Bóyá o ṣẹ àìsùn nítorí ìtọjú ọmọ, o ńkọ́ ọmọ láti dá se ìgbọ̀nsẹ̀, ò ńṣe àkóso iṣẹ́ amurele àti àwọn iṣẹ́ ilé-ìwé, tàbí ọkọ wíwà, iṣẹ́ òbí le púpọ. A gbọdọ̀ rántí pé Ọlọ́run kò rètí pé kí a ṣee nípa agbára wa. O féràn àwọn ọmọ wa ju bi a se le fẹràn wọn!

Ònà méjì tí o rọrùn fún wa láti tọka àwọn ọmọ sí Ọlọrun

1. Gbàdúrà fún wọn àti pẹlú wọn lójoojúmọ́Àdúrà déédé jẹ ohun tí ó se pàtàkì láti kọ́ ìpìlè ìgbàgbọ fún àwọn ọmọ. Gbàdúrà fún wọn àti pẹlú wọn lójoojúmó. Má dàá ádùrá fún àwọn ọmọ rẹ dúró. Má jẹ̀ kí ipò tí wọn wà lọ́wọ́lọ́wọ́ bojú agbára Ọlọ́run. Pàápàá bí ọmọ rẹ ba ń sá kúrò lọdọ Ọlórun lọ́wọ́ lọ́wọ́. Wọ́n wà ní àrọ́wọ́tó àdúrà sí Ọlọ́run. Àdúrà lè yí ohun gbogbo padà.

2. Máse dá ṣeé Wọ́n ma ńsọ pé ìtọjú ọmọ wẹwẹ ti gbogbo ará ni. Ìwọ yóò nílò àwọn ènìyàn nínú ayé rẹ tí wọ́n yìo ràn ọ lọwọ́ láti tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tíó tọ́. Gbogbo ìdílé gbudọ ma lọ sí ilé ìjósìn papọ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìdílé ní ilé Ọlọ́run. Ẹ darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ kékèké tí wọ́n kún fún àwọn ènìyàn tó ṣeé gbára lé ní gbogbo àkókò ìtọjú àwọn ọmọ. Gbogbo wa la nílò ará, ó sì ṣe pàtàkì fún ọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ní Ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tí o ní orísun ìgbàgbọ́ tí ó jinlẹ̀.

Kò tíì pẹ jù láti bẹrẹ igbesẹ ìgbàgbọ àwọn ọmọ rẹ. Kò sì tún tíì yájù láti bẹ̀rẹ̀. Ṣètò ipa ọ̀nà ìgbàgbọ́ fún àwọn ọmọ rẹ, kí ọ ṣì bẹ̀rẹ̀ síi tọ́ka wọn sí Ọlọ́run ní báyìí.

Todd Dobberstein
Olùṣàkóso fún àwọn Ètò YouVersion

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

7 Things The Bible Says About Parenting

Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.

More

A fé láti dúpe lówó YouVersion fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ si, jọwọ lọ sí: http://www.bible.com/reading-plans