Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbíÀpẹrẹ
Èmi ni mo kéré jù nínú àwọn ọmọbìnrin méjì ní ìdílé tí a bí mi sí, nítorí náà ìgbà èwe mi kún fún ohun ìmúṣẹrè púpọ̀, eré nínú ilé ìdáná tí a fi n'sere, oríṣiríṣi eré tí àwọn ọmọbìnrin má nṣe - àwọn eré tí kò ní ìjàngbọ̀n, àwọn eré tí kò léwu. Ní báyìí, mo ti di ìyá ọmọkùnrin méjì tí ọjọ́-orí wọn kò tíì tó ọdún máàrún, ilé mi kò fi ǹkankan jọ ibi tí mo ti dàgbà. Gbígba ádùrá fún àwọn ọmọ mi ti di ohun pàtàkì fún mi nínú ìrìn àjò òbí, ní pàtàkì nítorí ìjàngbọ̀n àwọn ọmọkùnrin mi. Ìyá ọkọ mi ti sọ tẹlẹ fún mi wípé ìtọjú àwọn ọmọkùnrin le púpò nítorí ìjàngbọ̀n wọn yóò mú mi mọ àwọn nọ́ọ̀sì pẹ̀lú iye ìgbà tí à ńlọ sí ilé ìwòsàn.
Èmi kò mọ̀ pé ní ọdún díẹ̀ nínú irin-ajo ìtọjú ọmọ, èmi yóò rí kí ọmọ mi tí o dàgbà jù ṣubu pẹ̀lú ojú rẹ nilẹ (tí o sí kán gbòngbò eyin rẹ̀) lẹyìn náà, bíi ọdún kan sí ìgbà yii, o tún fi orí ṣubú (ìyẹn yọrí sí riran orí rẹ lọnà méta). Èmi kò tún mọ pé wọn yóò ṣiṣẹ́ abẹ fún ọmọ mi tí o jẹ oṣù mẹwa nígbà náà nítorí àlébù kan tí a bí pẹ̀lú. Ipò kọ̀ọ̀kan yìí ti kúrò pátápátá ní ìkápáà mi. Ko sí ohun kan tí miò bá ti se láti se ìdíwọ́ fún gbogbo àwọn ǹkan tí o ṣẹlẹ̀ yìí - èyí ló mú mi lọ sórí oókún mi nínú àdúrà fún àwọn ọmọ mi.
Gẹ́gẹ́ bí òbí, àwọn ọmọ wa jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí a gbọ́dọ̀ pèsè fún, dáàbò bò, fi ìfẹ́ àti Ore-ọ̀fẹ́ Jésù hàn, àti láti jẹ́ kí wọ́n gbaradì fún ìrìn àjò ayé wọn. Ipò tí wọn wà lójoojúmọ́ tàbí gbogbo ìrìn àjò ayé won kò nṣe nkan tí a le pinnu fúnra wa - tàbí ohun tí a lè se ìṣàkóso lé lórí. Nítorí náà kíni àwa òbí fẹ́ ṣe lẹ́hìn ohunkóhun, nígbàtí a bá ti lo gbogbo agbára wa ṣe ìtọ́jú ọmọ tí yóò láàánú, tí yóò ní ìtẹríba, ọmọ tí yíò bu ọlá fún Ọlọ́run àti ọmọ tí yíò wà ní àlàáfíà àti àìléwu? A lè mú ìṣòro wa, àníyàn, àwọn ìrètí tí kò tíì ṣẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run - kí a sì dupẹ wípé kìí se dandan ko jẹ pé àwa ni a o se ìsàkóso.
Kí o máṣe rẹ̀ wá bí a ṣe ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ wa àti bí a se ńfi wọ́n lé Ọlọ́run l'ọ́wọ́ pẹ̀lú ìgbẹkẹ̀lẹ́ àti ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá wa - ẹni tí o fẹràn àwọn ọmọ wa ju bí a se lè fẹràn wọn, tí o sì di wọn mú pẹlu ọwọ́ agbára rẹ̀
.Lisa Gray
Olùṣàkóso Èdè fún YouVersion
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.
More