Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbíÀpẹrẹ

7 Things The Bible Says About Parenting

Ọjọ́ 5 nínú 7

Gbogbo wa lafẹ́ àwọn ọmọ ti ń fini lọ́kàn balẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? Nígbà míràn, ohun tí a ń túmọ̀ èyí sí niwípé afẹ́ kí àwọn ọmọ wa dàbíi wípé wọ́n ń wùwà dáradára s'ẹlòmíràn. Èyí le túmọ̀ sí wípé kò sí erépá, ó sì lè túmọ̀ sí sísọ “jọ̀wọ́” àti “o ṣeun” nígbà tíó yẹ. Nísìnyí tí àwọn ọmọ mi ti ń dàgbà, moti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbàárò bóyá gbogbo ìlàkàkà mi láti mú wọn ṣeé wò lójú maní ìwúlò nínú irú ènìyàn tí wọn yóò jẹ́ nínú ọkàn wọn.

Láàrin ọdún méjì, ọmọbìnrin mi àgbà mawọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Miò kí fẹ́ ròó, ṣùgbọ́n nkò ní sí níbẹ̀ láti ri wípé ó ńṣe ohun gbogbo lọ́nà tótọ́. Nítorí náà, mò ń sa gbogbo ipá mi láti ríi wípé ohùn mi ńrókì nínú oríi rẹ̀, fún àwọn ìgbà tí yóò máa làkàkà láti ṣe ohun tíó tọ́ọ. Ìbá tún dára, tó bá jẹ́ ohùn Ọlọ́run ni ọmọbìnrin yìí ń gbọ́? Nítorí yóò wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà—ní àwọn ìgbà tí nkò lè sí níbẹ̀ pẹ̀lú.

Ọ̀nà kan gbòógì tí afi lè ríi dájú wípé àwọn ọmọ wa dá ohùn Ọlọ́run mọ̀ ni láti kọ́ wọn ní Ọ̀rọ̀o Rẹ̀, ṣùgbọ́n kíkàá sí wọn létí lásán—tàbí kíkọ́ wọn bíi àkọ́sórí—kò lè tó. Tío bá fẹ́ rí ìyípadà àwọn ọmọọ̀rẹ nípasẹ̀ agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn nílò láti rí iṣẹ́ẹ rẹ̀ nínúù rẹ —bí óti ń darí ìgbésí ayéè rẹ àti àwọn ìpinnu tí ìwọ ńṣe lójojúmọ́. Jókòó láti báwọn sọ̀rọ̀. Sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ọkọ̀. Yáan nínú ọ̀rọ̀ ìgbà afẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ran àwọn ọmọọ̀rẹ lọ́wọ́ láti ríi yéké bí ohùn Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí ń darí ayéè rẹ. 

Nígbà Kanńà, ran àwọn ọmọọ̀rẹ lọ́wọ́ láti ní ìrírí Bíbélì fúnra wọn kí ìwọ sì jẹ́ atọ́nisọ́nà fún wọn. Ọ̀se pàtàkì fún wọn láti kọ́ fún rárá wọn bí a tií ńka Bíbélì àti bí a tií tẹ́tí sí Ẹ̀mí Mímọ́. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan ètò Bíbélì kan, kí o sì bèrè ìbéèrè tí wọ́n bá kàátán. Ìmọ̀ràn díẹ̀ ni wọ̀nyí lóríi bío tílè bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀ náà: 

  • Kínní ohun tíó jẹyọ nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ l'ọ́sẹ̀yí?
  • Ǹjẹ́ o ti ka ohunkóhun tó rú ọ lójú nínú Bíbélì?
  • Ǹjẹ́ o ni ǹkan tío ti kà tóo sì nílò àlàyé díẹ̀ lóríi rẹ̀?
  • Kíni Ọlọ́run ńkọ síọ nípasẹ̀ ibi tí ò ń kà?
  • Kíni ǹkánkan nínú ayéè rẹ tí ibi tí okà lè mú ọ yí padà?

Gẹ́gẹ́ bí òbí, à ń múgbá lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ láti kọ̀ àwọn ọmọ wa nípa Ọlọ́run àti ìjọba Rẹ̀. Ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínúu Rẹ̀ fún ìyípadà àtinúwáa wọn. Ó fẹ́ràn wọn ju bí a tilè fẹ́ràn wọn lọ.

 

Michael Martin

Elétò Ìmọ̀-ẹ̀rọ fún YouVersion

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

7 Things The Bible Says About Parenting

Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.

More

A fé láti dúpe lówó YouVersion fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ si, jọwọ lọ sí: http://www.bible.com/reading-plans