Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbíÀpẹrẹ

7 Things The Bible Says About Parenting

Ọjọ́ 6 nínú 7

Mo rọbí fún ọgọta wákàtí. Ọgọta wákàtí tí o nira, pẹ̀lú àníyàn. Àwọn obìrin kan má n kérora nípa iye wákàtí tí wọn fi robí, àwọn obìrin míràn ríi bí ohun amuyangan. Mo rò pé emi rii bíi ohun amuyangan nítorí ìwúrí ni gbogbo wákàtí irobi yìí jẹ fún mi.

Ṣugbọn ìwúrí yìí fo lọ ní kété tí ọmọkùnrin mi bẹrẹ sí ní sọkún láàrin òru, ní wákàtí díẹ̀ lẹyìn tí mo bíi. "Kini ìtumò ẹkun yìí?, Ṣé ebi npa a ni?, Báwo ni mo se fẹ mo ìdiwọ̀n ohun tí n yíò fún?, Njẹ́ o fẹ́ nkan míràn bí?Níbo ni nọ́ọ́sì wà?!?"

Bí mo ṣe pàdé ọmọ mí fúnmi ní èémí ọpẹ́ tí nkò le sàlàyé fún ẹbùn ẹ̀míi rẹ̀. Sùgbón lẹ́yìn ọpẹ́ yìí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iyèméjì, ìbẹrù àti àìgbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bíi ìyá titun, o dà bí mi o tí gbaradì láti dojúkọ ìtọjú ọmọ.

ká sọ òtítọ́, àwọn èrò yii kò tíì fi mí silẹ láti ìgbà náà. Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ:

Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò sì fún un. Nítorí Ọlọ́run lawọ́, kì í sìí sìrègún Jákọ́bù 1:5

Ọlọ́run fi ìpele titun ti inú rere rẹ̀ hàn mí pẹ̀lú ẹbun ọmọ bíbí, ipò titun yìí mú kí nfi ìrẹ̀lẹ̀ bèèrè fún ọgbọn lọ́wọ́ Ọlọ́run. Ó ṣe olóòótọ́ bí ọ ṣe ń tọ́mi sọ́nà nínú ìtọjú ọmọ pẹlu ọgbọ́n ní gbogbo ìgbà tí mo bá tọ̀ọ́ lọ pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti jíjọ̀wọ́ ẹ̀míì mi sílẹ̀.

Mo lérò wípé o mọ àwọn ohun èlò iyebíye tí o ní nínú Kristi. Ó fẹ́ láti máa ṣe inú rere fún ọ nínú ọnà tí o gbé ntọjú ọmọ. O fẹ́ ṣe síi ju bí ìwọ ti lérò kí ọmọ rẹ̀ lè mọ̀ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, ṣe ìránṣẹ́, àti láti tọ́ọ sónà. Krístì jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti onínúrere, o sì ṣetán láti fún ọ. Ṣé ìwọ ṣetán láti gbàá?

Lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa onínúrere, kí ọ sì béèrè fún ọgbọ́n bí iwọ ṣe ńla ìpènijà ìtọjú-ọmọ kọjá. O ṣetán láti fún o

Jessica Penick

Olùṣàkóso Ìwé-Kíkọ fún YouVersion

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

7 Things The Bible Says About Parenting

Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.

More

A fé láti dúpe lówó YouVersion fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ si, jọwọ lọ sí: http://www.bible.com/reading-plans