Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá ỌlọrunÀpẹrẹ

Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun

Ọjọ́ 6 nínú 7

Òmùgọ Ọlọrun sí Àgbàrá Ọgbọn Eniyan 2

Yiyansipo Ọlọrun jẹ ẹkọ gbọrọ àti àkòrí gbòòrò láti ṣe àwárí ni tiẹ. Ti o bá wó fínífíní ámā yà ọ lẹnu ni. Nígbà ti Ọlọrun fẹ Yan Orílẹ̀ èdè ti yóò jẹ tìrẹ O yan Abrahamu ati Sarah ti wọn ti gbó lọjọ̀ orí láì ni Ọmọ kan.

Nígbà ti Ọlọrun fẹ Yan Oba míràn fún Israẹli dipo Saul, O Yàn ọdọmọkunrin olùṣọ àgùntàn ti kó ni ìrírí ògùn jija. ọdọmọkunrin na ni Ọlọrun lò lati pá Goliati ati ògùn filistini to halẹ mọ Israẹli lẹnu mọ.

Nigbati Ọlọrun fẹ mú Olùgbàlà ẹda eniyan wá sí ayé, O YànWundia ti a o mọ rárá, to wà ni ipò ìrẹlẹ, ni Nazareti, bakanna àbí Jésù ni ẹyà Israẹli to kéré jù, Betlehemu.

Nigbati Jésù bẹrẹ iṣẹ iransẹ Rẹ ni ayé, awọn apẹja merin lọ kọkọ pé bi ọmọ ẹlẹyin, ọkan ninú mẹrin yi, Pétérù lò pàdà di adari fún awọn ọmọ ẹlẹyin kristi. Kini ẹkọ ti a ri kọ nínú èyí? Nínú ètò Ọlọrun iwọ ṣí lọ dára jùlọ fún Ọlọrun lati Yàn, lainika ṣe pẹ̀lú bóyá o yẹ nipa ti àrà abi ìmọ tabi àìlera rẹ, Ọlọrun ṣi lè ṣe òhún nla pàtàkì láti inú rẹ.

Siwaju sii kika: 1 Samueli 16:5-13, Luku 1:26-28, 2:1-7, Matteu 4:18-22

Adura: OLUWA, mo fi àrà mí fún Ọ, sọ àìlera mi di àgbàrá fún ìhìnrere Rẹ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun

Ìgbé ayé ninú Kristi láìsí iyemeji tayọ ìgbé ayé ẹlẹran àrà, ẹsìn tabi aṣa bi ìwà mimọ ati titẹle òfin. Ṣugbọn o jẹ ìgbé ayé àgbàrá ati Ọgbọn, ìgbé ayé tí a ni lati inú iyé ainipẹkun Ọlọrun. Kristi wà sáyé láti gbé 'nú rẹ àti lati fi ìyè hàn onigbagbọ nínú rẹ, onigbagbọ nínú Kristi jẹ alabapin àyè yìí nipasẹ dídì Atunbi ati Ẹmí Mímọ t'in gbé inú wọn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo:  https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL