Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá ỌlọrunÀpẹrẹ

Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ona Ọlọrun Tayọ Ti Eniyan

Ọlọrun ni gbogbo ìgbà amáa ṣe ohun to kọja akojọpọ èrò èèyàn, awọn ohun tí àbá ṣe iwadi ati àwárí amáa Muwá pórúrù tabi kún fún iyalẹnu.

Gbogbo iṣẹ Ọlọrun jẹ ohun iyalẹnu, O ṣe gbogbo rẹ ninu ipele ogbọn Ọ̀run kìi ṣe ni ipele ogbọn eniyan, ti àbá n'wadi ọgbọn Ọlọrun pẹlu ọgbọn eniyan asan ni yíò já sí.

Gbogbo igbiyanju eniyan nipa ti àrà lati wadii iṣẹdá ló bi oniruuru èrò ọjọgbọn ati ẹkọ asán ti o takò àrà wọn ti ko mú ogbọn dani.

Bakanna ni pẹlu ìgbàlà ati ìràpadà wa, kọja èrò èèyàn,ohun to dára jù ni lati kọkọ gbagbọ kì a to ma ṣe iwadi bi a ṣe n dagba. Isé Òmùgò Ọlọrun sàn jù ọjọgbọn eniyan to dára jùlọ.

Siwaju sii kika: Jeremiah 21:11

Adura: OLÙWÀ, Ran mi lọwọ láti gbẹkẹ lé O bí ohun gbogbo o bá tilẹ yé mí.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun

Ìgbé ayé ninú Kristi láìsí iyemeji tayọ ìgbé ayé ẹlẹran àrà, ẹsìn tabi aṣa bi ìwà mimọ ati titẹle òfin. Ṣugbọn o jẹ ìgbé ayé àgbàrá ati Ọgbọn, ìgbé ayé tí a ni lati inú iyé ainipẹkun Ọlọrun. Kristi wà sáyé láti gbé 'nú rẹ àti lati fi ìyè hàn onigbagbọ nínú rẹ, onigbagbọ nínú Kristi jẹ alabapin àyè yìí nipasẹ dídì Atunbi ati Ẹmí Mímọ t'in gbé inú wọn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo:  https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL