Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá ỌlọrunÀpẹrẹ
Òmùgọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú Agbara Ènìyàn
Okùn Ọlọrun jẹ ifihan ohun tí O ṣe ni àfiwé sí ohun tí ènìyàn ṣe. Ẹsẹ bibeli tòní wá ọnà láti ṣe àfiwé òmùgọ Ọlọrun sí àgbàrá ọgbọn eniyan
Ọpọ àpèjúwe lọ wá nínú Bíbélì mimọ ti a ri awọn ìrírí bayii bi àwòrán to ṣe tọka sí, Ọlọrun pé awọn aláìlágbára diẹ lati fi awọn orilẹ-ede sí ipò ìrẹlẹ kí olè fi Ògo Rẹ hàn.
Ọlọrun pé Abrahamu nígbà ti a kó Lọti lẹru, Abrahamu kó ọrindinirinwo òdìn méjì eniyan lati jagun wọn sí ni iṣẹgun ti orileede mẹrin kólé ni, o gbà Lọti ati awọn ti wọn di ni igbèkun.
Ọlọrun sọ fún Joshua lati dari awọn ọmọ Israẹli lati yi òdì jẹ́riko lẹ méje, ni ọjọ keje kí wọ́n hó pẹlu fèrè kí odi Jeriko lè wò, eleyii dàbí ohun òmùgọ.
Ọlọrun pé Gideoni nínú ẹrú rẹ lati kọ àwọn eniyan jọ fún ògún, Ọlọrun din wọn kú sí ọdunrun láti dojukọ orilede Midiani, wọn sí ni iṣẹgun to laami-laaka.
Ọlọrun sọ fún ọba Jehoṣafati lati fi awọn akọrin ati onílù ṣáájú ogun ni idojukọ ọmọ-ogun orilede mẹrin, ohun to dàbí itọni òmùgọ yíjasi iṣẹgun lórí orilede mẹrin láì mú ìjà kan dání. Lotọ, Ọlọrun o nilo lati pé àwón ẹni nlá, alágbára ati ọlọgbọn lati ni iṣẹgun.
Siwaju kika: Genesisi 14:1-16, Jóṣúà 6:2-5, Awọn onidajọ 6-8, 2 Kíróníkà 20:1-24
Adura: OLUWA, Mọ yọnda àrà mí fún ipè Rẹ lati ṣe òhún to fẹ kín ṣe.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgbé ayé ninú Kristi láìsí iyemeji tayọ ìgbé ayé ẹlẹran àrà, ẹsìn tabi aṣa bi ìwà mimọ ati titẹle òfin. Ṣugbọn o jẹ ìgbé ayé àgbàrá ati Ọgbọn, ìgbé ayé tí a ni lati inú iyé ainipẹkun Ọlọrun. Kristi wà sáyé láti gbé 'nú rẹ àti lati fi ìyè hàn onigbagbọ nínú rẹ, onigbagbọ nínú Kristi jẹ alabapin àyè yìí nipasẹ dídì Atunbi ati Ẹmí Mímọ t'in gbé inú wọn.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Kristi Ọgbọn ati Àgbàrá Ọlọrun fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL