Kristi, Ifihàn Ọlọrun Baba sí WáÀpẹrẹ
Ọlọrun Tíó Kin Yípadà
Bi Ọlọrun ṣe jẹ alagbara ni gbogbo ikorita ati igba sibẹsibẹ nínú ìwà ati àmúyẹ kò yipada Lai.
Àkókò kò lè mú Ọlọrun dagba. Nínú ìwà òdodo, ṣiṣe idajọ lori ohun gbogbo ati iparun ìwà ibi, bakanna ni. Nipa àmúyẹ rẹ gẹgẹbi Ọlọrun to mọ ohungbogbo, to wa nibi gbogbo tó ní gbogbo àgbàrá ko yipada.
Ko le fi àrà Rẹ hàn nínú iṣe, ìwà ati àmúyẹ to yatọ sí ti atijọ. Báwo la ṣe lè Mọ aiyipada Rẹ? Láti inú Bíbélì. Njẹ ṣe àgbàrá ati Ògo Ọlọrun dínkù sí ti ayé Majẹmu Lailai ati igba ibẹrẹ Majẹmu Titun? Rara!
Ṣé Ọlọrun Atetekoṣe to jẹ ẹlẹdàá kàn na ni? Ṣé Ọlọrun Abrahamu, Isaki ati Jakọbu kán nà ni? S'ohun na ni Ọlọrun Òfin àti àwọn Wòlíì? Bẹẹni òún ní Ọlọrun kan na tíó farahàn ninu Kristi. Kristi ọkàn náà titi Lai.
Ti iwọ ba fi gbogbo ọkàn rẹ wáá, iwọ na yíò ríi nínú ẹkunrẹrẹ Ogo Rẹ. Igba ati àṣa iyipada, awọn ọlọrun nwaye ti wọn ti parẹ́, awọn orilẹ-ede ìjọba ti wọn ti parẹ́ ṣugbọn bakanna ni Ọlọrun, o lè farahàn sí ọ bakanna.
Kíkà síwájú: Hébérù 13:8
Adura: Jésù Olùwà farahàn ninu ayé mi gẹgẹ bí Ọlọrun tíó yipada.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbélì jẹ iwe èto itan bi Ọlọrun ṣe fi ara rẹ hàn fún ẹdá ènìyàn. Ojẹ àlàyé bi Ọlọrun to fẹran iṣẹda rẹ, pẹlú ipò ìṣubú wọn, síbẹ o nọwọ rẹ lati fi kanwo, lati gb'awọn lá, wo wọn sàn ati tuwọn ni ide Kúrò lọwọ ikú ati iparun ayérayé. Èrò idi fún ẹkọ yi ni lati ran wa lọwọ ki ale mọ̀ Ọlọrun baba lati inu Kristi Ọmọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL