Kristi, Ifihàn Ọlọrun Baba sí WáÀpẹrẹ
Ìdápadàsipo
Alaye Nihin ṣafihan bi Ọlọrun ṣe fi ará rẹ hàn ẹdá èèyàn láti ìgbà dé ìgbà.
Sibẹsibẹ, oyẹ ki a kíyèsi pé ni atetekọ̀ṣe Ibasepo Ọlọrun pẹlu eniyan gẹgẹbii ẹdá rẹ to gajulọ́ òjé tārãta láìsí Angẹli tabi Wòlíì,
Ibaṣepọ Ọlọrun pẹlu èèyàn jẹ tãrãta nitori Ọlọrun da èèyàn ni àwòrán ara rẹ, láti Adamu dé Kaini (ni ipò ìṣubú èèyàn ati ìwà ipaniyan Kaini) Ọlọrun nbá eniyan ni gbólóhùn po ni óhùn sí òhun, Ọlọrun o nilo lati ran angẹli tabi Wòlíì lati ṣoju Rẹ.
Eleyii fi títóbi ohun ti a pàdánù hàn nípa wiwa pẹlu ati níní irẹpọ pẹlu Ọlọrun, a nilo ìdápadà sí ipò. Ọlọrun fẹ dá ibaṣepọ tí owá ni atetekọ̀ṣe pada; ọfẹ kí o sunmọọ, kí o gbọ ohun rẹ, kí o sí mọọ, ìdí tí Kristi fi wá parī iṣẹ ìgbàlà ni yii gẹgẹbii eni ti Ọlọrun Yan bí ajogún Ohun gbogbo.
Ṣugbọn oṣe pataki lati ri wàránsésa ìdápadà sí ipò, eleyi jẹ ìpàdánù to gajulọ ati àìní èèyàn tíó tobijulo ti Ọlọrun fẹ bojùtó. Ọlọrun fẹ kó pàdà ṣugbọn ṣe iwọ ṣetan àti pàdà lati ni ìdápadà sí ipò.
Kika siwaju: Jẹnẹsisi 3:8-9, Jobu 38:1-3, 40:1-4
Adura: Oluwa dami pada sínú irẹpọ pẹlu Rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbélì jẹ iwe èto itan bi Ọlọrun ṣe fi ara rẹ hàn fún ẹdá ènìyàn. Ojẹ àlàyé bi Ọlọrun to fẹran iṣẹda rẹ, pẹlú ipò ìṣubú wọn, síbẹ o nọwọ rẹ lati fi kanwo, lati gb'awọn lá, wo wọn sàn ati tuwọn ni ide Kúrò lọwọ ikú ati iparun ayérayé. Èrò idi fún ẹkọ yi ni lati ran wa lọwọ ki ale mọ̀ Ọlọrun baba lati inu Kristi Ọmọ.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL