Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ

Killing Kryptonite With John Bevere

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ó lé jẹ́ ìyàlẹ́nu wípé ète mí fún ọjọ́ kínní ètò yìí ni láti bà yín nínú jẹ́... Kí ni ìdí èyí?

Ìyàtọ̀ kedere wà nínú àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìjọ Májẹ̀mú Titun àti ìjọ òde òní. Yóò rọrùn láti fi ẹ́bi ẹ̀sùn yìí kan àwọn olórí, àṣà, ètò ìjọba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ ẹ jẹ́ kí a lo àsìkò yìí fi gbé ayé wa wò. 

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn onígbàgbọ́ àkọ́kọ́ jẹ́ ènìyàn alágbára ní ìran ti wọn, ayé sì wà ní ìwárìrì nítorí ti wọn. Díẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́ agbára wọn rèé:

Kò sí ẹnìkan nínú àwọn àdúgbò won tí ó kù díẹ̀ káàtó fún - kò sí ẹnìkan tí ó ní àìní àrà kan bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan tí ìjọba ń rán l'ọ́wọ́ nínu wọn (Ìṣe 4:33-35). Odindi ìlú jọ̀wọ́ ayé wọn fún Jésù nígbà kan náà, ìhìnrere sì tàn ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ́-èdè ní ìgbà kúkúrú (Ìṣe 9:32–35, 19:10). 

Agbára Ọlọ́run ṣiṣẹ́ nínú wọn ní ọ̀nà ìyanu tó béè gẹ́ tí wọn ní láti mú u dá àwọn ènìyàn lójú wípé wọn kìí ṣe ọlọ́run (Acts 10:25–26, 14:8–18)— ǹjẹ́ eléyìí ò ya ni l'ẹ́nu bí? Àwọn ìpéjọpò wọn máa ń l'ágbára dé bi wípé ilẹ̀ á mì (Ìṣe 4:31). Nítorí ìdí èyí, a mọ̀  wọn bíi àwọn ènìyàn tí ó yí ayé po (Ìṣe 17:6). 

Ohun tí ó yẹ kí ó pé wá níjà ni wípé Ọlọ́run fi hàn nínú Ọ̀rọ Rẹ̀ wípé àwọn Krìstìẹ́nì ìgbà ìkẹyìn yìó ṣe ju àwọn onígbàgbọ́ ìṣááju lọ. Ìbéèrè wa ni ìdí tí a kò fi rí àwọn iṣẹ́ nlá nlá, èyí tí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún wa.

Mo gbàgbọ́ wípé gẹ́gẹ́ bí Superman ṣe ní kríptónáìtì, ìjọ- èyí tíí ṣe ìgbájo pọ̀ àwọn ẹ̀dá tí ń tẹ̀lẹ́ Krístì - náà ní kríptónáìtì tirẹ̀ pẹ̀lú. 

Kríptónáìtì jẹ́ ohun àjèjì kan láti ìlú-u Superman. Ìgbàkígbà tí ó bá súnmọ́-on, agbára rẹ̀ à pòórá, yíò sì di aláìlágbára - kódà, ju ti ènìyàn lásán lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí a bá wo òṣùwọ̀n ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó, ìlò àwòrán ìwòkuwò, ìṣekúṣe àti àwọn ohun tó jọ mọ́-on ṣe ga nínú ìjọ lónìí, ó fi hàn ní gbangba wípé kríptónáìtì wà láàrin wa. 

Ipò ìjọ lónìí, tí ó jé ìdákejì ìfẹ́ àti ètò Ọlọ́run fún omolẹ́hín Krístì, yẹ kí ó bá yín nínú jẹ́. 

Nínú àwọn ẹ̀kọ́ yìí, a máa kọ́ ohun tí kríptónáìtì jẹ́, àti bí a ṣe lè gbé wọn kúrò. Àmọ́, a nílò láti kọ́kọ́ mọ̀, àti gbàgbọ́ nínú agbára wa, nítorí a kò lè lo agbára tí a kò mọ̀ wípé a ní. 

Nísinsìnyí ti ẹ ti mọ agbára yín, kí ló kù? 

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Killing Kryptonite With John Bevere

Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n. 

More

A fé dúpé lówó John àti Lisa Bevere (Messenger Int'l) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, ẹ lọ sí: http://killingkryptonite.com