Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri.
Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada,
O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn.
Nigbati awọn enia si ri ohun ti Paulu ṣe, nwọn gbé ohùn wọn soke li ède Likaonia, wipe, Awọn oriṣa sọkalẹ tọ̀ wa wá ni àwọ enia.
Nwọn si pè Barnaba ni Jupiteri ati Paulu ni Herme nitori on li olori ọ̀rọ isọ.
Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia.
Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara.
Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:
Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn.
Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin.
Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn.