Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.
Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: “Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.