Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ
Báwo ni ayédèrú Yahweh ti gbèrú ni Ísírẹ́lì, àti wípé báwo ni ayédèrú Jésù ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìjọ òde-òní? Méjèèjì ló wáyé nípasẹ̀ àyà líle tí àìní ìrònúpìwàdà òtítọ́.
Má wàá jẹ́ k'áyà ó fò ọ́. Mo mọ̀ wípé ọ̀pọ̀ ti wàásù ìrònúpìwàdà lọ́nà tí ń mú ìdè wá, ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe irú ìrònúpìwàdà tí Bíbélì fi lélẹ̀. Lótìítọ́ ni a nílò ìrònúpìwàdà, nítorí láì níi a kò lè ní ìrírí ìyè tí Ọlọ́run ti ṣètò fún wa.
Tí a bá ṣe àgbéyèwò ohun tí Bíbélì sọ, a ó ríi pé kìkìdá gbogbo ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Titun ló fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ wípé ìrònúpìwàdà pọn dandan fún Ìgbésí-ayé wa nínú Kristi. Àwọn tí ó mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ yìí ni Pétérù, Pọ́ọ̀lù, Jòhánù, Jákọ́bù, àwọn ọmọ lẹ́yìn mìíràn, Jésù fúnra rẹ̀, àti Ọlọ́run Baba pẹ̀lú. Ó jẹ́ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì àti èyí tí ó hàn kedegbe.
Ìtumọ̀ èyí ni wípé kò lè sì ìgbàgbọ́ òtítọ́ láì sí ìrònúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́. Àti wípé kíni ẹ̀ṣẹ̀? Ẹ̀ṣẹ̀ ni ìdàkejì ẹ̀bùn Ọlọ́run tó dára jù lọ.
Ìtumọ̀ èyí ni wípé a kò lè jẹ́ ti Kristi láì ṣe pé a kọ àwọn ǹkan bíi ìwà àìmọ́, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, àti àìní ìdáríjì sílẹ̀.
Báwo ló ti ṣeéṣe fún ọ láti mọ̀ọ́mọ̀ dìrọ̀mọ́ àwọn ǹkan wọ̀nyí kí o sì tún máa pé araà rẹ ní Kristẹni? Ohun tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni wípé, òfin ìwà híhù ọgọ́rùn-márùn-ólé ló wà nínú Májẹ̀mú Titun. Ọlọ́run fi àwọn òfin yìí lélẹ̀ nítorí Kò ní gba ǹkan tí yóò pa ọ́ run láyè láíláí—Ó fẹ́ràn rẹ rékọjá.
Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dìrọ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù tìtorí rẹ̀ kú, a ti ṣẹ̀dá Jésù ayédèrú, àti ìgbàgbọ́ àgbélẹ̀rọ nìyẹn.
Ìrònúpìwàdà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó ga jùlọ, èyí tí yóò ṣí ayé wa payá sí ìyanu ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Kódà, Ọlọ́run ṣèlérí láti fún wa ní ore-ọ̀fẹ́ nígbà tí a bá rẹ arawa sílẹ̀ (Jákọ́bù 4, Pétérù Kínní 5). Èyí ni ìdí tí ìrònúpìwàdà fi ṣe pàtàkì . . . kìí ṣe ohun tí à ń tijú rẹ̀. Àwọn tí ń lépa ìmọ̀ àti àwọn tí ń pera wọn ní onígbàgbọ́ ló gbọ́dọ̀ mọ ǹkan tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí. Ó ṣe pàtàkì fún ìgbàgbọ́ àti ìgbàlà!
Ìrònúpìwàdà túmọ̀ sí ìyípadà ọkàn tó jinlẹ̀ débi wípé ìṣẹ̀dá wa yóò ní àtúntò. Nígbà tí a bá kọjú sí Jésù, Yóò mú wa di ẹ̀dá titun, pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ láti máa ṣe bíi Rẹ̀.
Ìrònúpìwàdà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ lèyí—ó jẹ́ ìlànà ìsọni di ẹ̀dá titun nínú Kristi, tó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún ìrísí ìṣẹ̀dá bíi ti Ọlọ́run àti ìwà rere Rẹ̀ sí ayé wa. Ǹjẹ́ ànfàní kan wá jù èyí lọ bí?
Nípa Ìpèsè yìí
Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n.
More