Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ

Killing Kryptonite With John Bevere

Ọjọ́ 6 nínú 7

Orísirísi ìṣẹ̀lẹ̀ ma ń wà tí ó bá di ọ̀rọ̀ onígbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀.

Àkọ́kọ́, àwọn onígbàgbọ́ míràn wà tí ń f'ojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá nítorí ọkàn líle. Èkejì ni àwọn tí ó gba irọ́ náà gbọ́, wípé ẹlẹ́sẹ̀ ni gbogbo wa, wípé ẹ̀jẹ̀ Jésù gbà wá l'ọ́wọ́ èrè ẹ̀ṣẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n kò l'ágbára lóríi gbígbà wá kúrò nínú agbára rẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yìí ni, nítorí pé wọ́n fi ara wọn fún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n jẹ́ kríptónáìtì nínú ara Krístì, nítorí pé wọn ń mú ìrẹra bá gbogbo ara. 

Ẹgbẹ́ míràn sì wà - ẹgbẹ́ awọn onígbàgbọ́ tí ń lépa láti bọ́ l'ọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ẹgbẹ́ yìí ni mo fẹ́ s'ọ̀rọ̀ lé lórí lónìí. 

Ohun àkọ́kọ́ tí mo fẹ́ sọ ni pé, Jésù ò ní kùnà láti máa d'áríjì yín. Ó ń rí gbogbo ìyà tí ẹ̀ṣẹ̀ yín fi ń jẹ yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá kùnà. Ó mọ̀ wípé ẹ fẹ́ bọ́ lóòtó. Nípa ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ t'òní lè ràn yín l'ọ́wọ́. 

Èmi fún ra mi jẹ́ ọkàn l'ára awọn ẹgbẹ́ kẹta yí fún ọdún púpọ̀ nítorí ìfẹ́ mi láti máa wo àwòràn ìṣekúṣe, kó tó di pé mo wá s'ọ̀dọ Krístì. Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́hìn tí mo ṣe ìgbéyàwó mi tí mo sì bẹ̀rẹ̀ síi ṣiṣẹ́ nínú àjàrà Olúwa, mi ò bọ́. Kódà, ọ̀kan nínú àwọn olùṣọ́-àgùtàn àgbààgbà ní ilé Améríkà d'áwọ́ lé mi, ó sì gb'àdúrà fún ìtúsílè mi ṣùgbọ́n pàbo ló já sí. 

Ìdáńdé mi ò dé títí mo fi yí èrò mi padà. L'àkọ́kọ́, mò ń fẹ́ kí Ọlọ́run dá mi n'ídè nítorí àníyàn wípé ẹ̀ṣẹ̀ mi máa dí iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi l'ọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn mi yí padà, mo bẹ̀rẹ̀ síí d'ójú lé bí àwọn ìpinnu mi ba ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Jésù mu. Mo bẹ̀rẹ̀ síí ro bí ẹ̀ṣẹ̀ mi ṣe rí l'ára Ọlọrun. 

Nínú ìwé 2 Kọrinti 7:10, Pọ́ọ́lù àpóstélì gbé àwọn ìbànújẹ méjì yẹ̀ wò - ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run tíí ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà, àti ìbànújẹ́ ti ayé a máa tíí ṣiṣẹ́ ikú. Ìtàn ayé mi ṣ'àfihàn àwọn ìbànújẹ méjèèjì wọ̀nyí. Ní àkọ́kọ́, ìbànújẹ mi jẹ́ ti ayé, nítorí mò ń ṣ'àníyàn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ìbànújẹ mi di ti ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ síí rò bí ẹ̀ṣẹ̀ mi se ń pa Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn l'ára. 

Ọ̀rẹ́ mi, agbára Ọlọ́run wà láàyè láti dá yín n'ídè l'ọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àti láti fún-un yín ní ayé alágbára. Ẹ lé ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, ẹ gba ìdaríjí Ọlọ́run, kí e sì bẹ̀rẹ̀ síí gbé ayé titun nínú Krístì.

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Killing Kryptonite With John Bevere

Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n. 

More

A fé dúpé lówó John àti Lisa Bevere (Messenger Int'l) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, ẹ lọ sí: http://killingkryptonite.com