Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ
Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, Justin dé ilé láti ibi isẹ́, ó bá ìyàwó rẹ̀ Angela níbí tí ó ti ń wọ aṣọ dídára kan, ní ìmúra láti jáde. Ó rò wípé òde àkànṣe wà fún àwọn méjèèjì, nítorí náà, òhun náà fẹ́ lọ máa múra.
Angela dáhùn wípé kó má ṣèyọnu, torí òhun àti Tony ni wọ́n jo ń jáde. Àwọn méjèèjì fẹ́ lọ jẹun papọ̀, wọ́n á lọ sinimá, lẹ́yìn náà ni wọ́n á jọ lọ sí ilé ìgbàlejò tí ń jẹ́ Fairmont Hotel. Nítorí náà, ó máa di ọjọ́ kejì kí òun tó dé.
“Tani Tony?!” Justin béèrè.
“Eni tí mò ń fẹ́ ní ilé-ìwé gírámà ni,” o dáhùn.
“Hábà! O kò lè tẹ̀le jáde kẹ̀!”
“Kí ló dé?”
“Torí àwa méjèèjì ti di ọkọ àti ìyàwó báyìí, a ti di ọ̀kan. A ò lè máa fẹ̀ àwọn ẹlòmíràn!” Justin dáhùn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó hàn kedere ni.
“Dúró ná!” Angela f'èsì. "Lóòótọ́ ni wípé ìwọ ni mo fẹ́ràn jùlọ, àmò o kò lè rò wípé n ò ní máa fẹ́ àwọn tó kù. Èmi àti àwọn ti jẹ́ ọ̀rẹ́ láti ọjọ pípẹ́, ó dẹ̀ wùn mí kí n ṣì máa bá wọn rìn. Kí ló burú nínú rẹ̀?”
Ìtàn yìí hàn gbangba gẹ́gẹ́bí àrọ̀sọ. Báwo ni ènìyàn ò ṣe ní mọ̀ wípé ìgbéyàwó jẹ́ ìbáṣepọ̀ ẹni méjì péré? Ó hàn dájú wípé kò sí èyíkéyìí nínú wa tí ó bá fẹ́ Angela tí á tún retí wípé yóò máa fẹ́ ẹlòmíràn.
Síbẹ̀, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa ṣe ń bá Jésù rìn l'eléyìí.
Nínu Bíbélì, Ọlọ́run fi ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀ wé ìbáṣepọ̀ ìgbéyàwó. Bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run fi ìbáṣepọ̀ Òun àti Ísráẹ́lì inú Májẹ̀mú Láíláí wé. Ní ọ̀nà tí ó ya ni l'ẹ́nu, gbogbo ìgbà tí Ọlọ́run bá Ísráẹ́lì s'ọ̀rọ̀ nípa àwọn wòlíì lóri bí wọ́n ṣe ń ṣe panṣágà sí Òun, ó máa ń ní ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìbọrìsà.
Àwà lè máa rò pé ìbọrìsà ni fífi orí balẹ̀ fún ère, ṣùgbọ́n oun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni ìsìn wa. Ọlọ́run fún ra Rẹ̀ ló kókó sọ bí ìsìn ṣe jẹ́, nínú ìtàn Abrahamu ati Ísákì. Níbí la ti ríi pé, ìsìn jẹ mọ́ ìgbọràn.
Ìsìn kìí ṣe orin dídùn tí a ń kọ ní ilé ìjósìn; ìgbọràn ni ìsìn jẹ́. Kò sí bí a baà lè ṣiṣẹ́ tó nínú ìjọ, tí a kò bá gbọ́ràn sí Ọlọ́run l'ẹ́nu nínú gbogbo ayé ojoojúmọ́ wa, a kò sìn-ín. Kódà, à ń gbé nínú panṣágà ni. Bíi Angela.
Báwo ni òye ìsìn t'óní ṣe yí èrò re padà nípa bí ìgbé ayẹ́ Krìstìẹ́nì ṣe jẹ́?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n.
More