Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ
Ǹjé ẹ rántí Áńgẹ́là nínú ìtàn wa l'ánàá? A kọ́ wípé panṣágà rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú bí Bíbélì ṣe ṣ'àfihàn ìbọ̀rìsà sí Òun. Àmọ́ ǹjé èyí jẹ́ ohun tó ní láárí nínú ìjọ lónìí? Ó ṣe ni láàánú wípé ó jé ohun tó ní láárí nítorí bí ó ṣe gba ilé kan.
Bí ẹ bá wo Áńgẹ́là, ẹ ó ríi pé gbòǹgbò panṣágà rẹ̀ ni ìfẹ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ míràn fún ìfẹ tún ni ojúkòkòrò.
Ojúkòkòrò kìí ṣe ohun tí a máà ń m'ẹ́nu bà l'óde òní. Nítorí náà, má á ṣe àlàyé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé onímọ̀ ṣe kọ ìtúmọ rẹ̀, ojúkòkòrò ni "ìfẹ líle fún ohun tí ó jọ mọ́ ǹkan dáadáa". Báyìí, mà á tún wò ó láti apá míràn nínú ìwé Kólósè 3:5, níbi tí Pọ́ọ̀lù àpóstélì ti ṣo pé, "Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà.”
Ǹjé ẹ ríi? Pọ́ọ̀lù sọ wípé ojúkòkòrò jẹ́ ìbọ̀rìṣà. A lè máa rò wípé ìbọ̀rìsà ni ère àti ohun tí ó je mọ́-ọn, àmọ́ gbòǹgbò rẹ̀ ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ifẹ aimọ.
Ọlọ́run ti fún wa ní kọ́kọ́rọ́ láti borí ojúkòkòrò, ìtẹ́lọ́rùn sì ni. Ìtẹ́lọ́rùn máa sún wa kúrò nínú ìbọ̀rìsà sínú ọkàn Ọlọ́run, bí ojúkòkòrò ṣe máa lé wa jìnà kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run s'órí pẹpẹ ìbọ̀rìsà.
Nítorí ìdí èyí ni òǹkòwé Hébérù ṣe kọ ọ wípé, "Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé, “Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹ̀rù kò ní bà mí. Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” (Heberu 13:5-6).
Ẹ ti ríi nínú ẹsẹ̀ Bíbélì yìí bí ojúkòkòrò àti panṣágà ṣe jẹ́ ìkanńà. Áńgẹ́là fẹ́ràn àwọn ọkùnrin míràn, kò sì gbà Justin láàyè láti bá àwọn àìní rẹ pàdé. Ẹsẹ̀ Bíbélì yìí ń gbà wá n'íyànjú láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú Ọlọ́run, nítorí a mọ̀ wípé Òun ló lè tán gbogbo àìní wa. Tí a bá wo ọ̀nà míràn àyàfi Òun, tí a sì tèlé ọ̀nà míràn yàtọ̀ sí ọ̀nà ti Rẹ̀, èyí jẹ́ ìbọ̀rìsà!
Ohun tí ó túnmọ̀ sí rèé: onígbàgbọ́ tí ó ti mọ ìfẹ Ọlọ́run, ṣùgbón tí ó mọ̀-ọ́n-mọ̀ yàn láti ṣe ìfẹ t'inú ara rẹ̀, onígbàgbọ́ yìí ti b'ọ̀rìṣà. Ó ti yan òrìṣà ìfẹ inú rẹ̀ dídò Ọlọ́run.
N'ígbà ti ẹ wo àwọn èròńgbà, ìwà àti ohun tí ó je yín l'ógún, èwo l'ẹ máa sọ wípé ó gb'ilé jù nínú ayé yín- ojúkòkòrò tàbí ìtẹ́lọ́rùn? Báwo ni ẹ ṣe lè lé ayé tí ó ní ìtẹ́lọ́rùn ní kíkún síi?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n.
More