Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ

Killing Kryptonite With John Bevere

Ọjọ́ 7 nínú 7

Ìkéde ìrònúpìwàdà tí a nílò nínú ìjọ òde-òní ní òtítọ́ jẹ́ ìpè fún ohun tí a nílò jùlọ: ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Àìní ìfẹ́ láàrin ìjọ tí fà àlàfo ńlá láàárín gbèdéke méjì nínú iṣẹ́ ìríjú, iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti ilé ẹni kàǹkàn èyí tí í ṣe —ìfaradà àti fífi ipá ṣe ẹ̀sìn.

Ẹ̀tànjẹ tó wà nínú ìfaradà ni wípé ó farajọ ìfẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. A máa ń tẹ̀lé alààyè Bíbélì tó sọ wípé ìfẹ́ ní sùúrù, ó láàánú, kìí gbéra ga, kìí fọwọ́ lalẹ̀ ní gbogbo ìgbà, pẹ̀lú àwọn àmúyẹ mìíràn tó wà ní Kọ́ríńtì Kínní 13. Síbẹ̀-síbẹ̀, ìfẹ́ inú ayé lè ní púpọ̀ nínú àwọn àmúyẹ tí a ti dárúkọ. 

Ǹkan tó ya ìfẹ́ Kristẹni àti ti ayé sọ́tọ̀ ni wípé ìfẹ́ Kristẹni á máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run. “Ọ̀nà tí aó fi mọ̀ nìyí,” bí àpọ́sítélì ìfẹ́ ti kọ, “wípé a fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run tí a sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́” (Jòhánù Kínní 5:2).

Ìtumọ̀ èyí ni, bí mo bá ní sùúrù, tí mi ò kìí ṣe alárìfíń, kìí jowú, tàbí kógarù, ṣùgbọ́n tí mò ń yan àlè tàbí ṣe panṣágà, n kò rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. 

Ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn máa ń ní àmì òtítọ́ àti ìfẹ́. Òtítọ́ láìsí ìfẹ́ máa ń sin ènìyàn lọ lẹ́bà ọ̀nà ìjọsìn ìfipáṣe, èyí tí máa ń ṣekú pani. Àti wípé, ó bani lọ́kàn jẹ́ bí àwọn ènìyàn tí máa ń gbìyànjú láti dẹ́kun ìjọsìn ìfipáṣe yìí, nípa sísá fún ìbáwí àti ìkìlọ̀ látinú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó ṣe pàtàkì fún ìmúdúró àti ìdàgbàsókè ìjọ. 

Tí aò bá ní f'ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ—a máa ń rí ìkéde ìrònúpìwàdà sí ọkùnrin àti obìnrin gẹ́gẹ́bí àìní àánú, ìfarabalẹ̀, àti ìfẹ́. Síbẹ̀ gbìyànjú láti gba èyí yẹ̀wò: bí mo bá rí afọ́jú kan tó ń rìn tààrà lọ síbi ọ̀fìn jíjìn tí mo sì mọ̀ wípé yóò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tó bá jìn síi, ìfẹ́ ma kàn-án nípá fúnmi láti pe àkíyèsí rẹ̀ sí ewu náà!

Ní àwùjọ wa, àti láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ìjọ, irú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn tí ń pe àwọn ènìyàn sí ìrònúpìwàdà yí ni a máa ń rí gẹ́gẹ́bí ìkórìíra tàbí àìní ìfaradà. Ìdíwọ́ ńlá yìí jẹ́yọ́ nítorí àfojúsùn ọ̀pọ̀ ènìyàn kò kọjá ayé yìí. 

Nígbà tí a bá rántí wípé bíi ìṣẹ́jú àáyá ni ayé yìí rí ní àfiwé pẹ̀lú ayérayé, ìgbésí ayé wa yóò yàtọ̀. A ní láti fi ìrísí ayérayé wo àkókò wa lórílẹ̀ ayé láti ní òye nípa ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. 

Irú ìfẹ́ tí ìjọ nílò ní àkókò yí nìyí—Ìfẹ́ ayérayé, ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn—ìfẹ́ tí yóò kojú ẹ̀ṣẹ̀ tí yóò sì kéde ìrònúpìwàdà, síbẹ̀ ó jẹ́ ìfẹ́ tó ní sùúrù, tó ń káàánú, tó sì ní ìwà-pẹ̀lẹ́.

Ṣé o jẹ̀gbádùn kíka ètò yí? Mo fẹ́ gbà ọ́ níyànjú láti gba ìwé mi yẹ̀ wòKilling Kryptonite.  

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Killing Kryptonite With John Bevere

Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n. 

More

A fé dúpé lówó John àti Lisa Bevere (Messenger Int'l) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, ẹ lọ sí: http://killingkryptonite.com