Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John BevereÀpẹrẹ
Lónìí ni mo máa fi ẹ̀tànjẹ tí ó burú jù hàn èyí tí ń mú àwọn Kristẹni lọ sínú ìbọ̀rìṣà—lóde òní.
Láti ṣe èyí, mo máa fẹ́ kí o ronú nípa ìtàn ẹ̀gbọ̀rọ̀ màálù tí a fi wúrà mọ lórí Òkè Sínáì. Tí o bá rántí, Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ Íjíbítì nípa iṣẹ́ ìyanu agbára tí ó sì mú wọn la aginjù kọjá títí dé Òkè Sínáì. Ó sọ àwọn òfin Rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n sá padà wọ́n sì ti Mósè síwájú láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lórí òkè náà.
Kí Mósè tó dé, sùúrù àwọn ènìyàn náà pin. Wọ́n tọ Áárónì arákùnrin Mósè lọ, wọ́n sì kàn-án nípá fun láti mọ ère tí yóò mú wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Tí a bá fara balẹ̀ wòó, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “ère” ni Elohim, èyí tí a lò nínú Májẹ̀mú Láíláí gẹ́gẹ́bí àdàpè àwọn òrìṣà àti Ọlọ́run alààyè, fún ìdí èyí kò rọrùn láti mọ ẹni tí wọ́n ńsọ ní pàtó.
Áárónì tẹ́ wọn lọ́rùn, ó mọ ère ọ̀gbọ̀rọ̀ màálù, wọ́n sì sọ wípé, “ọlọ́run rẹ nìyí, ìwọ Ísírẹ́lì, tó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ́ Íjíbítì” (Ẹ́kísódù 32:4). A kò tíì mọ Ọlọ́run tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n lọ́gán ni Áárónì tan ìmọ́lẹ̀ síi.
Ó wípé, “Ọ̀la yóò jẹ́ ọjọ́ àjọ sí Olúwa” (Exodus 32:5). Níhìn-ín yìí tí ó ti wípé, “Olúwa,” ohun tí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ ni orúkọ náà, “Yahweh,” èyí tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run. Ní báyìí a ti fìdí ẹni tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀.
Ǹkan tó ṣẹlẹ̀ gan nìyí: Wọ́n ń jẹ́wọ́ wípé, “Yahweh ni Ọlọ́run wa. Yahweh gbà wá lọ́wọ́ Íjíbítì. Yahweh ni Olúwa wa,” síbẹ̀ wọ́n ń bọ òrìṣà. A gbọ́dọ̀ ṣe àkíyèsí ìkìlọ̀ yí, nítorí pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo ìjẹ́wọ́ wọn tó jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀ wọ́n ń bọ̀rìṣà, irú ǹkan báyìí lè ṣẹ́wo mọ́ àwa náà lọ́wọ́.
Kódà, ọ̀gọ̀rọ̀ Kristẹni ló máa ńṣe irú ǹkan yìí ní ìgbà dé ìgbà. Wọ́n máa jẹ́wọ́ wípé, “Jésù l'Olúwa,” ṣùgbọ́n wọn kò tẹ̀lé Jésù. Gẹ́lẹ́ bí Ísírẹ́lì ti lérò wípé ọ̀nwọ́n ń sin Yahweh, ṣùgbọ́n wọ́n tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ tiwọn dípò àlàálẹ̀ Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló máa ń ṣa ẹsẹ̀ Bíbélì tí wọ́n yàn láti tẹ̀lé, wọ́n yóò sì kọ etí ikún sí èyí tí ó kì wọ́n nílọ̀!
Bí a tií ṣẹ̀dá ayédèrú Jésù nìyí—èyí tí í ṣe òrìṣà. Kìí ṣe ìjọsìn sí Jésù ní tòótọ́.
Ìbéèrè tí ó yẹ fúnwa láti bèrè ni, báwo ni a ti lè dá ìjọsìn òtítọ́ sí Jésù mọ̀, yàtọ̀ sí ìjọsìn ayédèrú?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n.
More