Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ

Dating In The Modern Age

Ọjọ́ 7 nínú 7

 

Ìlànà Ìbáraẹnijáde (Apá Kejì)

Nínú ètò kíkà ti àná, a dúró níbi tí a ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìlànà ìdáwà nínú ìbáraẹnijáde—nínú ìbáraẹnijáde pẹ̀lú ọmọlẹ́yìn Kristi bíi tìrẹ nìkan. Nígbà tí ẹ bá tẹ̀lé ìlànà yí, ẹ̀yin méjèèjì a máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ “ìtọ́ni” kan ṣoṣo nípa títẹ̀lé Ọlọ́run. Èyí mú wa lọ sí ìlànà tí ó tẹ̀lée: ìwà mímọ́ nípa ìbálòpọ̀.

Ìwà mímọ́ nípa ìbálòpọ̀ jẹ́ ìlànà tí ó ti di ohun ìgbàgbé lóde òní. Àmọ́ ó ṣe pàtàkì nítorí ìbálòpọ̀ nííṣe ju ìfarakọnra lásán lọ. Ìmọ̀lára tó rinlẹ̀, ju bí a ti lérò lọ máa ń wáyé nígbà tí akọ àti abo bá ní ìbálòpọ̀. Ọkọ tàbí ayaà rẹ ló yẹ kójẹ́ ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ọ jùlọ, àmọ́ nígbà tí ìbálòpọ̀ bá ti wọ̀ọ́, ó ma nira láti ṣe àyẹ̀wò bóyá ẹni yìí jẹ́ ọ̀rẹ́ dáradára tàbí ìdàkejì rẹ̀. Yóò mú ọ dúró fún ìgbà tó pẹ́ nínú ìbáṣepọ̀ tí kò yẹ, àti wípé yóò mú kí ọgbẹ́-ọkàn pọ̀ nígbà tí ẹ bá pàpà túká.

Èyí mú wa lọ sí ìlànà tí ó tẹ̀lée: jẹ́ kí ìhà tí o ma kọ sí ènìyàn náà jẹ́ irú èyí tí o ma kọsí ọmọ Ọlọ́run. Irú èèyàn tí o jẹ́ ni yóò tọ́ ipa irú ìgbésẹ̀ tí o máa gbé. Nítorí náà, nígbà tí o bá wà nínú ìbáraẹnijáde, o nílò láti rí ẹnìkejì rẹ—òhun náà sì nílò láti rí ìwọ pẹ̀lú—bíi ọmọ tí a gbọwọ́ Ọlọ́run tọ́. Ìhà wo ló yẹ kí a kọsí ọmọ Ọba Ọ̀run? Ọ̀wọ̀, ìrẹ̀lẹ̀, àti àánú. Ipa tí ó yẹ láti gbìyànjú láti fi sílẹ̀ nínú ayé gbogbo àwọn tí o bá ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ni èyí tí ó dára. Ó yẹ kí ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú ẹni tọ̀ún ruú sókè láti ní ìjẹ́rìí àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run síi.

Ìlépa rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ láti bùkún, kìí ṣe láti móríwú. Fún ìdí èyí ẹ ṣeré jáde, gbìyànjú láti mọ èèyàn yí si, ẹ ṣe àwọn ǹkan tí ẹ fẹ́ràn. Kìí ṣe wípé o fẹ́ kí èèyàn yí fẹ́ràn rẹ ní ọ̀ranyàn, bíkòṣe láti mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ yín wọ̀ ni. Tẹ́tí lélẹ̀ pẹ̀lú ìfarabalẹ̀, bèrè ìbéèrè, kí o sì sọ èrò ọkàn rẹ pẹ̀lú ìṣòótọ́. Gbóríyìn fún-un. Gbàá níyànjú. Kí o sì sọ èrò ọkàn rẹ pẹ̀lú ìṣòótọ́ àti ìkáàńú. Máṣe la araà rẹ ní òógùn nípa ìgbìyànjú láti wú ẹnìkejì lórí. Ìbáraẹnijáde wà fún àgbéyẹ̀wò àti ìbùkún.

A ti bọ́ sí ìlànà tó kàn: gba àwọn ènìyàn tí o jẹ́rìí láàyè láti dá sí Ìbáraẹnijáde yín. Ìmọ̀ lára ìfẹ́ a máa pani bí ọtí a sì ma mú ni wò bàìbàì, fún ìdí èyí gbígba àwọn ohùn tótọ́ láàyè nínú Ìbáraẹnijáde yín ma ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan ẹni tí ó yẹ. Yan àwọn ọ̀rẹ́ tó fẹ́ràn Ọlọ́run, tó fẹ́ràn rẹ pẹ̀lú, tí wọn kò sì bẹ̀rù láti sọ èrò wọn fún ẹ. Rọ̀ wọ́n láti dá sí ìgbésẹ̀ Ìbáraẹnijáde rẹ ní kánkán àti léraléra. Yí ara rẹ po pẹ̀lú ìmọ̀ràn bíi t'Ọlọ́run.

Ìlànà Ìbáraẹnijáde tó kẹ́yìn ni láti ní sùúrù. Gba ìbáṣepọ̀ ọ̀hún láàyè láti dàgbà bó ti yẹ. Máṣe kánjú láti ki òrùka bọwọ́, àmọ́ dúró láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìhùwàsí ẹnìkejì rẹ. Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ lo máa ti mọ̀ wípé àwọn kan kò yẹ lẹ́ni tí à ń ní Ìbáraẹnijáde pẹ̀lú. Àwọn mìíràn ma dà bíi wípé wọ́n sàn ní ìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn-òrẹyìn o máa bẹ̀rẹ̀ sí ní rí kùdìẹ̀-kudiẹ nínú ìwà wọn. Ṣe ìṣọ́nà láti mọ bí wọn ó ti hùwà nígbà tí ǹkan kò bá lọ bí wọ́n ti fẹ́. Ṣe sùúrù láti rí wọn ní onírúurú ipò.

Ǹjẹ́ o ma rí ẹni tí ó yẹ ní gbogbo ọ̀nà? Ń kò lè sọ. Àmọ́ mo mọ̀ wípé Ọlọ́run ti kún ọ pẹ̀lú ọgbọ́n àti ara Rẹ̀ láti fẹ̀yìntì nínú ìrìn-àjò ayé. Ádùrá mi ni wípé ìrètí rẹ ní àkókò yí yóò dá lórí Ọba àwọn ọba, dípò ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin kan. Ádùrá mi ni wípé ìwọ yóò bá Ọlọ́run rìn, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wípé yóò pèsè gbogbo ohun tí o nílò àti wípé, tó bá jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, yóò darí rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tó yẹ lákòókò tótọ́.

Fèsì

Kí ló fà á tí ìwà mímọ́ nípa ìbálòpọ̀ fi ṣe pàtàkì nínú ìgbésẹ̀ Ìbáraẹnijáde? Báwo ni ìkóra-ẹni-ní-ìjánú kí ẹ tó gbéyàwó yóò ti ran ìdúróṣinṣin ìbáṣepọ̀ lọ́wọ́?

Kíni ìwà rẹ sí ẹnìkejì rẹ sọ nípa rẹ? Kílódé tí ó fi ṣe pàtàkì láti hùwà sí ẹnìkejì rẹ gẹ́gẹ́bí ọmọ Ọlọ́run?

Tani ẹni tó lè sọ òtítọ́ sínú ayéè rẹ bí o ti ń ṣe Ìbáraẹnijáde? Báwo lo ti ń gbọ́ràn sí ẹni tọ̀ún lẹ́nu sí?

Ìgbà wo ló ti nira fún ọ láti ní sùúrù nínú ìbáṣepọ̀? Kíni ǹkankan tó jẹ́ wípé ó gbogbo fàyè àkókò púpọ̀ sílẹ̀ láti mọ̀ nípa ènìyàn?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Dating In The Modern Age

Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ Ben Stuart fun ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ẹ lọ si: https://thatrelationshipbook.com