Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ
Bí a tií ṣe Ìbáraẹnijáde
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo ní ìrìn-àjò-afẹ́ lọ sí ibi tí à ń pè ní Grand Canyon, pẹ̀lú ìpinnu láti dé ibi odò kan tó ń dà látòkè ní agbègbè náà. Bí mo tií rìn ní ẹ̀báa odò Colorado, mo pàdé tọkọtaya kan tó ń lọ sí ibẹ̀ pẹ̀lú. Wọ́n filọ̀mí láti darapọ̀ mọ́ àwọn, àmọ́ mo wòye wípé ìrìn wọn yóò fà mí sẹ́yìn. Bí mo ti ń lọ níwájú, iyèméjì bóyá mo ti ṣìnà bẹ̀rẹ̀ sí í mú mi. Pẹ̀lú ìfòyà mo sáré gùn òkè kan lọ níbi tí mo ti gbé rí àgbọ̀nrín kan, lọ́gán ni mo kọsẹ̀ tí mo sì yí bírí padà sí ìsàlẹ̀ kòtò náà. Bí mo ti dùbúlẹ̀ síbi tí mo ṣubú sí, ni mo gbọ́ tí omi ń dà ní ìtòsí. Nígbà tí mo tẹ̀lé ìró omi náà, mo bá àwọn tọkọtaya tí mo fi sẹ́yìn lọ́nà, ní ibi tí wọ́n ti ń jẹ̀gbádùn oúnjẹ lẹ́bàá odò yí.
Mo sọ ìtàn yí láti ṣe àfihàn òtítọ́ kan: èmi àti àwọn tọkọtaya yìí pàpà dé ibi tí a pinu láti lọ, àmọ́ ọ̀nà tí kò rọrùn tí kò sì mú ìwúrí wá ni èmi gbà débẹ̀. Èyí ni àpèjúwe tó ṣe àfihàn ìbáṣepọ̀ lóde òní. Àwọn ènìyàn ń ní ìbápàdé ìfẹ́ lójojúmọ́. Síbẹ̀ ìrìn-àjò náà ń pẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀—ọ̀pọ̀ ní kò ní gbéyàwó títí wọn yóò kọjá ọmọ-ọgbọ́n-ọdún. Láàárín àwọn ìran tí ó kọjá ipa ọ̀nà mọ́lẹ̀ ju báyìí lọ, ṣùgbọ́n ní àkókò yí ṣeni à ń kán lùgbẹ́ láìní ìhámọ́ra, láìní atọ́nà, àti pẹ̀lú oúnjẹ kéréje. À ń rí ǹkan gbé ṣe, àmọ́ ojúu wa ń rí mẹ́wàá nínú ìlépa wa.
Àwọn òfin ìbáraẹnijáde ti rújú kò sì yéni mọ́. Nínú ìbáṣepọ̀, ó yẹ kí a ma sọ̀rọ̀ nípa àwọn ǹkan bíi ìgbádùn, ìdárayá, àti ìwúrí. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọ̀rọ̀ tí mo máa ń gbọ́ tí àwọn èèyàn ń mẹ́nubà pẹ̀lú ìbáraẹnijáde ni ìbànújẹ́, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti wàhálà. Gẹ́gẹ́bí ẹnìkan tó fẹ́ràn àwọn ọ̀rẹ́ mi tó jẹ́ ọ̀dọ́, tí wọn kò sì tíì gbéyàwó, mo fẹ́ ìrìn àjò tó dára fún wọn. Ìrìn-àjò dídára yí sì ṣeé ṣe! Ipa sí ìfẹ́ lè mú ìrora dání, ṣùgbọ́n ọ̀nà kan wà tí o fi lè rìn-ín láìní ìfarapa.
Púpọ̀ nínú làálàá àwọn olólùfẹ́ lónìí níi máa ń wáyé nípasẹ̀ àìní ìpinnu ìṣísẹ̀ ìbáraẹnijáde. Ṣe àkíyèsí ìṣísẹ̀ tí mo sọ—ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ìgbésẹ̀. Ìbáraẹnijáde ní láti jẹ́ àwọn ìgbésẹ̀ ọlọ́woọ̀wọ́ lọ sí ìparí tí a tí mọ̀ tẹ́lẹ̀. Kìíṣe ipele tí èèyàn ń dé láì gbé ìgbésẹ̀ kankan. Ó yẹ kí ó jẹ́ ìṣísẹ̀ àgbéyèwò tó ní ìparí—ibùdó tí à ń pè ní ìgbéyàwó.
Ìṣísẹ̀ yí ni ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìlànà ìhùwàsí àti ìfẹ́ Ọlọ́run. Wàá ríi wípé mo pè wọ́n ní ìlànà, láìṣe ìgbésẹ̀. Ìgbésẹ̀ ìbá rọrùn—ṣáà tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni, ìgbéyàwó aládìdúǹ yó sì jẹ́ tìrẹ! Àmọ́ ìbáraẹnijáde kò rí báyìí, nítorí ìbáṣepọ̀ máa ń rújú gidi. Ìbáraẹnijáde bá àpèjúwe títukọ̀ lójú agbami lọ ju títo ọjà jọ. Títẹ̀lé ìgbésẹ̀ nínú ọkọ̀-ojú-omi kò lè ṣe ìrànlọ́wọ́ lọ títí lójú agbami. Omi òkun ń yí lóòrè kóòrè, nítorí èyí ó kò lè tẹ̀lé ìgbésẹ̀ lọ-s'ọ̀tún-lọ-s'ósì. Ta ló mọ irú ìjì tí o ma bá pàdé lọ́nà?
Ìlànà, ní ipa kejì, lè pa ẹ̀míì rẹ mọ́ lójú agbami. Ìmọ̀ nípa bí a tíì wá ipa ọ̀nà lórí òkun pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìràwọ̀, tàbí bí a tií lo atọ́ka-ọ̀nà, tàbí máàpù lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gúnlẹ̀ ayọ̀. Bákan náà, ní àwọn ìlànà tí o bá tẹ̀lé nínú ìbáṣepọ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ìpèníjà tó bá dìde. Àlàyé yìí ni yóò gbé ọ láti èbúté àìlọ́kọ tàbí àìláya dé èbúté ìgbéyàwó.
Láti tẹ̀lé àwọn ìlànà tí a ó ṣíde ní àwọn ọjọ́ méjì tó wà níwájú, o máa nílò láti pa ọkàn pọ̀ láti bá wa lọ. Wàá nílò láti ṣiṣẹ́. Àmọ́ iṣẹ́ yìí yóò padà di ìrìn-àjò-afẹ́ (tó m'éwu dání) tí yóò wá mú èrèe rẹ̀ dùn lẹ́nu. Àwọn ìlànà atọ́nà wọ̀nyí—nígbà tí o bá lò wọ́n fún ìbáṣepọ̀ rẹ tó ń yí bírí—yóò mú ọ la ìrú-omi ìbáraẹnijáde já.
Fèsì
Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni ìwọ fi ń ṣe àpèjúwe ìbáraẹnijáde? Kíni ò ń retí níbi ìbáraẹnijáde? Kíni èróńgbà rẹ?
Kíni ó túmọ̀ sí tí a bá sọ wípé ìbáraẹnijáde nííṣe pẹ̀lú ìṣísẹ̀? Kíni àwọn ìgbésẹ̀ tí a ní láti gbé nínú ìbáraẹnijáde? Kíni òpin ìrìn-àjò tí o gbẹ́nulé yí? Tí o kò bá tíì ṣe tán láti gbéyàwó, kíni àwọn ọ̀nà míràn tí o fi lè ní ìbárẹ́ tó ní ìtumọ̀?
Kíni àwọn àmúyẹ ìbánidọ́rẹ̀ tí o nílò láti ṣiṣẹ́ lórí láti ní ìbáṣepọ̀ tó ní àṣeyọrí? Orí òṣùwọ̀n wo lo bọ́sí nípa ìtẹ́tí lélẹ̀, àkíyèsí, àti àgbéyèwò àwọn tí ò ń bá pàdé? Báwo ni ìṣísẹ̀ yí ti lè jẹ́ ìrìn-àjò-afẹ́?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.
More