Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ
Ẹni tí a má ní Ìbáraẹnijáde Pẹ̀lú
Ọ̀kan lára àwọn ewu ìbáraẹnijáde tó burú jù ni ìkúndùn láti kọ ìhà mú wá ju ìhà kíni molè fi fúnni. Nígbà tí o bá bèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn irú ẹni tí wọ́n fẹ́ ní ìbáraẹnijáde pẹ̀lú, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ka onírúurú àmúyẹ. “Gíga, àmọ́ tí kò ga jù. Tí kò láápọn, àmọ́ tó lágbára. Tó ní ìgboyà, àmọ́ tó tún ńṣe ìtọ́jú. Tó dùn ún wò, àmọ́ tó lè pani lérìń. Àti èyí tó ní iṣẹ́ tó dára pẹ̀lú owó oṣù tó jọjú.”
Ìṣòro ṣíṣe atọ́kà onírúurú àmúyẹ tí a fẹ́ ni wípé yóò fa gbèdéke tí ẹnikẹ́ni kò lè pójú òṣùwọ̀n fún. Ò ń gbìyànjú láti mú ohun tí ó dára jù lórí àtẹ. Nínú ìbáraẹnijáde, ò ń wá ènìyàn kan láti fẹ́ràn, kìí ṣe ǹkan ṣá tí o lè lò. Fún ìdí èyí àṣàyàn rẹ ko gbọdọ̀ dá lórí àwọn àmúyẹ bíi ẹwà, ọrọ̀, nítorí àwọn àmúyẹ yìí ma padà rẹ̀ dànù (wo Òwe 31:30). Tí ìgbéyàwó rẹ bá dá lóríi àmúyẹ tí a lè fojú rí, kò sí ìrètí wípé ìbáṣepọ̀ yín ma l'álòpẹ́.
Nínú ìbáraẹnijáde, kìí ṣepé o fẹ́ ṣe àgbélẹ̀rọ àwọn ẹ̀yà ara tí ó wù ọ́. Dípò èyí, o fẹ́ gbìyànjú láti ṣe àtúntò ayée tìrẹ láti lè mú ìdàgbàsókè bá ẹni kejì nínú ògo Ọlọ́run. Fún ìdí èyí ẹni tí o yàn ní láti ní ìdákọ̀ró ti ìfẹ́ àti ìwà-tótọ̀ ìyẹn lẹ́yìn gbogbo ǹkan tí o bá yànda fún ìgbéyàwó rẹ láti lè dúró digbí nígbà tí ìwọ bá rẹ̀wẹ̀sì. O kò fẹ́ ẹni tí yóò yí ohùn padà nígbà tí ǹkan kò bá rọgbọ.
Ní báyìí, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti mọ gbogbo ǹkan nípa ènìyàn nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ọjọ́ kan? Kò ṣeé ṣe! Ẹnikẹ́ni lè díbọ́n níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wákàtí kan. Àmọ́ ǹkan tí o ní láti máa wá ni láti pàdé ẹnìkan tó ń tiraka láti ṣe àwọn ǹkan ìwúrí fún àwọn ìdí tó móríyá. O nílò ènìyàn tó ń lépa Olúwa pẹ̀lú ipele ìtara kan náà pẹ̀lú tìrẹ. Láti lè jọ dúró níwájú pẹpẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú ìlérí àti jẹ olóòótọ́ sí ẹnìkejì láì ní ìbẹ̀rù wípé ẹnìkan ń parọ́.
Kìí ṣe ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run nìkan ni ìwọ ńwá bí kò ṣe ẹni tí ọ̀rọ̀ yín jọ wọ̀ pẹ̀lú. Ìgbàgbọ́ àti ìpinnu rẹ gẹ́gẹ́bí Kristẹni ṣe kókó nínú ìbáṣepọ̀ rẹ. Ó ní àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tí ẹ kò gbọ́dọ̀ yí padà: ìwàláàyè Ọlọ́run mẹ́ta-lọ̀kan, ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀, ikú Kristi fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àti ìgbàlà pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí ó ṣeé ṣe kí àwọn ǹkan míràn wà tí ẹ kò ní fẹnu kò lé lórí tí ẹ ó sì ṣiṣẹ́ lé lórí bí ẹ ti ń tẹ̀síwájú. Síbẹ̀ mo ní láti pe àkíyèsí rẹ wípé ẹ lè má lè ní ìpohùnpọ̀ nípa gbogbo ǹkan, àmọ́ ẹ nílò ìpohùnpọ̀ nípa àwọn ǹkan tí ó jẹ ẹ̀yin méjèèjì lógún.
Ẹ ní láti fẹnu kò nípa ìbárẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn míràn. Kìí ṣe gbogbo àkókò ìgbéyàwó yín ló máa wà fún níní ìbálòpọ̀ bíkòṣe níní ìjáde papọ̀. Ó yẹ kí o ní ìwúrí nínú ẹnìkejì rẹ. Ó yẹ kí àwọn ìlépa yín nípa ìgbésí-ayé àti iṣẹ́ wà ní ipa kan náà. Àti tẹ̀ fún ẹnìkejì lẹ́ẹ̀kàn-kan ṣe pàtàkì. Àmọ́ àpọ̀jù rẹ̀ ńkọ́, ó lè mú kí àìlè-lépa àwọn ǹkan tó jẹ ẹnìkan lógún láti fa ìrẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbéyàwó.
Bíbélì mọ rírì ẹwà (ìwọ ṣá ti ka Orin Sólómọ́nì). Ó ṣe kókó fún ìdàgbàsókè ìbáṣepọ̀—ṣùgbọ́n kìí ṣe gbèdéke láti fi mọ ẹni tí o lè ní ìbájáde pẹ̀lú. Kedere ló hàn, wípé èyí ríbẹ̀ nítorí ẹwà àti ìléra máa ń ṣá. Nítorí náà la ojúù rẹ sílẹ̀! Ó rọrùn láti gba àwọn ǹkan wọ̀nyí yẹ̀wò kí a tó tẹsẹ̀ bọ ìgbéyàwó. Àgbéyẹ̀wò àwọn ǹkan wọ̀nyí ma múu rọrùn láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run lọ́wọ́ sí ìbáṣepọ̀ náà.
Fèsì
Nígbà tí o bá ńṣe àgbéyẹ̀wò irú ẹni tí o fẹ́ ní ìbáraẹnijáde pẹ̀lú, kíni àwọn àmúyẹ to máa fojú sọ́nà fún?
Kíni àwọn ǹkan tí o kò lè gbà nínú ìbáraẹnijáde? Nípa àwọn ǹkan wo lo ti ṣe tán láti tẹ̀ tàbí ṣe ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìbáṣepọ̀?
Báwo lo ṣe fẹ́ mọ̀ tí ẹni tí o fẹ́ ní ìbáraẹnijáde pẹ̀lú bá ní ìlépa kan náà pẹ̀lú tìrẹ? Kíni kùdìẹ̀-kudiẹ tó lè ti ẹ̀yìn àìka ǹkan yí sí jáde?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.
More