Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ

Dating In The Modern Age

Ọjọ́ 3 nínú 7

 

Kini Eredi Ìbáraẹnijáde?

Ìbáraẹnijáde le nitoripe o lewu. Ìgbà míràn a máa dabi ṣíṣe ère 'suwe' ni pápá tí ó kún fun ẹtu ìbẹ́jàdì. O lè mú ọ máa ro èrò pé kí ni dídá ara ẹni láàmú láti tẹrí sì ewu ti ko ṣeé yẹra fún. Ìdáhùn rẹ̀ ni wípé nínú odò inú wa ni òùngbẹ àti ni ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn wà. A ń fẹ́ láti ni ìfẹ́ kí a sì pada ni ìrírí ìfẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé fe ṣé ìgbéyàwó. Nítorí náà a máa ń ṣe tán láti tẹrí sí èwù ìbáraẹnijáde fún ère ọlọ́jọ́ pípé, ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́.

Nínú ẹ̀kọ́ kíkà yí nko ni sọ̀rọ̀ nípa bí óò ṣe rí ẹni bá jáde, nítorípé òtítọ́ ibẹ̀ ẹnikẹ́ni lè rí ẹni ba jáde. Bí ó bá rẹ ọ̀págun rẹ sílè dáadáa, kódà ó lè ṣe ìgbéyàwó lálẹ́ òní. Rírí ẹni ba jáde rọrùn. Sugbon wíwà ẹni tí o tọ́ rí ní ọ̀nà tí ó tọ́ Kọ́ rí bẹ. Nítorí náà ìbéèrè a jẹ́ kini a ṣe lè ṣe àṣeyọrí nínú eyi. Kí ni o ṣé lè ní ìbájáde ní ọ̀nà tí ó má mú abala ti o dara nínú pípàdé ènìyàn pọ sì ti ìrora inú rẹ̀ a sì máa kéré sí? Lati dáhùn ìbéèrè yí, ó ní láti tẹ̀ sẹhin láti beere ìbéèrè tí ó tún ṣe koko ju eléyìí: Kini èrèdíi ibajade?

Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa ìbájáde, sugbon o ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti sọ nípa gbígbé àwọn ènìyàn lè ìwọ̀n. Mo máa fà kalẹ̀ pé ìbáraẹnijáde je ètò ìgbéléwọ̀n ayé òde òní. Ìbáraẹnijáde jẹ ṣíṣe àkíyèsí bóyá ó fẹ́ lo ọjọ́ ayé rẹ pẹ̀lú enikan ni pàtó. Ìbéèrè àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì tí ìgbéléwọ̀n yíì a yọrí sí ní àmì ìdáyàtọ̀ tí ó ní láti ṣàwárí rẹ nínú ènìyàn miran.

Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ti ṣe ìgbéyàwó, ó ní láti má gbà agbára sì ọ̀nà Ọlọ́run. Ní iyasọ́tọ̀ síi. Lílo ẹ̀bùn rẹ, agbára, àkókò àti ipá rẹ láti jẹ ìbùkún fún gbogbo ènìyàn tí a dá ní àwòrán Rẹ̀. Bi o ti ń lépa Rẹ̀, onírúurú ènìyàn na ni yóò má sáré bákan náà, ṣùgbọ́n sì onírúurúu ọ́nà. Nígbòóṣe, óò gbójú sókè óò sì rí àwọn ènìyàn tí ó ń lépa Rẹ pẹ̀lú rẹ. Bí ó ti ń sáré, óò bẹ̀rẹ̀ si ni bá díè nínú wọn sọ̀rọ̀. Óò yẹ wọ́n wo.

Ohun tí ó ń wá niìwà ati ẹ̀là. Ó fẹ́ ẹni tí ó ní ìwà tí ó sì nfi tọkàntọkàn lépa Ọlọ́run àti ohun tí ó jé tí Ọlọ́run. Bákannáà ó fẹ́ wá ènìyàn tí ó ní ẹ̀là pẹ̀lú rẹ. O fẹ́ ẹni tí ó gbádùn àti máa wà pẹ̀lú rẹ, láti máa bá sọ̀rọ̀, tí ẹ báramu. Ó fẹ́ ìwà bí Ọlọ́run ti o múlẹ̀ ṣinṣin àti àti ẹ́là tí ó rọrùn tí ó si fún ni ní igbadun.

Ìbáraẹnijáde kìí ṣe nípa lìlépa ẹlòmíì kí ó lè wá ìtumò àti ìmúṣẹ ayé rẹ nínú rẹ̀. Èyí pọ̀jù ni ẹrù láti gbé kárí ẹ̀dá alààyè kankan. Kìí sì ṣe bí a rí dá ọ nìyí. Óò sì kì í ṣe aàbọ̀ ènìyàn tí ó ń dúró de ààbọ̀ ènìyàn mìíràn tí yóò mú ọ "dodindi". Ó jẹ́ pípe, Ọlọ́run si feran rẹ bí ó ṣe wà lai tí ṣe ìgbéyàwó - kì í ṣe àìpé.

Nítorí náà, eredí ìbáraẹnijáde kìí ṣe wíwà pípé gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan sugbon láti wá ènìyàn tí ó ní ìwà tí ó dára tí ẹ sì jọ ní ẹ̀là tí ó dára kí ẹyin méjèèjì lè jọ sáré sínú ọjọ́ iwájú ti Ọlọ́run ni fún yín. Bí ó bá bá ẹlòmíràn jáde, òpin ìbájáde náà ni wípé kí ẹyin méjèèjì jọ dàgbà papọ̀ kí ẹ lè jọ ṣí àrà yín lórí, pé ara yín níjà, kí ẹ sì tún lè jọ ṣe ará yín ní mímú. Nípasẹ̀ èyí, ó má ni lati yí padà, wa ni ìbá dọ́gba, àti ipò ìyọ̀dá. Ko ni rọrùn ni gbogbo ìgbà, kò sì ní dabi àpèjúwe ijarọ̀ tí a ń rí lórí ère orí ìtàgé Hollywood. But you can be assured the journey will be well worth it. Ṣùgbọ́n, ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé ìrìn àjò na a ní iyì tí kò ṣe díyelé.

Èyí ni ẹ̀rẹ̀dí ìbáraẹnijáde. Èyí ni ìran tí ó ń lépa nínú ìgbéyàwó. Ó sì jẹ irin ajo ti o yani lẹ́nu tí ó sì rẹwà!.

Respond

Ǹjẹ́ o ha tí ni ìpalára nínú ìbánijáde rẹ? Kí ni o ti kọ́ nínú ìrírí rẹ?

Kí ni èròngbà rẹ láti wọnú ìbánijáde? Ǹjẹ́ èròngbà rẹ mọ bí? Kì ni ìdí rẹ?

Ki lọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ènìyàn yẹ̀ wò bí ẹni tí ó lè jẹ́ sọ yigi pelu rẹ? What hopes do you have for the future as you consider dating someone? Kì nì ìrètí tí ó ní fún ọjọ́ iwájú bí ó ti ń gbèrò ìbánijáde?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Dating In The Modern Age

Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ Ben Stuart fun ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ẹ lọ si: https://thatrelationshipbook.com