Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ

Dating

Ọjọ́ 1 nínú 7

 

Ká Fi Ohun Àkọ́kọ́ ṣe Àkọ́kọ́

Ǹjẹ ó fẹ́ jẹ́ irúfẹ́ ẹni tí ó ń ṣe oore tí ó sì ń hùwà ìfẹ́ sì àwọn ènìyàn? Ǹjẹ ó fẹ́ jẹ́ ẹni tí ó ń fi irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí ọ hàn sí ẹlòmíràn? Ǹjẹ́ o fẹ́ jẹ́ orísun ìyè fún ẹbí, ọ̀rẹ́, ẹni tí ò ń bá jáde - àti ẹni tí ó máà padà ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú rẹ̀? Bí ó bá jẹ́ bẹ̀, o máa nílò orísun ìyè kan. Bí ó ṣe yẹ kí ó ti rí nígbà gbogbo nìyí. Ìfẹ́ tí a kó mọ́ra ni ó máa ń di ìfẹ́ tí ó gbòòrò tí ó sì ń tẹ̀síwájú sọ́dọ̀ ẹlòmíì. Ó jẹ́ ìfihàn nípa bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ fẹ́ wá (wo Jòhánù Kini orí kẹ́rin ese kọkàndínlógún). Nigbati o bá ni  orísun ìyè kan, ó lè jẹ́ orísun iye bákan náà.

Nínú ìwé Jòhánù orí kẹ́rin, Jésù ṣàlàyé bi ẹnìkọ̀ọkan wá ṣe ní òùngbẹ tí ó jinlẹ̀ nínú ọkàn wa pé kí ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ wá. Jésù n bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ níbi kànga omi, nígbòóṣe Ó sọ fún ú, “O ti ní ọkọ márùn-ún rí, ẹni tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nísinsìnyí kì í sì í ṣe ọkọ rẹ” ( ẹsẹ kejìdínlógún Niv). Ó tún so wípé, “ Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.(ẹsẹ̀ kẹwàá Niv). Òun ti Jésù nsọ ni wípé, “Ó ti ń wá ìtẹ́lọ́rùn fún ìpòǹgbẹ ọkàn rẹ ni ọwọ́ ènìyàn - o kò lè ri níbẹ̀. Ó ti ṣe àyẹ̀wò òun ti o nílò láti ṣe”. Ohun tí Jésù nsọ ni wípé ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú ìtẹ́lọ́rùn wá fún òùngbẹ ọkàn rẹ̀ wà nínú Ọlọ́run, orísun ìyè, kò sì sí nínú àjọṣepọ̀ ènìyàn kankan.

Bí ó bá fí irú àjọṣepọ̀ ìbáraẹnijáde yí ṣe ìjẹrí sì ìdúró rẹ, àbájáde rẹ máa ń jẹ bí fífà ẹ̀mí jáde kúrò lára ẹnìkejì rẹ.  Bí a ṣe ń dá àjọṣepọ ìbáraẹnijáde tí ó dàbí májèlé sílẹ̀ ni yi. Ìdí ni yi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi má ń ṣìnà. Bí o bá gbé àìní tí ó tóbi bí Ọlọ́run ká iwájú ènìyàn, kò sì ọ̀nà tí wọn fi lè bá àìní náà pàdé. Bákan náà o kò lè nawọ́ ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn ní ọjọ́ tí wọ́n bá ní ìdojúkọ, nítorí wípé àwọn ni ó ń dúró bí  orísun rẹ . Ṣùgbọ́n, tí Ọlọ́run bá jẹ́ orísun rẹ, yóò jẹ́ oun tí ó rọrùn fún ni jùlọ láti jẹ ki ìfẹ́ Rẹ̀ ṣàn jáde láti inú rẹ sì ẹni tí ó ń bá jáde. Nígbà tí ó bá mọ wípé áyànfẹ́ ni ọ ní tòótọ́, yóò rọrùn fún ọ láti fẹ́ràn ẹlòmíì. Nígbà tí o bá ní orísun ìfẹ́ tí kò lè gbẹ, nígbà náà ni ó lè jẹ́ orísun ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn.

Bí o bá wà nínú Krístì, o mọ̀ wípé Ẹ̀dá tí ó lẹ́wà jùlo tí ó sì lágbára jù lọ lórí ilẹ̀ ayé ló ń ṣìkẹ́ẹ̀ rẹ. Ó mọ orúkọ rẹ. Ó ń rí ọ. Ó fi ohun gbogbo sílẹ̀ kí ó lè jẹ́ tirẹ̀. Ko ni sọ ìrètí nù lórí rẹ lailai. Nítorí náà, kí ó tó wọnú ìbáraẹnijáde - àti wípé kí ó tó yàn láti fẹ́ ẹni tí ó fẹ́ bá so yìgì— ó ní láti máa bá Ẹlẹ́dàá rẹ pàdé láti ni ìbáṣepọ̀ pelu Rẹ. Nínu ìfẹsẹ̀múlẹ̀ bíbá Kristi rìn ní óò ti ní ohun tí ó nílò láti bùkún ẹni tí ò ń bá jáde

Fèsì

Kíni ìdíi rẹ̀ tí ó fi ṣe kókó láti niy Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí orísun ìyè kí ìwọ náà lè jẹ́ orísun ìyè fún ẹlòmíràn? Kíni ó máa ń ṣẹlẹ̀ bí ènìyàn kùnà ètò yí?

Báwo ni ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe ní ipa lóríi ẹni tí ò ń bá jáde? Kíni ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe ní ipa lóríi bí ó ti rí araà rẹ?

Kí lo ní láti ṣe lónìí láti dàgbà síi nínú ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run?  Kíni àwọn ìgbésẹ̀ tí ó wúlò ti ó máa là kalẹ̀ láti rí wípé eléyìí ṣẹlẹ̀?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Dating

Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ Ben Stuart fun ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ẹ lọ si: https://thatrelationshipbook.com