Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ

Dating In The Modern Age

Ọjọ́ 2 nínú 7

 

Atukọ̀ fún ìrìn-àjò

Bí mo bá wo rere ayé àti ìfẹ́ nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lónìí, Mo ríẹ̀rù. Ẹ̀rù ṣíṣe àṣìṣe. Ẹrú ká yọ ní sílẹ̀. Ẹ̀rù pípàdánù àǹfààní. Nínu ẹlòmíràn mo má ń gbóhùnìgbéraga—títẹramọ́ ìgbé ayé ní ìlànà tí wọ́n là kalẹ̀ fún ara wọn kì ẹnikẹ́ni má bàa dẹ́rùba òmìnira tí wọn ní láti ṣe tàbí sọ̀rọ̀ bí ó ti wù wọ́n. Nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀, mo tún má a nriìfẹ́kúfẹ̀. Kí ni ìdí ṣíṣe àdéhùn fi féràn ẹni tọkàntọkàn bí ènìyàn bá kan lè lo wón nípa ti ara? Ẹ̀rù, ìgbéraga, àti ìfẹ́kúfẹ ni gbongbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro tí ó má lọri jáde nínú ìbáṣepọ̀.

Kọ́ sì ọkàn nínú gbogbo àwọn nkan wonyi tí lájorí rẹ jẹ́ ìfẹ́. Ẹ̀rù a máa fa sísé ati ìfàsẹ́hin, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a má a lawọ́ a sì máa fún ní l'ọ́fẹ̀ẹ́. Ìgbéraga kò níí farada aàfo tí ó lè jẹ ki ènìyàn fi ara rẹ̀ hàn fún ẹlòmíì, sùgbọ́n ìfẹ́ ń fara dà eewu ìpalára fún ànfàní ẹnìkejì. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ a máa sọ fún ẹnì kejì wí pé ó kàn fẹ́ àwọn ẹ̀yà ara ti o le lo, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ń gbani mọ́ra lódindi -  ni ọjọ́ ti o dara tàbí tí ó burú julọ.

Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀rù, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìgbéraga bá jẹ atukọ̀ ìbáṣepọ̀ rẹ, o óò má sáré tete jìnà kúrò nínu ìfẹ́ tí ó ní ìlera. Àwọn nkan wọ̀nyí a máa fi ọ́ sínú ìyaraẹnisọ́tọ̀ tàbí kí ó ṣẹ̀dá àwọn ìbátan aìjinlẹ̀ tí kò bù ọlá fún Ọlọ́run. Èyí ni ipo ti mo má ń rí nínu àṣà wá lónìí. Mo rí ìran tí ó ti sọnù s'ókun láì mo ọ̀nà tí wọn ò tọ̀ nínu òkun ìjì líle tí ìfẹ́ láti lè yọ ara wọn kúrò nínu ọ̀fìn ẹ̀rù, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìgbéraga. Won wá ní fínfín tí afẹ́fẹ́ ati ìgbì n'lu wọ́n.

Ní ìgbà àtijó, bí ọkọ̀ ojú omi bá wọ inú ìgbì tó lewu, atukọ̀ máa ń níláti jẹ́wọ́ pé òun kò ní ìmọ̀ tí ó tó láti darí ọkọ̀ rẹ̀ sì èbúté. Nígbà tí òye yí bá sọ, (kí ó tó di aiye òde ìṣòrọ̀-gbẹ̀sì lórí ẹ̀rọ alátagbà), ó má gbé àsíá kan soke tí ó ń ṣe ìfihàn tí ó nsọ wípé ''Mo nílò iranlọwọ atukọ̀''.p Nígbàkúùgbà tí atukọ̀ ti o ni ìmọ́ omi náà bá rí àsíá tí a gbé sókè lórí òpó yìí, yóò jáde tọ ọkọ̀ ojú omi náà lọ, yíò sì wọ inú ọkọ̀ náà.

Atukọ̀ náà a gbà ìṣàkóso ọkọ̀ náà  a sì tọ ni ailewu la ipa tí ó ní àpáta àti omi-oníyẹ̀pẹ̀ kọjá sí ebute. Láti lè jẹ ki àwọn Atukọ̀ yókù ti wọn lé ní èrò láti gba ìṣàkóso ọkọ̀ náà pé wọn kò nílò ìrànwọ́ mọ́, ọkọ̀ náà a tà ásíá míràn - èyí tí ilaji rẹ̀ jẹ́ pupa tí ilaji sì funfun. Ásíá yìí a máa sọ fún gbogbo ojú tí ó bá ríi pé '' Mo ní Atukọ̀ '' Wọn kò nílò Atukọ̀ mìíràn mọ́, àwọn ará agbègbè náà á sì ni ìfọ̀kànbalẹ̀ pé  ọkọ̀ ojú omi náà wá ní ọwọ́ tí ó lè tọ ni àiléwu.

Nínú òkun aidánilójú ìbáṣepọ̀ ìbá jáde, ìwọ náà ni ọ̀nà láti tọ ipa ọ̀nà tí ó tẹsíwájú. Ó lè na àsíá jíjọ̀wọ́ sókè kí ó sì jẹ́wọ́ pé '' Mo nílò Atukọ̀'' tí ó má tọ́ ó jáde kúrò nínu ewu ti o wa lábẹ́ ojú omi. Ó sì lè gbé àsíá ìfọkànsìn sókè sí ayé pe "Mo ní Atukọ̀" kí ó sì yan láti tẹ́lẹ̀ òun nìkan.

Ọlọ́run ní o dá ọ, òun nìkan ló sì lè tọ ọ̀ délé ni àiléwu. Bíbélì sọ fún wa wípé Òun ni Ìfẹ́ (wo ìwé 1 Jòhánù 4:8). Nítorí náà, nínú ìbáṣepọ̀ ìbájáde rẹ lónìí, gba wípé ó nílò ìtọ́nà láàrin omi ìfẹ́ aìmọ̀. Jẹ́wọ́ fun Ọlọ́run pé ó nílò rẹ láti gba ìtukọ̀ kí ó sì tọ́ ọ. Bi o bá ṣe tí ìbá jáde, ibi yìí ni ìrì aájò rẹ gbọ́dọ̀ tí bẹ̀rẹ̀.

Fèsì

Ipa wo ni ẹ̀rù, ìgbéraga àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí kò nínú ìlépa rẹ fún ìfẹ́. Kìni ìrírí rẹ pẹlu ìfẹ́ aláìlera.

Kìni àwọn "omi ilewu" tí ó ti ní ìrírí rẹ̀ ni ti ìbájáde?

Kini o túnmọ̀ sì nínú ìbájáde rẹ láti gbé àsíá jíjọ̀wọ́ sókè kí ó sì jẹ́wọ́ wípé ó nílò ìtọ́nà?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Dating In The Modern Age

Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ Ben Stuart fun ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ẹ lọ si: https://thatrelationshipbook.com