Ìbáraẹnijáde ní Ayé Òde ÒníÀpẹrẹ

Dating In The Modern Age

Ọjọ́ 6 nínú 7

 

Ìlànà Ìbáraẹnijáde (Apá Kínní)

Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ ìlànà Ìbáraẹnijáde, ṣáájú ohun gbogbo o nílò láti pe Ọlọ́run gbogbo àgbáyé wá sínú ìgbésẹ̀ rẹ. Gba òtítọ́ nípa ẹni tí Ó jẹ́ láàyè láti darí èrò àti ìṣe rẹ. Ádùrá ma tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìfòyà dídá wà—yóò sì pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ewu gbígba ọ̀jẹ̀gẹ́. O lè sinmi pẹ̀lú ìmọ̀ àti ìdánilójú wípé Ọlọ́run ń darí rẹ ní ọ̀nà tí ó dára. Nígbà tí o bá ní ìdàpọ̀ tó dán mọ́nrán pẹ̀lú Ọlọ́run, o máa rí àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí ohun ìní Rẹ̀ tó ṣe iyebíye—tí kìí ṣe ohun àmúlò lásán, ṣùgbọ́n tí a bọ̀wọ̀ fún.

Nínú Ìbáraẹnijáde, ọ̀wọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú títẹ̀lé ìlànà Ìbáraẹnijáde kejì: máṣe fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún ẹnìkejì rẹ. Nínú Éfésù 4:15, Pọ́ọ̀lù sọ wípé ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ènìyàn Kristi ni wípé wọ́n ma ń “[sọ] òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́.” Òwe 24:26 sọ wípé ìdáhùn tó ní òtítọ́ nínú dàbí fífi ẹnu koni lẹ́nu. Àmì ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ ló jẹ́ nígbà tí a bá sọ òtítọ́ fún ènìyàn. Nítorí náà dìde pẹ̀lú ìgboyà láti sọ èrò rẹ fún ẹnìkejì rẹ, ìmọ̀lára rẹ, àti ǹkan tí o ma fẹ́ ṣe.

Ri dájú wípé o kò f'ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tí o bá wà nínú ìbáraẹnijáde. Jẹ́kí ẹnìkejì mọ èrò rẹ nípa ìrírí ìbáṣepọ̀ yín—má fi ẹnìkejì rẹ sínú òkùnkùn nípa ohun tí ó ń bọ̀ níwájú. Àìlè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yéni máa ń dá wàhálà sílẹ̀. Ní àfikún, tan ìmọ́lẹ̀ sí bí ó ti ṣeé ṣe fún ìbáraẹnijáde yín láti wá s'ópin. Sọ bí ara ti tù ọ́ sí nígbà kugbà, kí o sì ṣe tán láti fòpin síi nígbà tí ǹkan kò bá rọgbọ mọ́. Ilẹ̀kùn àbájáde tí kò ní ìdíwọ́ gbọ́dọ̀ wà. Nígbà tí o bá tan ìmọ́lẹ̀ sí gbogbo ìṣeè rẹ, o máa fún àwọn tó yí ẹ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti wípé wọn kòní nílò láti díbọ́.

Àwọn onígbàgbọ́ nínú Jésù ò nílò láti ṣe àmúlù-málà. Ìgbà kéréje laó lò láyé. Kò sí àyè láti máa gbé àwọn ènìyàn sórí àga tí kò lẹ́sẹ̀. Bó bá ti rí ni kí o sọ. Dúró lórí ǹkan tí o bá sọ. Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn sí gbogbo ìgbésẹ̀ rẹ.

Ìlànà kẹta nípa ìbáraẹnijáde ni wípé ó ní láti wáyé láàárín àwọn onígbàgbọ́ nínú Kristi. Bíbélì fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn tó jẹ́rìí Kristi ní láti ní ìbáraẹnijáde (àti ìgbéyàwó) pẹ̀lú onígbàgbọ́ bíi tiwọn. O ní láti fẹ́ràn àwọn àláìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n kìí ṣe bíi kí o máa ní ìbáraẹnijáde pẹ̀lú wọn. Gẹ́gẹ́bí onígbàgbọ́ nínú Kristi, ìbáraẹnijáde wà lára àwọn ọ̀nà tí a fi ń wà ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ mìíràn—ìyẹn ìbáṣepọ̀ tó ní èdìdí. Ọlọ́run ò rí ìbáraẹnijáde gẹ́gẹ́bí “ipò.” Arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi, tàbí ọkọ àti aya ni àyè gbà yín láti jẹ́. Kò sí àlàfo fún ìbáṣepọ̀ míràn yàtọ̀ sí wọ̀nyí. Fún ìdí èyí máṣe s'oríi ọ̀rọ̀ yí kodò.

Bá kan náà, ni Bíbélì ti pa àlà sí àwọn ǹkan tí Ọlọ́run gbà láyè nípa ìbálòpọ̀. Nínú ìgbéyàwó, àyè gba lọ́kọ-láya. Kí a tó gbéyàwó, kò sí ǹkankan nípa ìbálòpọ̀ tí Bíbélì fàyè gbà. Nínú ìbáraẹnijáde pẹ̀lú, á kò fàyè gba ǹkankan. Ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn kò ní gbìyànjú láti tú ọ láṣọ wò pẹ̀lú ìgbìyànjú láti yẹrí fún ojúṣe láti tọ́jú rẹ nípa ti ara àti ti ẹ̀mí. Fún ìdí èyí, níwọ̀n ìgbà tí a kò tíì so yín pọ̀ níwájú Ọlọ́run, ẹ̀yà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹ jẹ́.

Ìwọ fúnra rẹ lo máa jíhìn fún Ọlọ́run bí o ti lo ayéè rẹ. Nítorí náà lo àkókò ìbáraẹnijáde gẹ́gẹ́bí ipele àgbéyèwò tí yóò dárí rẹ láti mọ ìpinnu tí o ma ṣe nípa ẹnìkejì rẹ. Lo àkókò ìbáraẹnijáde láti mọ̀ bóyá inú ìbáṣepọ̀ tótọ́ ni o wà.

Fèsì

Ọ̀nà wo lo ti gbà pe Ọlọ́run wá sínú ètò ìbáraẹnijáde rẹ? Èíṣe tó fi ṣe pàtàkì láti kọ́kọ́ pe Ọlọ́run wá sínú àwọn ìgbésẹ̀ rẹ kí o tó pinu ẹni tí o ma yàn láti bá ní ìbáraẹnijáde?

Àwọn ọ̀nà tótọ́ wo lo mọ̀ tí o fi lè sọ fún èèyàn wípé o fẹ́ báwọn ní ìbáraẹnijáde? Ọ̀nà wo ni o lè gbà fi ọ̀wọ̀ fún ẹni tí o fẹ́ bá ní ìbáraẹnijáde nípasẹ̀ ìhà tí o kọ sí wọn?

Kíni àwọn àlà tí Ọlọ́run ti pa nínú ìbáṣepọ̀? Tí o bá ti fo ọ̀kan nínú àwọn àlà yí ní àtẹ̀yìnwá, báwo lo ti lè padà sí ipa ọ̀nà?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Dating In The Modern Age

Ìbáraẹnijáde... Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yi há kò ìpayà tàbí ìrètí bá ọkàn rẹ? Ó dàbí ẹni wípé anfaani tí ó bá ẹ̀rọ ayélujára wá túbọ̀ jẹ́ kí ìbáraẹnijáde túbọ̀ dojuru, tí a sì máa sú ni. Nínú ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì tí a là kalẹ lórí Àpọ́n. Ìbáraẹnijáde. Àdéhùn ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó. Ọ̀gbẹ́ni Ben Stuart a rán ọ lọ́wọ́ láti rí wípé Ọlọ́run ni eto fún àsìkò yí nínú ayé rẹ, o si fi ètò ìtọ́ni tí ó múlè lélẹ̀ tí yóò rán ọ lọ́wọ́ láti mọ irúfé ènìyàn tàbí àkókò ìbájáde. Ogbeni Ben ni Olùṣọ́ àgùntàn ìjo Passion City, ní ìlú Washington ó sì jẹ adari ìṣe ìránṣẹ́ Breakaway, ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọṣẹ̀ṣẹ̀ tí ẹgbẹgberun ogunlọgọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga tí ọgbà ilé ìwé Texas A&M máa ńlọ.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ Ben Stuart fun ètò ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ẹ lọ si: https://thatrelationshipbook.com