Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwáÀpẹrẹ

Ìgbẹkẹ̀lé
Ìlú Oklahoma ni mò ń gbé níbi tí ojú ọjọ́ ti lè yí padà lójijì. Ní ọdún náà lọ́ọ̀hún nínú oṣù kẹta, a ní ojú ọjọ́ tó rẹwà tó mú oru òrùn lọ́wọ́. Ní ọjọ́ tó tẹ̀lé oru yìí yìnyín tó pọ̀ jọjọ jábọ́. Bí èyí ti yani lẹ́nu tó, kò burú tó ìgbà ẹ̀fúùfù ńlá. Ìjì ẹ̀fúùfù yí a si máa dìde láìrò tẹ́lẹ̀.
Bí wọ́n ti ńṣe nínú ayé wa.
Mo bá obìnrin kan, tí àìsàn ń bá fíra, sọ̀rọ̀ níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó wáyé ní ilé ìwé ọmọkùnrin mi. Ó ṣàlàyé bí òhun ti súnmọ́ Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún àti bí o tí ń ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run nínú ìjọ. Àmọ́ nígbà tí àwọn ìpèníjà tó nípọn bẹ̀rẹ̀ sí ní yọjú, ó ja Ọlọ́run níyàn nípa ìdí tó fi gba irú ǹkan wọ̀nyí láàyè. Bó ti ń sọ wípé “Báwo ni mo ṣe fẹ́ sin Ọlọ́run tí n kò lè gbẹ́kẹ̀lé?” ni ó ń gbìyànjú láti má sunkún.
Njẹ́ a lè jẹ́rìí wípé Ọlọ́run dára bí ayé wa kò tilẹ̀ dára lọ títí?
Ìbéèrè obìnrin yìí sọ ojú abẹ ní'kòó nípa ọ̀kan nínú àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì jùlọ láyé. Ǹjẹ́ a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé wípé Ọlọ́run dára nígbàtí ìgbésí ayé wa kò bá rọgbọ? Ìhà tí a bá kọ sí ìrora àti ìpèníjà ma nííṣe pẹ̀lú bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe ma rí.
Nípa bí ìṣẹ̀dá rẹ̀ ti rí, ìgbàgbọ́ a máa nílò ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ohun kàn—tàbí ẹnìkan—tí a kò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ní òye nípa rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ènìyàn. Tí a bá máa jẹ́ olóòótọ́, gbogbo wa ló fẹ́ ní àrídájú nípa ìwàláàyè Ọlọ́run nínú ayé wa.
Èyí kìíṣe ǹkan titun. Ṣé ẹ rántí Tọ́másì oníyèméjì? Lẹ́yìn ikú Jésù lórí igi àgbélébùú àti àjíǹde rẹ̀ kúrò ní ipò òkú, Tọ́másì sọ wípé òhun kò ní gbàgbọ́ àyàfi tí àrídájú bá wà. Kàkà kí ó gba ìbínú láàyè tàbí gbáa sẹ́gbẹ̀ẹ́ fún àìnígbàgbọ́, Jésù fi ọwọ́ rẹ tí a fì'ṣó dálu han Tọ́másì.
Ẹ má gbàgbé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lákòókò ìjì orí omi. Ẹ̀fúùfù tó lágbára dìde, omi òkun sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́ sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó kù díẹ̀ kí ọkọ̀ náà rì. Máàkù 4:37 NIV. Nínú ìjì yí, àwọn ọmọlẹ́yìn kò dá wà. Ní ẹsẹ̀ Bíbélì tó tẹ̀lé èyí, Máàkù rán wa létí wípé Jésù wà níbi kọ́lọ́fín ọkọ̀ náà níbi tó ti ń sùn.
Pẹ̀lú Jésù nínú ọkọ̀ rẹ, àwọn ìjì lè dà ọ́ kiri, àmọ́ o kò ní rì.
Àwọn ènìyàn bí ìwọ àti èmi, obìnrin tí mo pàdé níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀, Tọ́másì, àti àwọn ọmọlẹ́yìn a máa lérò wípé ìjì kankan kò lè dé bá wa níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú Jésù nínú ọkọ̀, ìjì ṣì lè rọ́lù ẹ́, àmọ́ o kò ní rì. Ó wà pẹ̀lú rẹ, bóyá nígbà t'ójò ń fún tàbí tí ẹ̀fúùfù líle ń fẹ́.
Kò kàn wà pẹ̀lú rẹ lásán, Ó jẹ́ tìrẹ. Bí ó bá sì jẹ́ tìrẹ, tani ó lè dojú ìjà kọ ẹ́? Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run pẹ̀lú ohunkóhun tí o bá ti ń fi pamọ́ látẹ̀yìnwá. Gbẹ́kẹ̀lé E nípa ọkọ tàbí aya tí o ma fẹ́. Gbẹ́kẹ̀lé E nípa àwọn ọmọ rẹ. Gbẹ́kẹ̀lé E nípa iṣẹ́ rẹ. Gbẹ́kẹ̀lé E nípa ìléra rẹ. Gbẹ́kẹ̀lé E nípa ìṣúná rẹ.
Gbẹ́kẹ̀lé Ẹ nípa ohun gbogbo.
Lóbátán.
Àdúrà: Baba mi tí ḿbẹ Lọ́run, mo gbẹ́kẹ̀lé Ẹ pẹ̀lú ǹkan tí mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àti èyí tí mofẹ́ fòpin sí. Mo gbẹ́kẹ̀lé Ẹ nípa ibi tí ma dúró sí àti ibi tí máà ti t'ẹsẹ̀ mọ́'rìn. Mo gbẹ́kẹ̀lé Ẹ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè jọ̀wọ́ ayé mi láti sìn Ọ́ àti láti fa àwọn ènìyàn míràn wá sọ́dọ̀ rẹ. Mo sì jẹ́rìí wípé O ní èrèdí fún gbogbo ìjì ayé mi. O ṣeun tí o wà pẹ̀lú mi, to sì ń tọ́ ipa àti ìṣísẹ̀ mi, Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí

Lójojúmọ́, a ma ńṣe àwọn àṣàyàn tó ń tọ́ ipa nínú ìtàn ìgbésí ayé wa. Báwo ni ìtàn ìgbésí ayé rẹ yóò ti rí tí o bá ṣe àwọn àṣàyàn tó dára? Nínú Ètò Bíbélì Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá, gbajú-gbajà ònkọ̀wé New York Times àti Olùṣọ́àgùntàn àgbà ní ìjọ Life.Church, Craig Groeschel, máa gbà ọ́ níyànjú pẹ̀lú àwọn ìlànà méje tí a fà jáde látinú ìwé Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá fún ìrànlọ́wọ́ láti ṣe àwárí ọgbọ́n Ọlọ́run fún àwọn ìpinnu tí à ńṣe lójojúmọ́. Ṣe àwárí àwọn ìtọ́ni ti ẹ̀mí tí o nílò láti gbé ìgbésí ayé tó bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.
More
Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ

Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ - Ọgbọ́n

Gbígbé Nípa Ti Ẹ̀mí Mímọ́: Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì Pẹ̀lú John Piper

Ètò Olúwa Fún Ayéè

Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwu

Ẹnití a Yàn: Rán Ara Rẹ Létí Ìhìnrere Lójoojúmọ́

Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Wiwá Àlàáfíà

Ohun Méje Ti Bíbélì So Nípa Àníyàn
