Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ
MÁ TIJÚ LÁTI TẸRÍBA LÁTI DÚPẸ́
Nígbà kékeré mi, a kọ́ mi láti fara balẹ̀, kí n tẹ orí mi ba, kí n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oúnjẹ mi.Títí di òní tí í ṣe ọdún kẹtàdínlọ́gọ́rin lẹ́hìn ìgbà yẹn, kódà ní ilé tí a ti ń ra oúnjẹ jẹ, mo ṣì máa ń tẹrí mi ba láti dúpẹ́.
Bóyá kìí sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó dàbí pé a kìí ṣe èyí mọ́ lónìí. Kìí ṣe pé mò ń dájọ́, mo kàn ń gbìyànjú láti sọ nnkan tí mo ti ń ṣàkíyèsí ni. Ọkàn mi a máa yọ̀ nígbà tí mo bá ríi tí àwọn mìíràn náà bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run láì tijú fún ìbùkún t'ó fún wa. Ọ̀kan lára ìdí tí a kò fi gbé ìwà yìí lárugẹ mọ́ bí ti àtijọ́ ni pé iṣẹ́ ti kún àwọn ènìyàn lọ́wọ́ dé'bi pé ṣàṣà ni ìgbà tí ìdílé ń jókòó pọ̀ jẹun mọ́.
Tìmótì kìlọ̀ fún wa nípa àwọn olùkọ́ tí yó máa tàrí ẹ̀kọ́ àti òfin tiwọn sí àwọn ènìyàn. Ẹsẹ t'ó ṣaájú sọ pé àwọn kan á máa kọ́ pé kí á yààgò fún àwọn oúnjẹ kan àti ìgbéyàwó.."Nítorí ohun gbogbo tí Ọlọrun dá ni ó dára. Kò sí ohun tí a gbọdọ̀ kọ̀ bí a bá gbà á pẹlu ọpẹ́, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati adura ti sọ ọ́ di mímọ́." Timoti Kinni 4:4-5
Nígbà tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, nnkan àkọ́kọ́ t'ó ṣe ni pé, Ó gbé búrẹ́dì márùnún àti ẹja méjì s'ókè sí ọ̀run Ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run kí ó tóó bù ú. Ó tún ṣe bákan náà nígbà tí ó bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú búrẹ́dì méje àti ẹja.
Fífi àsìkò sílẹ̀ àti lílo gbogbo ànfàní láti fi ọpẹ́ wa hàn fún Ọlọ́run ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹ̀mí ọpẹ́ láti dàgbà nínú wa.
Kìí ṣe pé mò ń rétí pé kí àwọn ènìyàn dúpẹ́ nígbà tí mo bá ṣe nnkan t'ó dára fún wọn, ṣùgbọ́n tí wọn kò bá lè fí ìmoore hàn, kò yé mi bóyá wọ́n mọ rírì ìbùkún náà. Bákan náà ló ṣe rí pẹ̀lú Ọlọ́run. Kò yẹ kí Ó ṣe iyèméjì lórí ìdúpẹ́ wa.
Nígbà tí mo bá kọ nípa pé kí á gbàdúrà s'órí oúnjẹ wá nígbà tí a bá wà lójú gbaara, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí á mọ̀ pé kìí ṣe pé kí á ṣe é bí iṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kí á rí àwọn ènìyàn t'ó tẹríba kí wọ́n tóó jẹun lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn t'ó bá rí wọn, kìí ṣe pé kí á gbàdúrà pẹ̀lú ariwo sórí oúnjẹ wa kí áwọn ènìyàn leè rí wa ni mò ń sọ.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn t'ó ń wò wá rò pé à ń sínwín, ó sì tún lè ta wọ́n jí nínú ẹ̀mí. Ó pa ni lẹ́rìn bí a ṣe lè lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, kọ́lẹ̀ẹ̀jì tàbi kí á lọ wo eré bọ́ọ̀lù kí á sì fi gbogbo agbára pariwo, ṣùgbọ́n kí á máa tijú lérò pé a máa tàbùkù ara wa nígbà tí a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Àgbáyé fún ìbúkún Rẹ̀.
IṢẸ́ ÀKÀNṢE T'ÒNÍ:
• T'ó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ tóo ti gbàdúrà kí o tó jẹun, bẹ̀rẹ̀ lónìí. Kínni ìdí? Nítórí pé kìí ṣe pé yó ru ọkàn Ọlọ́run sókè nìkan, ṣùgbọ́n yó tún mú kí o dàgbà nínú dídúpẹ́!
• Bẹ̀rẹ̀ láti ilé. Dá bẹ̀rẹ̀ kí o sì tẹ̀síwájú nípa gbígbàdúrà pẹ̀lú ìdílé rẹ.
• Láìpẹ́, yó wù ọ́ láti tẹríba nílé oúnjẹ!
• Bí o bá lè ṣe bí asínwín níbi eré bọ́ọ̀lù, o lè ṣe bí asínwín díẹ̀ fún Ọlọ́run!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!
More