Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ
GBÒǸGBÒ LÀTI BẸ̀RẸ̀ ÌKÓRÈ!
Ní ọdún 2020, ọmọ mi obìrin àti ọkọ rẹ̀ ṣe àbẹ̀wò sí Grumeti, ní orílẹ́-èdè Tanzania ní Áfíríkà, níbití wọ́n ti ní àǹfààní láti rí ẹbí kan ní abúlé kan. Ẹbí yìí fi amọ̀ àti ẹ̀ka igi kọ́ ahéré kan. Ìyá inú ẹbí yìí fi igi ṣe ohun ìṣiré àgbéniyípo fún àwọn ọmọ rẹ̀. Orí eékún rẹ̀ nínú ilẹ̀ eléruku ni ìyá yìí ti ǹ d'ána. Yíó sì tún pe àwọn ọmọ rẹ̀ jọ, wọ́n á s'owọ́ pọ̀ k'ọrin pẹ̀lú àwọn àlejò tí wọn kò bá pàdé rí bíi ẹni. pé ẹbí kannáà ni wọ́n. Gbogbo ẹbí yìí pátá ni wọ́n fi ayọ̀ àti ọkàn ìmoore hàn bí ẹni pé àwọn ni wọ́n ní gbogbo ilé-ayé!
Mo sọ ìtàn yìí fún ọ nítorípé ó jẹ́ ọ̀nà tó dára láti bẹ̀rẹ̀ síí ní òye pé ìdúpẹ́ áti ayọ̀ kò dá lórí ipòkípò sùgbọ́n lórí ohun tí ń bẹ nínú ọkan wa àti bí a ṣe ń wo sàkun ńńkan. Irú ìgbé-ayé yìí nìkan ni àwọn ẹbí yìí mọ̀, ó tẹ́wọn l'ọ́rùn, inú wọn sì dùn sí ohun tí wọn ní.
Ọpọ̀lọpọ̀ nínú wa l'ágbàyé ni ó ń jẹ ìgbádùn àwọn ohun amáyédẹrùn ìgbàlódé àti àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ òde-òní. À ń jẹun ẹ̀ẹ̀mẹta lóòjọ́ pẹ̀lú àwọn ìpanu ní àalàfibọ̀, síbẹ̀ ìba díẹ̀ ló kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn.
Láti inú ààrin gbùngbùn ọkàn wa, yálà kí a jẹ́ oníkùn-sínú àti àláròyé, ẹni tí ń ké kòtó, kòtó tàbí kí á dàbíi ẹbí yìí ní Áfíríkà tí wọ́n fi ọkàn ìmoore rí ohun gbogbo tí wọ́n ní!
"Nítorínáà bí ẹ̀yin ti gba Krístì Jésù Olúwa, bẹ́ẹ̀ni kí ẹ máa rìn nínú rẹ̀, kí ẹ fi gbòngbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín, kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú idupẹ." Kólósè 2:6-7
Nígbàtí a bá f'ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Jésù tí a sì ṣe àmúlò ìgbàgbọ́ tì ń wá látàrí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ yìí, ìwé-mímọ́ fi yé wa pé à ń pọ̀ síi nínú ìdúpẹ́. Láti pọ̀ síi túmọ̀ sí pé kí a ṣe é rékọjá, ní ọ̀pọ̀ yanturu.
IṢẸ́ ÀKÀNṢE T'ÒNÍ:
· Bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé ìgbà wo lo ti f'ọkàn ọpẹ́ hàn gbéyìn.
· Bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé ìgbà mélòó ni ò ń fi ọkàn ayọ̀ àti ìdúpẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn.
· Bẹ̀rẹ̀ síí dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo ọ̀pọ̀ ìbùkún tí ò ń gbádùn!
· Kí a máa pọ̀ síi nínú ìdúpẹ́!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!
More