Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ
GBÉ ỌLỌ́RUN GA PẸ̀LÚ ỌPẸ́!
Báwo ni a ṣe le gbé Ọlọ́run ga pẹ̀lú ọpẹ́ wa? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló wà l'áti fi ọpẹ́ wa hàn sí Ọlọ́run fun ohun gbogbo tí Ó jẹ́ àti tí Ó ṣe.
• Ìgbọràn: A rán mi l'étí nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pé 'ìgbọràn' sàn ju ẹbọ lọ. I Sámúẹ́lì 15:22 Tí a bá gbọ́ràn tí a sì ń gbé ní ìlànà ọ̀rọ̀ Rẹ̀, à ún dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ìgbésí ayé wa!
• Ìyìn pẹ̀lú ẹnu wa: "Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga; èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga." Orin Dáfídì 69:30
• Ìkáàánú:"Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín." Éfésù 4:32
• Àdúrà:"Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́." 1 Tẹsalóníkà 5:16-18
• Ìsoore:"Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ!" 2 Kọ́ríntì 9:7
Jọ̀wọ́ ronú sí àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì yìí láti rú ọpẹ́ àti ayọ̀ l'áti gbùngbùn ọkàn sókè!
Mo fẹ́ràn láti máa ronú àti sin Ọlọ́run tinútinú pẹ̀lú àpẹẹrẹ ṣiṣẹ́ àkàrà èèbó aládìídùn tí wọ́n fi kòkó ṣe. Tí ojú bá ń kán mi, mo lè gb'ìyànjú kí ń parí ìgbésẹ̀ náà kíákíá; mo tún lè yí ìdáná sókè lalala ju ohun tí ìwé àkọsílẹ̀ àsè wí lo. Mọ lè má fi iyè sí ohun tí mò ń ṣe mọ́ n'ítorí mo gba ìpè lórí ẹ̀ro ìbánisọ̀rọ̀ kí n sì gbàgbé l'áti fi awon èròjà kéékèèké tó nílò l'áti fi po ìyẹ̀fun náà síi. Tàbí kí n ṣe àṣìṣe l'áti lo àwọn èròjà kòkó tó ti pé n'ílé.
Mi o rò pé ìmọ̀ore àti ìfẹ́ mi yóò n'ítumọ̀ sí ẹnikẹ́ni nípa fífi àkàrà òyìnbó tí a ṣe ní irú ọ̀nà yìí t'ọọre. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú Olúwa. Bíi ṣíṣe ètò àkàrà òyìnbó, a ó fi àkókò s'ílẹ̀, a ó dá ohun gbogbo míràn dúró, a ó sì lo àwọn èròjà tí ó dára tí ó sì jọ̀lọ̀ jùlọ tí a lè rí. Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ní ìmọ̀lára pé a pọ́n wọn lé àti pé a n'ífẹ wọn n'ígbà tí wọ́n gbọ́ òórùn àkàrà yí, pàápàá jùlọ, n'ígbà tí a bá fi sí abọ́ fún wọn jẹ.
Ọlọ́run ń dúró dè wá kí á wá Òun lójoojúmọ́, l'áti fi ìfẹ́ wa hàn n'ípa ìmoore!
IṢẸ́ ÀKÀNṢE T'ÒNÍ:
• Lo àkọsílẹ̀ yìí tàbí kí o ṣe àkójọ tìrẹ fún ọ̀nà l'àti gbé Olúwa ga.
• Àǹfààní ńlá ló jẹ́ l'áti wá s'íwájú Ẹlẹ́dàá; bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní fi èrò yìí s'ínú ẹ̀mí rẹ!
• Má fi Ọlọ́run sí ìgbẹ̀yìn ohun tí òún ṣe l'ójoojúmọ́.
• Rú ọpẹ́ s'ókè l'áti odò ọkàn rẹ wá.
Nípa Ìpèsè yìí
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!
More