Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ọjọ́ 4 nínú 7

KÍNI Ó KÚN ỌKÀN RẸ?

"Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò."Fílípì 4:8

Àwọn ènìyàn kò máa dúpé nítorí pé ọ̀kan wọn kún fún oríṣiríṣi ǹkan. Ǹjẹ́ o ti lẹ̀ dà bíi pé ọwọ́ rẹ dí tí o kò lè dúró fi ara balẹ̀ kí ojúlùmọ̀ kan? Ní ọ̀nà míràn ẹ̀wẹ̀, ọwọ́ rẹ dí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí o kò náání àwọn ohun tó ṣe pàtàkì mọ́. Ilé ayé kìkì hílàhílo. Tí o kò bá tíì ṣiṣẹ́ f'ẹ̀hìn tì, ojoojúmọ̀ rẹ lè kún fún iṣẹ́, ọmọ, ilé ẹ̀kọ́, àwọn eré olọ́kan-ò-jọ̀kan, ilé ìjọ́sìn, ìyànda-ara-ẹni, eré ìdárayá, ìrìnàjò lọ s'ọ́jà, àjùmọ̀ wọ ọkọ̀ ìrìnà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo.

Yálà o kò ti lẹ̀ kìí ṣe nkankan nínú àwọn èyí, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ọkàn rẹ ti kún fún ìfẹ́kúùfẹ́, àwòrán oníhòòhò, ọtí mímu, wòbìà, tàbí àwọn eré ojú iworan tí kò yẹ kí o máa wò.

Àwọn ènìyàn ti kọ́ ìgbé ayé tó dà bíi èyí tó tọ́ l'áwùjọ. A gbọ́dọ̀ ṣe ‘ohun gbogbo’ bíi ẹni pé a ṣeé sí Ọlọ́run! N'ígbà tí a bá ń ṣe ohunkóhun fún Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ma ṣe wọ́n pẹ̀lú ọkàn t'ó ń dúpẹ́. Tí a bá mọ̀ pé ohun tí à ún ṣe kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, à ó mọ̀ pé a kò wá s'íwájú Rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ.

Ǹjẹ́ mo ti sọ nípa ìfẹ̀yìntì? Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀kan wa lè kún fún ohun tí a ó ṣe n'ígbà tí a bá f'ẹ̀hìn tì, bíi ìrìn-àjò, gbígbá boolu kékeré tí a ún f'igi gba, ìyẹn gọ́lfùù, ṣíṣe ìkẹ́ àwọn ọmọọmọ, àti bíbá àwọn ọ̀rẹ́ jẹun. Ọwọ́ wa lè dí nípa ṣíṣe àwọn ohun-àṣe-najú àti iṣẹ́-ọnà àti gbogbo àwọn ǹkan a-duni-nínú tí a fi kún ọkàn wa dípò àwọn ǹkan ìmọ̀ore. Ní tòótọ́ kò burú l'áti ṣe nínú àwọn ǹkan tí a ti m'ẹ́nu bà ní ẹ̀kọ́ tòní, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kọ́ l'áti ṣe gbogbo rẹ̀ n'ígbà tí à ún fí Jésù ṣe àárín gbùngbùn ìdojúkọ wa àti pẹ̀lú ọkàn t'ó ń dúpẹ́.

Romu 12:2 rán wa l'étí kí á má ṣe dọ́gba pẹ̀lú gbèdéke ayé ṣùgbọ́n kí á ní ìyípadà nípa sísọ ọkàn wa di ọ̀tun!

Báwo ni a ṣe ń yí ọkàn wa padà?

L'ákọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ mọ ohun t'ó ń tì wá àti ìdí pàtó tí a fi ń fẹ́ máa ṣe ohun tí à ń ṣe. Má fi ara pa mọ́ n'íwájú Olúwa, nínú ìtàkùrọ̀sọ pelu Rẹ̀, bèèrè l'ọ́wọ́ ara rẹ bí gbogbo akitiyan rẹ bá ń polongo ara rẹ kí àwọn ènìyàn lè gbé orí yìn fún ọ. O mọ̀ pé ohun t'ó gba ọkàn rẹ kan ni ohun t'ó ń wá ti ara rẹ̀ nìkan. T'ó bá ṣe ìwọ ni, béèrè ìdáríjì l'ọ́wọ́ Ọlọ́run àti fún ìrànlọ́wọ́ l'áti yí àwọn ohun t'ó gba ọkàn rẹ padà.

IṢẸ́ ÀKÀNṢE T'ÒNÍ:

· Tí o bá ríi pé ọwọ́ rẹ kún jù, ṣe àṣàrò bí o ti ṣè dín-in kù.

· Tí ọkàn rẹ bá kún fún irúfẹ́ ohun ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ta àbùkù bá ìrìn rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, lo s'ọ́dọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn t'ó dájú kí o sì bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

· Ṣe àyẹ̀wò aládáṣe l'áti fi múlẹ̀ bí ó bá ṣe pé àwọn ìṣe ati akitiyan rẹ ń wá tí ara rẹ nìkan tàbí ti ògo Ọlọ́run.

· Pin'nu l'áti wá ààyè nínú ayé rẹ fún ìdúpẹ́ àti ayọ̀!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Eternity Matters With Norma tí wọ́n ṣ'ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.facebook.com/eternitymatterswithnorma