Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ọjọ́ 2 nínú 7

NJẸ́ Ẹ̀MÍ INÚ RẸ Ń FÒ FUN AYỌ̀?

"Olúwa ni okun mi àti apata mi; ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn-àyà mi ń fò sókè fún ìdùnnú, èmi yóò sì fi orin mi yìn ín. Sáàmù 28:7

Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń gbára lé òjò àti oòrùn tó ń ràn dáadáa láti mú kí irè oko rẹ̀ dàgbà, àwa náà gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Kristi pátápátá torí pé a jẹ́ onígbàgbọ́ àti ọmọlẹ́yìn Rẹ̀! Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa lónìí sọ ibi tí agbára wa ti ń wá. Ó wá lát'ọ̀dọ̀ Olúwa, ìdùnnú rẹ̀ sì ń fún wa lókun láti kojú àwọn ìṣòro ojoojúmọ́.

Nínú ẹ́kọ̀ọ́ wa àná, a kọ́ nípa obìnrin kan tí ayọ̀ rẹ̀ ń tàn láti inú lọ́hùn-ún, àti pé nínú ayọ̀ yẹn, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ kọ orin kan! Nínú ipò àìnírètí wa, tí a kò mọ̀ bóyá owó oṣù tó láti san àwọn ìnáwó wa, tàbí nígbà tí a bá fún ẹni tí a fẹ́ràn ní àyèwò tí kò dára, ṣé a jìnlẹ̀ tó nínú Olúwa láti gbẹ́kẹ̀lé È nínú ipò wa àti láti gbé orin ìyìn sókè?

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa ń jẹun lọ́pọ̀ ìgbà l'ójúmọ́ láti fún ara wa lókun, bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe ní láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ọkàn wa lójoojúmọ́, kí a sì máa gbàdúrà kí a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó jinlẹ̀.

Ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn, èmi àti ọkọ mi gbọ́ àyẹ̀wò tó le koko pé kò sí ohun mìíràn tí dókítà lè ṣe láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Èyí jẹ́ Òkúdù 22, 2017. Ààrùn náà jẹ́ èyí t'ó ń dàgbà nínú ọ̀nà-ọ̀fun àti ọkàn rẹ̀. Dan, ọkọ mi, kò lè jẹun mọ́, kò lè mu mọ́, kò sì lè gbé nǹkan mì mọ́. Ó pàdé Olúwa wa ní nǹkan bí oṣù méjì lẹ́yìn náà. Dan kò lè pèsè oúnjẹ fún ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ ti kó oúnjẹ t'ẹ̀mí jọ láti gbé e ró ní gbogbo ọjọ́ wọ̀nyẹn.

Agbára inú rẹ̀ tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún-un mú kó lè máa lọ s'ọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n sé mọ́ ilé, ó sì máa ń kọ àwọn orin ìhìnrere láti mú kí inú wọn dùn!

Àkókò kan máa dé nínú ìgbésí ayé wa nígbà tí a bá gbẹ́kẹ̀ lé E pátápátá tàbí tí a bá ríi pé ìgbàgbọ́ wa kò rí bí a ṣe rò. Àkókò nìyí láti dìde s'ókè tàbí láti dákẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ líle ni, àmọ́ ó jẹ́ kí a rí kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà. A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Kristiẹni tí wọ́n ń wá ilé ìjọsìn ṣùgbọ́n tí wọn kò ní okun inú fún ọjọ́ 6 tó kù! Wọ́n máa ń sọ̀rọ̀, àmọ́ wọn kìí ṣe ohun tí wọ́n ń sọ. Ìgbà tí a bá kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nínú "ohun gbogbo" nìkan ni ìdúpẹ́ àti ayọ̀ yóò máa tàn jáde láti inú wa!

ÌṢE ÀKÀNṢE T'ÒNÍ:

· Máa dúpẹ́ wákàtí sí wákàtí.

· P'ète láti gbé orin kan jáde láti inú rẹ.

· Bí o bá ti fi oúnjẹ bọ́ ara rẹ lónìí, o ní láti bọ́ ọkàn rẹ.

· Àkókò nìyí láti dìde s'ókè tàbí láti dákẹ́.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Eternity Matters With Norma tí wọ́n ṣ'ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.facebook.com/eternitymatterswithnorma