Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ọjọ́ 7 nínú 7

MA DÚPẸ́ FÚN OHUN KÉKERÉ

Ẹnì kan sọ fún mi nígbà kan pẹ̀lú àwàdà pé, ‘Bí ó bá náni ju ìdá mẹ́rin lọ, dúpẹ́!” Bí mo ṣe ń kọ ìwé ìfọkànsìn yìí, n kò lè ronú jinlẹ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú 1 Thessalonians 5:18.

“Nínú ohun gbogbo, ẹ mã dúpẹ́: nít'orí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run nínú Krístì Jésù."

Ìyàlẹ́nu ni ó Jẹ́ ní ìgbà gbogbo àwọn nǹkan kékeré ní ìgbẹyìn ni ó má ń jọjú jùlọ.

• Ronú nípa ọmọ kékeré yẹn tí yóò fi tìfẹ́tìfẹ́ fún ọ ní òdòdó dandelion kan pẹ̀lú ẹ̀rín títóbi jù lọ bí o ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn!
• Ronú ti àkọsílẹ̀ ti à tẹ̀jáde tí a fi ọwọ́ kọ tí o ríi tí a fi pamọ́ sínú àpótí láti ọ̀dọ̀ olùfẹ́ kan tí ó ti kọjá lọ.
• Ronú ti àjòjì èèyàn yẹn tí ó dúró láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ ní ọ̀nà.
• Báwo ni nípa ìpè aìròtẹ́lẹ̀ yẹn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ kan tí ó kò tí gbọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ọdún tó típẹ́?
• Awọn tí ó dì mọ́ ọ ní òwúrọ̀ láti ọ̀dọ̀ ọmọ rẹ tàbí ọmọ-ọmọ, tàbí ọkọ àti ìyàwó re.
• Ẹsẹ̀ ohun ọ̀sìn rẹ lórí apá rẹ tí ó fẹ́ ìfẹ́ rẹ.

Dájúdájú, ìwọ nyí Jẹ́ àwọn èrò díè láti mú ìrántí àwọn nǹkan kékeré tí ó túmọ̀ púpọ̀ sí ọ.Tí ènìyàn kò bá tọ́jú ọkọ̀ ayọ̀kẹ́lẹ́ ti àtijọ́ yẹn, tí a fun ní àkọ́kọ́ ìwúlò, ó ṣé ẹṣẹ pé wọ́n kìí yóò tọ́jú ọkọ̀ ayọ̀kẹ́lẹ́ tuntun míràn ni awọn ọdún tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú

"Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ, ó sì jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòótọ́ nínú ohun kékeré jẹ́ aláìṣòótọ́ nínú ohun púpọ̀ pẹ̀lú.”Luke 16:10

Mo ti máa ń ṣe kàyéfì lọ́pọ̀ ìgbà bóyá Ọlọ́run dán wa wò pẹ̀lú ohun díẹ̀ láti rí bí a ṣe kún fún ọpẹ́ tó. Èyí dá wa padà sí ọjọ́ kiní nínú àyọkà yíì. Rántí ìyá onírẹ̀lẹ̀ ní Afíríkà tí ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ láti kọ orin ayọ̀. Ní iwájú wá a rí oun kékeré; síbẹ̀ lójú wọn, wọ́n ní ìmọ̀lára ìbùkún ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì ń yọ̀ nínú rẹ̀. Wọ́n ti kọ́ ẹ̀kọ́ láti kórè ìdúpẹ ní gbogbo ọdún yíká! Ẹ jẹ́ kí á kọ́ láti ara ohun tí wọ́n ní!

IṢẸ́ ÀKÀNṢE TÒNÍ:

• Ní àkókò láti ṣe àlàyé lórí atọ́ka ti àwọn nkan kékeré tí ó túmọ̀ púpọ̀ sí ọ.

• Rántí pé ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan kékeré láti parí àwọn ohun ńlá: àwọn èékánná ṣe pàtàkì bíi igi tí ó kọ́ ilẹ̀!

• BÍ o bá ṣeé ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ní o si maa n rorun.

• Idi lati ‘Kore Idupẹ Ni Gbogbo Ọdun!”

Tí o bá gbádùn ìfọkànsìn yìí, mo gba ọ níyànjú láti tẹ ẹ̀rọ aṣàwákiri You Version, Eternity Matters With Norma àti àwọn ìfọkànsìn mìíràn tí Norma kọ yóò farahàn.

Akọ̀wé àti àwọn iṣẹ́ mìíràn ni a lè ríi ní http://facebook.com/eternitymatterswithnorma.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Eternity Matters With Norma tí wọ́n ṣ'ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.facebook.com/eternitymatterswithnorma