Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ

Bolder: A Look at the Audacious Faith of Imperfect People

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ọjọ́ Kìíní: Pétérù

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ti ka Bíbélì tàbí tí wọ́n ti wo ohunkóhun tí ó dá lórí Bíbélì ni wọ́n ti gbọ́ ìtàn nípa bí Pétérù ṣe rìn lórí omi, èyí sì ti mú kí wọ́n "jáde nínú ọkọ̀ ojú omi" pẹ̀lú ìgboyà ìgbàgbọ́. Bí Jésù ṣe rìn lórí omi wà nínú mẹ́ta nínú àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rin tí ó sọ nípa ìgbésí ayé Jésù (ìyẹn Mátíù, Máàkù àti Jòhánù), ṣúgbọ́n ọ̀kan tí ó m'ẹ́nuba ipa tí Pétérù kó ni Mátíù. Ṣe àkíyèsí ìtọ́ni tààràtà tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn nínú àkọsílẹ̀ Mátíù. Mátíù ṣe àpèjúwe bí Jésú ṣe sọ fún wọn láti bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi náà. Gbogbo àkọsílẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n kọ wípé Jésù sọ pé "Èmi ni; ẹ má fòyà". Ohun tí Jésù ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n bẹ̀rù. Kò sí ìdìí láti bẹ̀rù nítorí pé Jésù ni, ó sì wà pẹ̀lú wọ́n. Àmọ́, àbá tani ó jẹ́ kí Pétérù jáde nínú ọkọ̀ náà? Àbá Pétérù fúneaarẹ̀ ni. Jésù gbà, ṣùgbọ́n Jésù kò kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ohun tí ó ṣe Ni pé Ó ní kí--ó má bẹ̀rù--Pétérù kùnà ní (ẹsẹ 30). Àmọ́, ẹ jẹ́ ká wo bí ìtàn náà ṣe parí. Ẹnú ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run. A ti mú u dá wọn lójú pé Jésù "ni Ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́."

Irú ìwà àṣejù àti ìwà àìbìkítà yìí jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ lára Pétérù gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìnrere. A rí i tí ó ń sọ àwọn nǹkan ńláńlá tí kò lè mú ṣẹ (bí àpẹẹrẹ, ó sẹ́ pé òun kò mọ Jésù lẹ́yìn tí ó sọ pé òun yíó kú fún un), a rí i tí ó gé etí ọkùnrin kan, a rí i tí ó ń sọ̀rọ̀ láìronú lọ́pọ̀ ìgbà, a sì rí i tí ó ń fí ìbáwí tọ́ Jésù fúnraarẹ̀ s'ọ́nà. Àmọ́ a tún rí i tí ó ń darí ìjọ àkọ́kọ́ ní ọ̀nà tí ó kàmàmà. Nínú Ìṣe 2 a rí Pétérù--tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́--tí ó kó ipa nínú wíwo ọkùnrin arọ kan sàn, tí ó dúró lójú inúnibíni, tí ó sì wàásù tí ó lágbára lẹ́yìn èyí tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn gbàgbọ́ nínú Jésù. Ṣé ọkùnrin kannáà nìyìí?

Jésù sábà máa ń tọ́ Pétérù sọ́nà (a sì dúpẹ́ pé Ó wo ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ sàn!), àmọ́ Jésù mú Pétérù, bíótilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣe nǹkan ṣáájú kí ó tó ronú, ó sì yan án láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ìjọ rẹ̀. Kíni ìdí? Ó hàn kedere pé Pétérù ní ọ̀pọ̀ kùdìẹ̀-kudiẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì ṣe àṣìṣe. Àmọ́, Jésù rí i pé Pétérù ní ànímọ́ kan tí Òún lè lò. Pétérù ní láti dàgbà, àmọ́ àwọn ohun tí yíó ràn án lọ́wọ́ wà níbẹ̀. Pétérù múra tán láti fi wọ́n rúbọ, kí ó jẹ́ kí Jésù tọ́ òun sọ́nà nígbà tí ó bá yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, kí ó sì máa wo Jésù.

Àṣàrò/Ìbéèrè Ìjíròrò:

1. Ẹ̀kọ́ wo ni o rí kọ́ láti inú kíka àkọsílẹ̀ àwọn ọkùnrin mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n kọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kannáà?

2. Kíni ìdí tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan péré lára àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́ta tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ó m'ẹ́nu bà á pé Pétérù kópa nínú rẹ̀?

3. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbàgbọ́ pé ìhìnrere Máàkù jẹ́ ìtàn ìgbésí ayé Jésù tí Pétérù kọ, pé Máàkù kọ ọ́ sílẹ̀ fún Pétérù ni. Bí ó bá jẹ́ pé òótọ́ ni, kíni ìdí tí o kò níi jẹ́ kí wọ́n sọ fún gbogbo ènìyàn nípa ìgbà tí o rìn lórí omi?

4. Àwọn okun tàbí àìlera wo ni o ní tí Jésù lè lò?

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Bolder: A Look at the Audacious Faith of Imperfect People

Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.

More

A fẹ́ dùpẹ́ lọ́wọ́ Berea fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://berea.org