Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ

Bolder: A Look at the Audacious Faith of Imperfect People

Ọjọ́ 3 nínú 7

Ọjọ́ Kẹta: Stéfànú

Stéfànú ni Krìstìẹ́nì àkọ́kọ́ tí ó kú ikú ajẹ́rìíkú (ẹni tí wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn) lẹ́yìn tí ó sọ àsọyé gbígbóná janjan fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan nínú èyí tí ó sọ ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Stéfànú ṣe àlàyé láìfọ̀rọ̀ s'ábẹ́ ahọ́n sọ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kọ Ọlọ́run sílẹ̀ léraléra, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dáàbò bò wọ́n Ó sì gbà wọ́n là léraléra. Àmọ́ Stéfànú kò bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ amúbíiná. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi ṣíṣe ìránṣẹ́ tábìlì. Nínú Ìṣe orí kẹfà, a rí i pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń gbìyànjú láti yanjú ìṣòro kan. Iṣẹ́ tí wọ́n ní láti ṣe ti pọ̀ jù. Àwọn opó wà tí wọ́n ní láti bójú tó, àmọ́ ìhìnrere Jésù náà ní láti tàn k'álẹ̀! Wọn ò gbọ́dọ̀ gbójú fo bíbójú tó àwọn ènìyàn tàbí títan ìhìnrere ká. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá ìrànlọ́wọ́ lọ.

Ohun kan tí ó gba àfiyèsí nípa bí wọ́n ṣe yan àwọn tí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ ni bí àwọn ìlànà náà ṣe ga tó. Ó lè máa ṣe ènìyàn ní kàyééfì bóyá ó tilẹ̀ ṣe pàtàkì láti mọ irú ẹni tí ó ń pèsè oúnjẹ fún àwọn opó bí i kí àwọn opó ṣáà ti jẹun ni. Ṣúgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń wá irú ènìyàn kan pàtó láti ṣe iṣẹ́ náà: "àwọn ọkùnrin tí ó ní orúkọ rere," "tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́," àti "tí ó kún fún ọgbọ́n." Kíni ìdí tí áwọn ànímọ́ yìí fi ṣe pàtàkì fún iṣẹ́ náà?

Stéfànú ni wọ́n yàn láti ṣe iṣẹ́ yìí pẹ̀lú àwọn mẹ́fà mìíràn, Bíbélì sì ṣ'àpèjúwe rẹ̀ ní pàtó pé ó "kún fún Ẹ̀mí mímọ́". A tún ṣ'àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó "kún fún ìgbàgbọ́ àti agbára" tí ó sì lè ṣe "iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu" (6:8). Ọ̀nà tí Stéfànú gbà ta yọ lọ́pọ̀lọpọ̀ jẹ́ kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wò ó gẹ́gẹ́ bí ewu. Wọ́n tilẹ̀ wá àwọn ẹlẹ́rìí èké láti parọ́ mọ́ ọ, wọ́n sọ pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n sì pa Stéfànú nítorí èyí.

O lè máa rò ó lọ́kàn ara rẹ báyìí pé, "Ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe agbọ̀rọ̀sọ, èmi kì í ṣe onígboyà, tí ẹnikẹ́ni bá sì gbìyànjú láti pa mí, màá sá lọ. Mi ò lè ṣe bí Stéfànú." Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé kì í ṣe bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ní ìgbà tí a bá m'ẹ́nuba àwọn iṣẹ́ ìgboyà rẹ̀, ohun tí ó tẹ̀lé e ni pé ó "kún fún Ẹ̀mí Mímọ́" ó sì "kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára." Nínú Bíbélì, ní ìgbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá wà l'ára ẹnìkan, wọn á ní agbára. Nígbà míìràn, agbára ara ni (wo Sámúsìnì nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́), àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, agbára láti ṣe nǹkan tàbí láti sọ ohun tí wọn kò lè ṣe tẹ́lẹ̀ ni. L'édè mìíràn, bí o kò bá ní ìgboyà láti ṣe ohun tí ó o mọ̀ pé ó tọ́, Ẹ̀mí mímọ́ lè fún ọ ní ìgboyà! O lè kojú ikú tàbí kí ó má rìí bẹ́ẹ̀ látàrí pè o ń tẹ̀lé Jésù bí Stéfànù ti ṣe, ṣùgbọ́n mọ̀ pé Ẹ̀mí kannáà tí ó fún un ní ìgboyà láti dúró ṣinṣin fún Jésù lójú ìpalára (kódà, lójú ikú) ni ẹni tí ó ń gbé inú rẹ nígbà tí o bá yàn láti tẹ̀lé Jésù.

Àṣàrò/Ìbéèrè Ìjíròrò:

1. Báwo ni àbájáde tí ó wà nínú Ìṣe 6:7 ṣe tan mọ́ àwọn ìlànà tí a fi yan áwọn òṣìṣẹ́ nínú Ìṣe 6:3?

2. Àwọn nǹkan wo lo se àkíyèsí pé Stéfànú àti Jésù fi jọra?

3. Bí o bá ti yàn láti tẹ̀lé Jésù, láti tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀ fún ọ, kí o sì fi ìgbésí ayé rẹ fún un, ǹjẹ́ o ti rí bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

4. Bí o kò bá tíì ṣe ìpinnu yẹn, kíni ohun ìdènà tàbí ìbéèrè kan tí o ní, báwo ni o ṣe lè wá ìdáhùn sí i?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Bolder: A Look at the Audacious Faith of Imperfect People

Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.

More

A fẹ́ dùpẹ́ lọ́wọ́ Berea fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://berea.org