Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ

Bolder: A Look at the Audacious Faith of Imperfect People

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ọjọ́ Kejì: Ẹ́sítérì

À ń sáré lọ sí àárín ìtàn náà ní orí kẹrin, nítorí náà ẹ jẹ́ kí á mú ohun tí ó wà nínú ìwé Ẹ́sítérì náà wá (Ẹ lè ka gbogbo ìwé Ẹ́sítérì tí ó bá wù yín!): Ẹ́sítérì, Júù kan, ni a sọ di ayaba lẹ́yìn tí Xerxes Ọba Páṣíà (tàbí Ahaswérúsì ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ) korò ojú sí ìyàwó rẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Hámánì tí ó jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún Ọba Xerxes kórìíra Módékáì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n bàbá Ẹ́sítérì gan-an nítorí pé Módékáì kọ̀ láti tẹríba fún un (nítorí pé Ọlọ́run nìkan ni àwọn Júù máa ń tẹríba fún). Hámánì nawọ́ ìkórìía yìí sí gbogbo àwọn Júù, ó sì yí òótọ́ padà fún Ọba Ahasuwérúsì pé ó yẹ kí wọ́n pa gbogbo wọn run. Ọba náà gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé tí kò tọ́ àti pé wọ́n fi ohun tí kò tọ́ tóo l'étí.

Nínú ìwé Ẹ́sítérì orí kẹrin, Módékáì pe Ẹ́sítérì n'íjà pé kí ó lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ayaba láti gba àwọn Júù là. Ìlọ́ra Ésítérì bá ọgbọ́n mu níwọ̀n bi ó ti jẹ́ pé ìdí tí ó fi wà ní ipò rẹ̀ ni pé ọba korò ojú sí ayaba àná, o sì kan ọ́ sílẹ̀, kò sì tíì pè òun láti rí i fún odindi oṣù kan. Ṣé yíó tilẹ̀ jẹ́ kí òun bá a sọ̀rọ̀? Ó lè pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ bí ó bá lọ sọ́dọ̀ ọba láìjẹ́ pé ọba pè é.

Ìgboyà tí Ẹ́sítérì ní nígbà tí ó dojú kọ ikú kò ṣà déédé rí bẹ́ẹ̀. Ohun méjì ni ó jọ pé ó mú kí ó gbé ìgbésẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bẹ̀rù fún ẹ̀mí rẹ̀: ọ̀rọ̀ ìwúrí àti ìtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀. Bí o bá ń ṣe eré ìdárayá tàbí tí o ti wo fíìmù nípa eré ìdárayá, o lè fojú inú wo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀: Olùkọ́ tàbí adarí-égbẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ìwúrí, tí ó sì ń rán àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ náà létí ìdí tí ó fi yẹ kí wọ́n máa bá eré ìdárayá nìṣó kódà nígbà tí wọ́n bá rẹ̀wẹ̀sì. Àsìkò náà jẹ́ kí égbẹ́ náà mọ̀ wípé àwọn wà papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́, ó sì mú u dá wọn lójú wípé bí ó ti wù kí nǹkan rí, awọ́n wà nínú rẹ̀ papọ̀, àwọ́n sì lè fọkàn tán ara wọn ní ìta. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ẹ́sítérì náà nìyẹn. Nígbà tí ọ̀rọ̀ tí Módékáì sọ mú kí ó gbà pé ó yẹ kí òun lọ bá ọba, ó níílò àtìlẹyìn. Ó ní kí àwọn tí wọ́n súnmọ́ òun jùlọ d'arapọ̀ mọ́ òun nínú ààwẹ̀ gbígbà láti múra sílẹ̀ fún àkókò tí òun máa lọ rí ọba, ó sì ní kí Módékáì sọ fún gbogbo àwọn tí ó bá lè d'arapọ̀ mọ́ òun náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Kì í ṣe Ẹ́sítérì nìkan ni ọ̀rọ̀ Módékáì tí ó wà nínú orí 4:14 mú kí ó ṣe ohun tí ó tọ́, ó ti mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ohun tí ó tọ́ láìka ìbẹ̀rù tí wọ́n ní sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìràn lẹ́yìn ìgbà yìí. Ọ̀rọ̀ yìí "gbani n'íyànjú" wá láti inú èrò pé kí á fúnni ní ìgboyà. A rí ìgboyà Ẹ́sítérì nínú bí ó ṣe múra tán láti lọ bá ọba àti bí ó ṣe múra (ó ṣe ètò kan), a sì rí ìgboyà Módékáì nígbà tí ó fún ọbàkan rẹ̀ ní ìgboyà láti lo ohun tí ó ní fún ire àwọn ènìyàn.

Àṣàrò/Ìbéèrè Ìjíròrò:

1. Ìgbà wo ni ẹ̀rù bà ọ́ láti ṣe ohun kan tí o mọ̀ pé ó yẹ kí o ṣe, tí ìgbaniníyànjú ẹnìkan sì mú ìyàtọ̀ dé bá ọ?

2. Tani ẹnìkan nínú ìgbésí ayé rẹ báyìí tí o lè fún ní ìgboyà rẹ?

3. Ǹjẹ́ o lè ran ẹnìkan lọ́wọ́ nísinsìnyí, àmọ́ tí ìbẹ̀rù kò jẹ́ kí o ṣe bẹ́ẹ̀? Kíni ìgbésẹ̀ kan tí o lè gbé láti ní ìgboyà tí o níílò?

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Bolder: A Look at the Audacious Faith of Imperfect People

Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.

More

A fẹ́ dùpẹ́ lọ́wọ́ Berea fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://berea.org