Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ
Ọjọ́ Kẹfà: Obìnrin tí a mú L'áradá
Mátíù, Máàkù àti Lúùkù sọ ìtàn obìnrin kan tí ó wá ìwòsàn lọ s'ọ́dọ̀ Jésù. Ẹ̀rù ń bà á láti sọ fún Jésù pé kí ó wo òun sàn, nítorí náà, ó kàn f'ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jésù, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ó ní agbára tí ó pọ̀ tó láti wo òun sàn l'ọ́nà yìí. Fi ara rẹ̀ sí ipò rẹ̀ fún ìṣẹ́jú kan. Ọdún méjìlá rèé tí ó ti ń ṣ'àìsàn. Ronú nípa ẹnìkan tí o mọ̀ tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, tàbí ó jẹ́ pé ìwọ náà jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá. Èyí ni gbogbo ìgbésí ayé wọn (tàbí tìrẹ)! Láìka ọjọ́ orí rẹ sí, ọdún méjìlá jẹ́ àkókò gígùn láti ṣ'àìsàn. Àìsàn obìnrin náà mú kí ó máa da ẹ̀jẹ̀. Ní ti ìṣègùn, èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe kí ó máa rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu ní gbogbo ìgbà, ó sì ṣeé ṣe kí ó máa lè ṣe àwọn iṣẹ́ ojoojúmọ́ bí ó ṣe yẹ. Ní ti ẹ̀sìn, gẹ́gẹ́ bíi Júù, èyí túmọ̀ sí pé ó jẹ́ "aláìmọ́" kò sì lè kó ipa nínú àwọn ìgbòkègbodò ẹ̀sìn--fún ọdún méjìlá. Ẹ wo bí àárẹ̀ á ṣe mú un tó àti bí ó ṣe máa dàbíi pé kò sí ẹni tí ó rí t'òun rò. Yàtọ̀ sí ìyẹn, kò sí dókítà tí ó lè ràn án lọ́wọ́, kò sì l'ówó tí ó lè fi ṣe nǹkan míìràn. Kíni ó tún lè ṣe pàápàá?
Lẹ́yìn náà, Jésù ń rìn kiri la ìlú náà já, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí ó jẹ́ olókìkí sì ní kí ó wá sí ilé òun kí ó lè wo ọmọbìnrin òun sàn. Ó dájú pé obìnrin yìí ti gbọ́ nípa Jésù àti ohun tí ó lè ṣe, torí ó rò pé bí óun bá fi ọwọ́ kan ẹ̀wù rẹ̀, ara òun yíó yá. Yálà ó ń gbìyànjú láti má ṣe da Jésù láàmú ni o tàbí ó ń tijú láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ (tàbí kó jẹ́ pé méjèèjì ló rí bẹ́ẹ̀), ó ṣe é - ó sì ṣiṣẹ́! Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún obìnrin náà, ó sì dàbíi pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí òun, àmọ́ Jésù dáwọ́ ohun tí ó ń ṣe dúró, ó sì bá a sọ̀rọ̀.
Wàyí o, f'ojú inú wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn. O ti ń gbìyànjú láti rìn láìsí ẹni tí ó rí ọ, o rí ohun tí ò ń wá, nígbà náà ni Jésù dá àwọn èrò dúró, ó sì béèrè pé, "Tani ó f'ọwọ́ kàn mí?" Bí o bá sálọ, ó lè hàn kedere. Bí o bá ń wò yíká bí ẹni pé kì í ṣe ìwọ ni, ṣé ó ṣì máa mọ̀, yíó sì wá burú sí i ní ìgbà tí wọ́n bá pè ọ pé oò sọ nǹkan kan ni? Obìnrin náà pinnu láti jẹ́wọ́, ó sì d'orí k'odò, ó gbà pé òun ni òun ṣe é--níwájú gbogbo ènìyàn. Fún gbogbo àwà ti a ní àǹfààní láti ka Bíbélì tí a sì ti rí bí Jésù ṣe máa ń bá àwọn ènìyàn ṣe, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé ohun tí Jésù ṣe ní pé Ó fí àànú hàn, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ó ya obìnrin yìí àtí àwọn tí ó wà láyìíká rẹ̀ lẹ́nu. Bí Ó ṣe ń sáré lọ ran ẹlòmíràn lọ́wọ́, Jésù dúró díẹ̀, ó sì bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, ó yìn ín fún ìgbàgbọ́ rẹ̀. Jésù sọ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ló mú kí ara rẹ̀ yá. Ìgbàgbọ́ rẹ̀? Ó gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ẹni tí òun jẹ́, ó sì ṣe é ní ìkọ̀kọ̀. Kò fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa wo òun, ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ rárá; ó ṣeé ṣe kí ó rò pé òun ò yẹ l'ẹ́ni tí ó lè béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Àmọ́ nígbà tí ó fi máa di ìrọ̀lẹ́, ó ṣì lọ bá Jésù pẹ̀lú gbogbo ìgboyà tí ó ní, ìyẹn náà sì ti tó. Jésù kò béèrè fún ìgbàgbọ́ ńlá ní ìfiwéra pẹ̀lú ti ẹlòmííràn; ó kàn ń béèrè pé kí a wá sọ́dọ̀ òun pẹ̀lú ìgbàgbọ́ èyíkéyìí tí a bá ní. Ó gba ìgboyà láti ṣe èyí, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé, yíó gbé ìgbésẹ̀ láti ibẹ̀ lọ
Àṣàrò/Ìbéèré Ìjíròrò:
1. Ǹjẹ́ apá ibìkan wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí o kò ti ní ìgboyà nítorí o rò pé o kò yẹ?
2. Ǹjẹ́ o ti rí Jésù tí ó mú ohun kan tí o rò pé kò dára rárá, tí ó sì fi ṣe ohun àgbàyanu kan? Ṣ'àlàyé tàbí kí ó ṣ'àfihàn rẹ̀.
3. Kíni ohun kan tí o rò pé ó yẹ kí o mú wá fún Jésù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà ọ́?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.
More