Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ
Ọjọ́ Karùn-ún: Nátánì
Ṣé o rántí Dáfídì tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lánàá? Ọkùnrin àtàtà ni. Àyàfi ìgbà tí ó bá fi àyọ fọ́ ọ. Dáfídì ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ fún ìyìn, bíi pé ó fi ara mọ́ ìpinnu Ọlọ́run pé kí ó sọ òun di ọba, ó sì fi sùúrù dúró kí Ọlọ́run tó sọ ọ́ di ọba. (Ó dúró de ìgbà tí ìṣàkóso Sọ́ọ̀lù dópin dípò kí ó fi ipá mú ara rẹ̀ g'orí ìtẹ́ kí ó tó di pé Ọlọ́run fẹ́ bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ Dáfídì tún ṣe àwọn àṣìṣe kan tó burú jáì. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ìgbà tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn ṣe àgbèrè, tí ó sì pa ọkùnrin náà lójú ogun; ó pa ọkùnrin náà láti fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pa mọ́. Àmọ́ Dáfídì ni ọba ní àkókò yẹn, tani o wá lè sọ pé òun ló jẹ̀bi ohun tí ó ṣe yẹn? Tani yíó lè fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ọba, tí wọn kò sì ní pa òun fúnra rẹ̀?
Wòlíì Nátánì wọlé wá. Gẹ́gẹ́ bí wòlíì, Nátánì jẹ́ aṣojú Ọlọ́run fún áwọn ènìyààn. Àmọ́, ènìyàn lásán ni Nátánì. Bí o bá ka ìwé àwọn Ọba àti Àwọn Króníkà, wíwà ní ìhà Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé àwọn ọba kò ní gbìyànjú láti pa ọ́ bí wọn kò bá fẹ́ ohun tí Ọlọ́run ní láti sọ nípasẹ̀ rẹ. Nítorí náà, Nátánì wà nínú ipò tí ó léwu, àmọ́ ó fi ìgboyà ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì lọ k'ojú Dáfídì. Àmọ́, ọ̀nà tí Nátánì gbà bá Dáfídì sọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀nà tí ó tayọ (ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Ọlọ́run ni ó rán an ní tààràtáárá). Nátánì mọ̀ pé Dáfídì yíó bínú (ní gbogbo ìgbà, tani kò níi bínú nígbà tí wọ́n bá tú u l'ásìírí?), ṣùgbọ́n Nátánì rí ọ̀nà láti d'arí ìbínú Dáfídì sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó jáfáfá. Nátánì sọ ìtàn kan fún Dáfídì, èyí tí o kà nínú Ìwé Mímọ́ ti òní. Inú bí Dáfídì gan-an nígbà tí ó rí bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ṣe hùwà sí òtòṣì náà, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa ọkùnrin náà. Nígbà náà ni Nátánì sọ pé: "Ìwọ ni ọkùnrin náà".
Fojú inú wo bí ó ṣe máa rí l'ára Nátánì, iye ìgbà ti yíó ti fi ìtàn náà dánra wò, tí yíó sì máa ronú ibibtí ọ̀rọ̀ náà yíò y'ọrí sí. Ìdààmú yíó ti bá a, bí jìnnìjìnnì kò bá tilẹ̀ bò ó. Nígbà tí àkókò tó, ǹjẹ́ ó lọ́ tìkọ̀? Ǹjẹ́ ó ní láti mí èémí gígùn kanlẹ̀? Gbogbo ohun tí a mọ̀ ni pé ó sọ ọ́. Ó tú àsírí Dáfídì, láìka ipò Dáfídì tàbí ohun tí ìdáhùn yíó jẹ́ sí. Fún oríire Nátánì, ati ìjólótitọ̀ Dáfídì, Dáfídì jẹ́wọ́.
Ọ̀rọ̀ náà yí padà l'ójú ésẹ̀. Èsì tí Nátánì fọ̀ sí ìrẹ̀lẹ̀, ìmọ̀wọ̀n-ara-éni àti ìjẹ́wọ́ Dáfídì ní ìkáànú. Nátánì kàn ń sọ ìdáhùn Ọlọ́run fún Dáfídì ni, ṣùgbọ́n ó rán Dáfídì létí lẹ́yìn tí ó jẹ́wọ́ tí ó sì ronúpìwàdà pé, "Ọlọ́run ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò." Dáfídì ṣì ní láti jìyà àbájáde ìwà tí ó hù, àmọ́ Ọlọ́run ti dárí jì í. Nítorí náà, ìhà yòówù kí o wà--bóyá à ń bá ọ wí ni tàbí ìwọ ní ò ń bá ènìyàn wí--o lè dúró láìṣojo láti kojú ìbẹ̀rù tàbí láti kojú àwọn àbájáde nítorí pé "Ọlọ́run ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò."
Àṣàrò/Ìbéèrè Ìjíròrò:
1. Ǹjẹ́ o ti ní láti bá ọ̀rẹ́ rẹ kan wí nípa bí ó ṣe ń ṣe ẹlòmíìràn ní ìjàǹbá? Báwo ni o ṣe ṣe é? Kíni ó wá ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ o máa ṣe nǹkan lọ́nà tí ó yàtọ̀ ní ìgbà mìíràn?
2. Tún Òwe 25:15 kà. Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe ní kí a sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣòroó yanjú?
3. Ǹjẹ́ ẹnìkan ti sọ àléébù kan tí o ní fún ọ rí, tí o kò sì f'ara mọ́ ọ? Báwo ni o ṣe lè fi ìgboyà hàn ní jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nígbà tó bá tún yá?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.
More